YO/Prabhupada 0022 - Ebi o pa Krishna



Lecture on SB 1.8.18 -- Chicago, July 4, 1974

Krishna so wipe "Oni gbagbo Mi, pelu ife," yo me bhaktyā prayacchati Ebi o pa Krishna. Krishna ko wa lati gba oore yin nitoripe ebi Npa. Rara. Ebi O pa. O wa ni pipe fun ara re, ati ni ibode orun won nsin, lakṣmī-sahasra-śata-sambhrama-sevyamānam, awon ogo-gorun ati egbe-gberun awon alaade wura ni won se ijise Re. Sugbon Krishna ni aanu pupo, nitoripe bi eyin ba je olufe ododo Krishna, Oun ma gba patraṁ puṣpam, ohun oree, yin Bi e ba ti le je oni talaka to rele ju lo, O ma gba ikan ki nkan ti e ba ni. bo ti le se ewe kekere, omi die, tabi adodo kekere. Ni bi ki bi lori ile aye, eni keni lo le ri nkan wonyi lati se oree fun Olorun, Krishna. " Olorun, emi ko ni ohun ti mo le fun O gege bi oree, talika ni mi, jowo gba eleyi" Krishna a gbaa. Krishna ni, tad aham aśnāmi, "Emi a jee" Nitorina, nkan ti o wa pataki julo ni bhakti, ife.

Ni bi bayi, won so pe alakṣyam. Airi ni Olorun. Olorun ko se ri, Sugbon ni pa ti aanu re pupo O ti so ka le wa siwaju yin, lati se riri fun oju yin yepere. Olorun ko see ri ni nu aye yi, pelu oju lasan. Gege bi a se je t'apa t'ese Olorun. T'apa t'ese Olorun ni wa, gbogbo nkan elemi, sugbon a ko ri ara wa. Eyin ko le ri mi, Emi ko le ri yin. "Rara, mo ri e. "Ki lo ri? O ri ara mi. Nitorina, ni igbati emi ba ti kuro ninu ara, kilode ti e ma nke "Baba mi ti lo? Kilode ti eni Baba ti lo? Baba sun si le. Kini e ri, bayi? E ti ri oku baba yin, ki se baba yin. Bee na, ti e ko ba le ri iwonrin Olorun, ti nse emi, bawo le e le ri Olorun? Nitori eyi, śāstra {iwe mimo} so wipe, ataḥ śrī-kṛṣṇa-nāmādi na bhaved grāhyam indriyaiḥ (CC Madhya 17.136). Oju imu lasan yi, oun ko le ri Olorun, tabi gbo oruko Olorun, nāmādi. Nāma tumo si oruko. Nāma tumo si oruko, ara, iyee, ise. Awon nkan wonyi ko le yin ni pa iriri oju ati imu yin lasan. Sugbon ti won ba di mimo, sevonukhe hi jihvādau, Ti won ba di mimo ni ipa ise ti ise oluwa, bayi e le ri Olorun ni gbogbo igba ati nibi kibi. Sugbon fun eni ti o ni wonsi, ko le se e ri. Krishna wa nibi gbogbo, Olorun wa nibi gbogbo, aṇḍāntara-stha-paramāṇu-cayāntara-stham. So alakṣyam sarva-bhūtānām. Bi o ti le je pe Olorun wa ninu ati lode, lona mejeji, sibe sibe awa ko lee ri Olorun afi ti a ba ni oju ti a fi le ri. Nitorina egbe isokan Olorun yi wa lati lawa loju la ti ri Olorun; ti e ba si le ri Olorun, antah bahih, igbesi aye yin ti se aseyori niyen. Nitorina śāstra {iwe mimo} so wipe, antar bahir.

antar bahir yadi haris tapasā tataḥ kiṁ
nāntar bahir yadi haris tapasā tataḥ kim
(Nārada Pañcarātra)

Oni kaluku nse gbiyanju lati di eni pipe, sugbon asepe tumo si lati ri Olorun ninu ati lode. Iyen ni asepe.