YO/Prabhupada 0024 - Alaanu ni Krishna



Lecture on SB 3.25.26 -- Bombay, November 26, 1974

Nigba ti Arjuna nri Krishna l'oju koroju - Krishna nko ni Bbagava-gita - iri Krishna yi ati ki ka Bhagavad-Gita, nkan nkan na ni mejeji Ko si iyato. Enikan, won so wi pe "Arjuna ni ori rere to to lati ri Krishna so ju ati gba imoran" Iyen ki se otito. Krishna, a le ri ni isin sinyi, ayafi ti a ba ni oju lati ri. Nitorina won so wipe, premāñjana-cchurita... Prema ati bhakti, nkan kan na ni. Premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena santaḥ sadaiva hṛdayeṣu vilokayanti [Bs. 5.38]. Ma so fun itan kan fun yin ni pa eleyi, pe ojise Olorun kan, brahmana ni isale India, ni Tempili Ranganatha, o nka Bhagavada-gita. Sugbon o je eniti ko mo iwe. Ko mo ede Sanskrit tabi oro ni ki ko, alaimowe. Bee na ni awon eniyan ara-adugbo re mo wi pe " Arakunrin yi ko mo iwe ka sugbon o nka Bhagavad-Gita" O nsi oju iwe Bhagavad gita, "Uh, uh," bayi lo se nse. nigba na ni enikan ba nfi se yeye, "E ma rora o, bawo ni e se nka Bhagvad-gita yi? O ye loju pe " Okunrin yi nfi mi se yeye nitoripe mi o mo iwe ka" Ni akoko yi, bee lo se wa wipe Caitanya Mahāprabhu na wa ni tempili Ranganatha lojo yi, o si da loju pe "Oni gbagbo ni eniyi" Bee ni O se sumo lati bere, "Brahmana mi owon, kini e nka?" Oun na ri wipe "Eni yi ki nse awada." Nigba na lo ba so wipe, "Alagba, Mo nka Bhagavad-Gita. Mo ngbiyanju lati ka Bhagavad-Gita, sugbon alaimowe ni mi. Nitori pe Guru Maharaja mi so wipe " O gbodo ka ori mejidinlogun inu iwe yi lojojumo" Sugbon emi o ni imo Kankan. Mi o si le ka iwe. Sibe sibe, Guru Maharaja si tenu mo, idi eni yi ti mo se ngbiyanju lati se ase re ati pe mo kan nsi awon oju iwe na, ko ju yen lo. Emi o mo bi won se nka' Caitanya Mahāprabhu so wipe "Mo ri pe ni igba miran oun sunkun" Bee ni, Mo nsukun " "Bawo lo se nsunkun ti iwo ko ba mo iwe ka?" "Rara, se nitoripe nigba ti mo gbe Bhagavad-Gita yi, mo ri aworan kan, to fi han pe Krishna ni pa aanu re pupo O ti di awako, sārathi, fun Arjuna. Omo eleyin Re ni Arjuna je. Eyi je wipe Krishna je alaanu pupo to be ti O fi gba ipo iranse. nitoripe Arjuna nfun ni ase, "Fi oko mi si bi' ati pe Krishna njise fun. Nitorina Krishna je alaanu pupo. Nitori eyi nigba ti mo ri aworan yi ninu okan mi, mo bere si nsunkun." Nigba na ni Caitanya Mahāprabhu faa mora re lowo kan na, wipe " O nka Bhagavad-Gita. Laini eko kan kan, iwo nka Bhagavad-Gita." O si faa mora.

Nitorina eyi ni... Bawo ni ose nri aworan? Nitoripe o je olufe Krishna, ko nse dandan, boya o le ka awon ewe yi tabi beko. Sugbon ife Krishna bo lokan to bee ti o se nrii, Krishna joko sibe, O si nwa oko Arjuna. Nkan ti a fe ni yi.