YO/Prabhupada 0039 - Awon Olori orile ede oni dabi isere owo



Lecture on SB 1.10.3-4 -- Tehran, March 13, 1975

Nitorina Oba t'apeere to ga ju lo bi Yudhisthira, ki ise lori ile nikan lo le joba, subgon lori okun ati lori gbogbo aye. Iyen ni apeere ti o ga ju lo. [Nkawe] " Ofin oyinbo ti ode oni nipa ti ijogun ti omo akobi, je asa to gbode ni igba ti Oba [Maharaja] Yudhisthira njoba lori aye pelu ile ati okun re." Iyen je gbogbo aye, ati awon okun. (Nkawe) "Ni igba na ni awon ojo ana Oba Hastinapura, agbegbe New Delhi ti isinyi, oun ni Oba awon oba aye, pelu ile ati okun re. titi ti o fi di igba Maharaja Pariksit, omo-omo Maharaja Yudhisthira. Awon aburo re okunrin ni won je asoju ati balogun ti orile ede, ifowosowopo gidi si wa laarin awon olufokansin egbon ati aburo Oba na. Mahārāja Yudhiṣṭhira je oba alapere to ga ju tabi asoju Oluwa Krishna..." Oba gbodo je igbakeji Orisa[Olorun]. "... lati joba lori ipinle aye o si je ifarawe Oba Indra, ti o je asoju Oba Orun. Awon Orisa Nla bi Indra, Candra, Surya, Varuna, Vaayu, ati bebe lo won je asoju awon oba ti aye miran. Ati bakanna ni Mahārāja Yudhiṣṭhira se je ikan ninu won, gebe bi alakoso aye.

Mahārāja Yudhiṣṭhira ki ise bi awon aimokan olori oniselu ti ojo oni. Mahārāja Yudhiṣṭhira gba imoran lowo Bhismadeva ati ti Oba ti ki isubu, nitori eyi o si ni iye kikun ti gbogbo nkan ni pipe. Olori orile ede ti ode oni ti a yan sipo ko ju bi isere owo nitoripe ko ni ase oba. Bi o ti le je eni ti o ni imo ijinle bi Mahārāja Yudhiṣṭhira, ko le se nkan nkan ti okan ara re gege bi ipo re. Nitori eyi, awon orile ede ngbo gun ti ara won nitori iyato ninu eto iselu tabi nitori idi iro ara ti enikan. Sugbon oba bi Mahārāja Yudhiṣṭhira ko ni eto ti ara re. Ko ni ohun miran lati se ju pe ko tele imoran Olorun ti ko ni isubu ati ojise re, ati ojise alase, Bhismadeva. Won so fun wa ninu awon iwe mimo pe ki a tele alase nla ati Olorun ti ko ni isubu lai ni imoara eni kan kan ati imo ti a da sile. Nitori eyi, o ti se se fun Mahārāja Yudhiṣṭhira lati joba lori gbogbo aye, pelu ile ati okun re, nitori awon ilana ti ko ni baje ti won si wulo fun oni kaluku ni ibi gbogbo.

Iro aye kan pelu ijoba kan le see se nikan ti a ba tele olori ti ko ni isubu. Omo eniyan ti o je alabuku ko le da imo ti o le da onikaluku lorun. Afi eni alailabawon ati eniti ko ni isubu nikan ni o le se eto ti a wulo ni ibi gbogbo ati eyi ti gbogbo aye le tele. Eni ti o ndari ni olori, ki ise ijoba. Ti eni na ba je alainibawon, ijoba re na o si wa ni pipe. Ti eni na ba je omugo, ijoba na a si je orun awon omugo. Opolopo itan lo wa ni pa awon oba alaito, tabi awon olori orile ede ti won je alaito. Nitori eyi, olori orile ede gbodo je eniti a ti oni eko gege bi Mahārāja Yudhiṣṭhira, o si gbodo ni agbara patapata lati joba lori gbogbo aye. Iro ijoba aye kan lee se se nikan ni abe Oba to dape bi Mahārāja Yudhiṣṭhira. Ile aye ro awon eniyan l'orun ni igba na nitoripe awon oba bi Mahārāja Yudhiṣṭhira wa lati se ijoba lori aye." Ti oba yi ba tele Mahārāja Yudhiṣṭhira ti o si nfi apeere han bi oba se nse eto ilu ni ni aseyoju laisi iwonku wonsi. Ilana wa ninu awon iwe mimo, ti o ba si tele won, o lee se. O ni agbara na.

Ati pe nitori ti o je oba ti o daaju, ati, igbakeji "Orisa" tabi ojise Olorun, nitorina, kāmaṁ vavarṣa parjanyaḥ (SB 1.10.4). Itumo Parjanyah ni ojo riro. Ojo riro je ipinle pataki fun sise eto gbogbo nkan ini eniyan, iro ojo. Nitori eyi Krishna so ninu Bhagavad Gita wipe, annād bhavanti bhūtāni parjanyād anna-sambhavaḥ (BG 3.14). Ti e ba fe mu inu awon eniyan dun, ni eniyan ati eranko... Awon eranko na pelu. Won je... Awon olori orile ede ti won o nilari yi, won ma nse afojuri fun anfani awon eniyan sugbon won o ni se nkan nkan fun anfani awon eranko. Kiilode? Kini o fa iru ikoje bayi? Omo ile yi na ni won, Awon elemi na ni won. Won le je eranko. Won o ni ogbon. Bi ogbon won ko tile to gbon bi awon eniyan, iyen ko ni wipe a gbodo ko ile ipa run lati fi ma pa won deede? Se idajo rere ni yi? Sugbon ki ise iyen nikan, sugbon enikeni, ti o ba wa si orile ede, oba na gbodo fun ni abobo. Kilode ti a nse iyato? Enikeni ti o ba wa si abe abo, "Alagba, mo fe wa gbe ni orile ede yin," won si gbodo fun ni aye. Kini idi eyi, "Rara, rara, iwo ko le wa. Omo Amerika ni iwo je. Omo India ni iwo. Omo yi ni e"? Rara. Opo nkan lo wa. Ti won ba tele awon ilana gidi gan, awon ilana Vediki, ni igba na oba ti o dara ju lo a se ise re bi olori ti odara. Aseda na a ba se. Nitori eyi won so wipe ni igba ijoba ti Mahārāja Yudhiṣṭhira, kāmaṁ vavarṣa parjanyaḥ sarva-kāma-dughā mahī (SB 1.10.4). Mahi, ile aye. E ri gbogbo nkan ini yin lati ilè wa. Ko jabo lati oju orun. Beeni, , o jabo lati orun ni ipase ojo. Sugbon won o mo imo ijinle yi., pe bi nkan se nti ile wa ni ipa ti eto orisirisi. Ni akoko ati igba ti o ye ojo nro. Nigba na ni awon nkan orisirisi se nda sile, awon ileke iyun ti won joju, awon ileke. Won o mo bi awon nkan wonyi se nwa. Nitori idi eyi, ti oba na ba je eni ti o ni iberu Olorun, eda ohunkohun na a si se ifowopowopo lati ran lowo. Sugbon ti oba na ati ijoba re ti won o ba ni iberu Olorun, eda ohunkohun na ko ni se ifowopowopo.