YO/Prabhupada 0044 - Itumo ise ni pe ka se nkan ti Oga ba da l'ase



Lecture on BG 4.1 -- Montreal, August 24, 1968

Beeni iyen tumo si wipe o ntele ilana Olorun. O pari. Ko jo loju pe "Mo fe di ota Olorun" Ofin ni wipe oun tele ilana. Ti Olorun ba ni "Iwo di ota Mi," Beeni mo le se l'ota. Iyen ni bhakti-yoga. Beeni. Mo fe se ife Olorun. Gege bi oga kan se nbeere lowo iranse re " Gba mi ni bi" O si ngbaa be. Beena iyen se je ise. Awom miran leri pe, " Ah o ngba oga o si ro pe oun se ise fun? Kini itumo eleyi? Oun gba oga" Sugbon ife oga ni pe ki "Iwo gbaa mi" Iyen ni ise. Itumo ise ni pe ka se nkan ti oga ba da l'asè. Bo ti wu ki nkan na je. Apeere to dara kan wa ninu aye Oluwa Chaitanya, o wa pe o ni iranse kan, Govinda. Leyin ti Oluwa Chaitanya ba pari ati jehun, igba na ni Govinda ma jehun. O wa di ojo kan, Oluwa Chaitanya, leyin ti o ti pari ati jehun O si nara re si oju ona. Ki na ti npe? Oju ona? Ilekun? Enu ona. Beni Govinda se da koja. Govinda ma npara ese Re fun leyin ounje, ni igba ti O ba nnara. Bayi ni Govinda se da Oluwa Chaitanya koja to si bere si para ese re. Oluwa Chaitanya si sun lo, titi di nkan bi idaji wakati kan, ni igbati O ta ji, O ri wipe, "Govinda, iwo ko tii jehun ?" "Rara, alagba" "Kilode" Mi o le da yin koja. E nnara ni be" "Bawo lo se wa ngba na"? " Mo tun yin ka." "Bawo lo se tun mi ka l'akoko, kilode ti o ko le tun mi ka ni ekan si? "Nigba na mo wa se ise fun Yin. Sugbon nisinyi emi ko le da yin koja lati lo jehun. Iyen ki ise ojuse mi. Iyen je temi. O si je ti Yin." Nitorina fun ife Olorun o le se l'ota, o lo se l'ore, o le se nkan ki nkan. Iyen ni bhakti-yoga. Nitoripe ero okan yin ni lati se ife Olorun. Gbere ti o ba ti wu yin lati se ife ti ara yin, e si di eni ti aye lasan lowo kan na.

kṛṣṇa-bahirmukha hañā bhoga vāñchā kare
nikaṭa-stha māyā tāre jāpaṭiyā dhare
(Prema-vivarta)

Gbere ti a ba ti gbagbe Olorun ti a si fe se nkan ife ara wa, maya ni yen. Gbere ti a ba si fi iwa ati se ife ara yi sile ti a si nse gbogbo nkan fun Olorun, iyen ni igbala.