YO/Prabhupada 0045 - Iriri imo ni a si npe ni jneyam



Lecture on BG 13.1-2 -- Paris, August 10, 1973

Prabhupāda:

prakṛtiṁ puruṣaṁ caiva
kṣetraṁ kṣetra-jñam eva ca
etad veditum icchāmi
jñānaṁ jñeyaṁ ca keśava
(BG 13.1)

Eyi ni nkan to se pataki julo fun omo eniyan, pe o le ni iye eda ohunkohun, ipinle iseda aye gbogbo, ati onigbadun eda ohunkohun, ko si je nkan ti o faramo daju daju nipa nkan ti o se koko ninu imo, jñeyam.

Nkan meta lo wa, jñeyam, jñāta, ati jñāna. Iriri imo, onimo ni a npe ni jñāta, iriri imo ni a si npe ni jñeyam. Ona ti a si ngba lati ni oye, iyen ni a npe ni jñāna, Gbere ti a ba soro ni ipa imo, nkan meta gbodo wa nbe: iriri imo, eni ti o ngbiyanju lati mon ati ona ti a ngba lati se aseyori imo.

Nitorina awon kan ninu won... Bi awon oni sayensi onife aye, ise won ko ju lati mo prakriti. Sugbon won o mo purursa. Prakriti tumo si nkan ti a gbadun, purusa na si tumo si onigbadun. Ni enu kan Olorun ni Onigbadun. Oun ni onigbadun atilewa Arjuna ma se ijewo eyi: puruṣaṁ śāśvatam. "Iwo ni onigbadun atilewa, purusam." Olorun ni onigbadun, eni ko kan wa, awon nkan elemi, ati prakriti na, eda ohunkohun, gbogbo nkan, ni won wa fun igbadun Olorun. Iyen ni ti Olorun... Purusa miran, awa omo eda. Awa ki nse purusa. Prakiriti ni awa na nje. A wa ni lati fi se igbadun. sugbon ni ipo ile aye yi, a ngbiyanju lati je onigbadun, purusa. Itumo eyi ni wipe, nigbati prakriti, tabi awn nkan elemi, ba fe di purusha, ipo ti aye ni yen. Ti obinrin ba fe di okunrin, bi o ti je nkan ti o sodi si idanida, bakanna ni igbati awon nkan elemi, ti won je nkan lati fi se igbadun gege bi iwa eda won...

Apeere na, bi a ti se alaaye ni igba pupo, pe ti omo ika ba di onje mu, sugbon bi o ti wa daju awon omo ika ki nse onigbadun. Awon omo ika le ran onigbadun gangan lowo, inu la npe. O le mu nkan jije to dara ko si fi si enu, ti o ba si lo s'inu, onigbadun gidi gan, igba na gbogbo awon prakritis, gbogbo ipa ara, gbogbo t'owo t'ese ara, won si ma ni ite lorun. Nitorina inu ni onigbadun, kii se ipa ara kan kan.

Itan kan wa ni inu Hitopanishad, Hitopadesha, ninu ibi ti won ti tumo awon itan Isopu. Itan kan wa nbe: udarendriyānām. Udara. Inu lo nje be, Udara, awon oju ati imu na nje indiriya. Itan na nse ni pa udarendriyanam. Awon ipa ara, oju-imu-eti-owo ati ese parapo lati se ipade. Won so wipe "A wa la nse se, oju-imu..." [Legbe kan] Kilode ti won si?

"Awa la nse se" Ese so wipe: "Beni, Emi, ni gbogbo ojo, mo nrin kiri." Owo so wipe: "Beni, mo nse se ni gbogbo igba, ibikibi ti ara ba wi: "Wa mbi ko wa gbe onje yi" gbigbe awon nkan, si se onje. Emi na ni mo nse onje." O wa kan oju, won so wipe: "Mo nriran" Gbogbo ipa ara, lati ori d'ese, won fi se sile won wipe "a ko le ma sise ki inu nikan ma'a jehun. Gbogbo wa nse se, oun si wa nbe, tabi inu nikan, nda jehun" Nigba na ni, a fi ise si le... gege bi awon olowo ati osise. Osise fi se sile, ko si se mo. Beeni gbogbo ipa ara, t'owo t'ese, se f'okan se kan lati f'ise si le, leyin ojo meji, ojo meta, ti won tun se ipade, won bere si soro laarin ara won wipe: " Kilode ti o se nrewa? A ko le se ise nisinyi" Ese na so wipe: "Beni, o nre mi" O nre owo na, ko si eniti o lokun mo. Kini idi eleyi? Idi re... Inu wa so pe: "Nitoripe mi o jehun mo. Nitorina ti e ba fe lokun lara, e si fun mi ni onje je. Bi beko... Emi ni onigbadun. Ki ise eyin. Ise yin ni lati se opo awon nkan fun igbadun mi. Ipo yin ni yen" Igba na lo wa ye won. "Bee ni, a o le je igbadun fun rara wa. Ko se se." Igbadun gbodo wa lati inu wa. Mu rasagulla kan, eyin omo ika, e o le gbadun fun rara yin. E fifun enu, bi o ba de inu, e kan na ni agbara ma wa. Ki ise awon omo ika nikan ni won ma gbadun, oju, ati gbogbo ara ti o ku, won o ni itelorun ati agbara bakanna. Bakanna, onigbadun gidi gan ni Olorun. Olorun so wipe:

bhoktāraṁ yajña-tapasāṁ
sarva-loka-maheśvaram
suhṛdaṁ sarva-bhūtānāṁ
jñātvā māṁ śāntim ṛcchati
(BG 5.29)