YO/Prabhupada 0053 - L'alakoko ni pe agbodo gboran



Lecture on SB 2.1.5 -- Delhi, November 8, 1973

Bee na awa na je prakrit. Awa na je agbara Olorun Ati nitoripe a ngbiyanju lati lo awon eroja ilè, idi e niyi ti awon nkan ti aye ni iyi. Bi beko, ko ni iyi, asan. Sugbon iponju wa ni... Won fi enu ba yen nbi, nitoripe a wa ninu idande pelu nkan ti aye yi Nkan ti aye kii se iponju wa. Iponju kan soso ti a ni je bi a se le kuro ninu aye yi. Iyen ni iponju wa ni ododo. Ti e ba fe iponju na, e wo ilana eto re ni bi. Kini nkan na? Śrotavyaḥ kīrtitavyaś ca. Ayafi ti e ba gbo ran, bawo ni e se le loye ipo yin? Ni igbati e ba ni oye Olorun, Krishna, ati oye wipe e je ti apa ti ese Olorun, tabi Krishna, igba na ni e le ni ie ipo yin: "Ah, t'apa t'ese Olorun ni awa je." Olorun ni Atobiju lo, ṣaḍ-aiśvarya-pūrṇam, ti o kun fun awom nkan ini pupo. Gege bi were omo ti o nrin igboro, nigba ti o loye pelu ogbon wipe: "Baba mi je olowo olola, ti o si lagbara, kilode ti mo nrin ka igboro bi eniti o ya were? Mi o ri je, ko si abo. Mo nya ile s'ile lati bebe," ni ori re ba wa si le. Iyen la npe ni ipo brahma-bhuta (BG 18.54) "Ah, Emi, Emi ki se eni ilé. Emi je émi okan, t'apa t'ese Olorun. Iyen ni ifokansin.

Ifokansin yi ni anse yanju lati fun l'okun. Eyi ni ise anu fun alafia awon eniyan ti o dara julo, lati se irapada ti emi. Onfi ti omugo ronu wipe "Lati inu erupe ni won ti da mi, ati pe mo ni lati to awon nkan mi lesese laye yi" Eyi ni ise omugo. Ogbon to daju ni pe o je Brahma-bhuta, ahaṁ brahmāsmi. ahaṁ brahmāsmi, "T'apa t'ese Olorun ni emi je. Olorun ni Brahman to ga julo. Emi, gege bi t'apa t'ese ..."Gege bi ipa ti golu, orisun golu, o le je yarini kekere, golu na ni. Bakanna, iba omi kekere ti okun je iri kan na pelu okun, oniyo. Bakanna, awa ti a je gege bi ipa t'apa t'ese Olorun, awa na ni awon iri kan na. Ni iriri, a je ikan na. Kilode ti a nse laala nipa ti ife? Nitoripe ife ni Olorun. A nsin Radha Krishna ni bi. Ni atilewa ife wa. Nitorina, jije wa bi t'apa t'ese Olorun, awa na ngbiyanju lati ni ife. Okunrin ngbiyanju lati ni ife obinrin, obinrin ngbiyanju lati ni ife okunrin. Eleyi je iwa-eda. Eleyi ki s'eke. Sugbon o ti pawada ninu ibora aye. Iyen ni ibamo. Nigbati a ba yege kuro ninu ibora ti aye yi, nigba na ni a o je iriri kan ānandamayo 'bhyāsāt (Vedānta-sūtra 1.1.12), gege bi inu didun... Gege bi Krishna se njo ni gba gbogbo... E ko le ri igba kan ti Krishna... E ti ri aworan Krishna. Nigba ti o nja pelu ejo Kaliya. Se l'O Njo. Ko beru ejo na. Se l'O njo. Bi O ti se njo pelu awon gopis ni rasa-lila, bakanna, l'O se Njo pelu ejo. Nitoripe O je ānandamayo 'bhyāsāt. O je ānandamaya, gbo gbo igba ninu didun. Ni gbo gbo igba. E ma ri Krishna... Krishna ... Bi igbati ogun nja ni Kurukshetra Krishna wa ni idunnu. Arjuna wa ninu ibaje nitori wipe o je eleda, sugbon Oun ko si ninu ibaje. Oun wa ninu idunnu. Iwa-eda Olorun ni yen. Ānandamayo 'bhyāsāt. Sutra na wa, ninu Brahma-sutra, to so wipe "Anandamaya ni Olorun, ayo ni nigbogbo igba, titi layo ni." Eyin na le di alayo nigbati e ba pada si Babaloke. Iyen ni isoro wa.

Nitorina bawo ni a se le de be? L'akoko ni pe a gbodo gboran. Srotavyah. Gbigbo ni pa Olorun pere, kini ijoba orun Re, Kini ise Re, Bawo ni O se je alayo. A gbodo gbo nkan won yi. Sravanam. Nigba na, gbere ti e ba ti wa daju, "Ah, Olorun dara gan," nigbana e o si niwara lati fihan tabi lati se ikede ihinrere yi kari aye. Eyi ni kirtanam. Eyi ni kirtanam, iyin logo.