YO/Prabhupada 0058 - Ara elemi tumosi aye ailopin



Lecture on BG 2.14 -- Mexico, February 14, 1975

Ni ododo ara elemi tumosi aye ailopin ti idunnu ati oye. Ara ti a ni lowo bayi, ara yepere, ko nse ailopin, tabi talayo, tabi pe o kun fun imo. Olukaluluku wa ni a mo wipe ara yepere yi ma wa si opin. O si kun fun aimokan. A o le so nkankan mo, ti o ba ti koja ogiri yi. A ni awon apa ara, sugbon won ni iwonba, won je alaipe. Nigba miran o nse wa lagan pe a nriran, a si ma se ileri, " Se o le fi Olorun han mi"? sugbon o se wa ni igbagbe wipe gbere ti ina ba lo, agbara ririran mi na ti lo. Nitrina gbogbo ara yi ni o je alaipe ti o si kun fun aimokan. Ara ti emi tumo si imo kikun, idojuko ara. Bee na a le ri ara na gba ni aye miran, a si gbodo fi se ikora bi a se leri iru ara na. A le fi se ikora bi a se le ri ara miran ni ori awon aye to ga tabi a le fi se ikora bi a se ngba ara minran bi awon ologbo ati aja. a si le fi se ikora bi a se nni ara ti ko lopin, ti alayo ati imo. Nitorina eniti o baje ologbon gidi a se yanju lati ni ara miran ti o kun fun ayo, imo ati aye ailopin. Won se alaye eyi ninu Bhagavad -Gita. Yad gatvā na nivartante tad dhāma paramaṁ mama (BG 15.6). Aye na, aye miran, tabi orun, ibi ti e ma lo ti e ko si ni pada wa si ile aye asan yi. Ni ile aye asan, bi e ba tile ni igbega, paapa si aye miran to ga julo, ti a npe ni Brahmaloka, bakanna, e gbodo tun pada wa. Ti e ba si se iyanju pupo lati lo si ijoba orun, ni ipada s'ile s'odo Babaloke, e ko ni pada wa lati gba ara yepere ti ile aye yi.