YO/Prabhupada 0064 - Siddhi tumo si isepe aye



Lecture on SB 6.1.15 -- Denver, June 28, 1975

Kecit tumo si "enikan" "Sowon pupo" "Enikan" tumo si "sowon pupo" Ko rorun rara lati di vāsudeva-parāyaṇāḥ. Mo se alaaye l'ana pe Bhagavan, Olorun, so wipe yatatām api siddhānāṁ kaścid vetti māṁ tattvataḥ, manuṣyāṇāṁ sahasreṣu kaścid yatati siddhaye (BG 7.3). Siddhi tumo si isepe aye. Nigbakugba won ma gba fun aṣṭa-siddhi ti ise yoga - aṇimā, laghimā, mahimā, prāpti, siddhi, īśitva, vaśitva, prākāmya. Bee ni awon eyi ni a npe ni siddhis, yoga-siddhi Yoga-siddhi tumo si wipe e le di kekere ju nkan to kere julo; Titobi wa n'idaju koju kinkinni. Bee na ni pa ese ti yoga-siddhi, laibikita ara ti a ni yi, yogi wa ti o le di kinkinni bi ori abe, ti o si le jade ni ibikibi ti won ba fi pamo si; Iyen ni won pe ni anima-siddhi. Bakanna ni mahima siddhi wa, laghima-siddhi. O le di fi fele bi igbon owu Awon yogi, won ma ndi fele fele. Titi di isinyin awon yogi wa ni India. Ni idaju, ni igba ti awa l'omode, a ri awon yogi kan, ti o ma nwa si odo baba mi. Bee ni o se so wipe oun le lo si ibi kibi laarin iseju melo kan. Ati pe ni igba miran won a lo ni aaro kutu si Jagannatha Puri, si Ramesvara, si Haridwar, nibi ti won ti nwe ninu orisirisi omi Ganga ati awon omi miran. Iyen ni won npe ni laghima-siddhi. Ki e di fele fele' , O ma nso wipe " A njoko pelu guru wa a ti bi ase nfowo kan lasan A joko si bi, ati ni eyo iseju kan anjoko ni bo miran" Eyi ni won n pe ni laghima siddhi.

Bee na ni awon orisirisi yoga-siddhis lo wa. O ma nya awon eniyan lenu lati ri awon nkan iyanu yoga-siddhi wonyi. Sugbon Olorun so wipe, yatatām api siddhānām: (BG 7.3) "Lara awon ti won ti ni yoga-siddhi wonyi, ti won npe ni siddhas, yatatām api siddhānām kaścid vetti māṁ tattvataḥ (BG 7.3), "Boya enikan ninu won ni o ni iye MI" Bee na eyan le ni agbara yoga-siddhis, sibe sibe o je isoro fun lati mo Olorun. Ko le se se. Olorun le se mo nikan fun awon ti won ti fi gbogbo re Fun patapata laiku. Nitorina ni Olorun se bere wipe, sarva-dharmān parityajya mām ekam śaraṇaṁ (BG 18.66). Olorun se mo nikan nipa ti awon olufokansi mimo Re, ki se nipa eni kan miiran.