YO/Prabhupada 0081 - Ni aye oorun ara awon eda alaaye je ti ina



Lecture on BG 2.13 -- New York, March 11, 1966

Bee nisinyi, won so nibi yi pe dhira, dhira

dehino 'smin yathā dehe
kaumāraṁ yauvanaṁ jarā
tathā dehāntara-prāptir
dhīras tatra na muhyati
(BG 2.13)

Dehinaḥ. Dehinaḥ tumo si "eni ti o ti gba ara yepere yi." Asmin. Asmin tumo si "ni aye yi" tabi "ni igbesi aye yi" Yathā, "gege bi." Dehe. Dehe tumo si "ninu ara yi" Nitoripe dehinah tumo si "eni to ti gba ara yi", dehe na "ninu ara yi" Bee na ni mo njoko ninu ara yi. Nisinyi, emi ki se ara yi. Gege bi e se wa ninu ewu ati kootu yi,, bakanna, emi na si wa ninu ara yi. oku ara yi ati ara ti emi. Nipa iyepe, omi, ina, ategun ati ofurufu ni ara yi ti wa, oku ara yi, gbogbo ara aye yi pata. Bayi, ninu Aye yi, ninu aye ti a wa yi, ilé-iyepe je pataki julo Nibi gbogbo, ara na, ara aye yi, wa lati inu awon ohun okun marun yi: iyepe, omi, ina, ategun ati ofurufu. Awon eroja marun na niyi. Gege bi ile yi. Won ko gbogbo ile yi lati inu iyepe, omi ati ina. E ti mu awon iyepe die, e si mo won si biriki ti e si jo won ninu ina, ati leyin igba ti e ba ti yi yepe mo omi, e mo biriki, e si fi sinu ina, nigba ti o ba ti le dara dara, nigba na le ma to won po bi ile nla. Bee na ko je nkankan bi ifihan, yepe, omi ati ina, nikan. Ko ju yen lo. Bakanna, ara wa na wa ni ona kan na: iyepe, omi, ina ategun ati ofururfu. Ategun... Ategun nkoja, mimi na. Se mo. Ategun wa nbe nigba gbogbo.. Eyi, awo ara yi je yepe, oruu si wa ninu inu. Laisi oruu, e ko le da ounje. Se e ri ba yen? Gbere ti oruu ba ti din ku, agbara ati da ounje ko ni lokun mo. Opolopo nkan. Eto leto ni. Nisinyi, ninu aye yi a ni ara yi ti o je, nibi ti iyepe ti se pataki. Bakanna, ni awon aye miran, nibi kan omi lo lokiki ju, nibi kan ina lo lokiki pupo. Ni aye oorun, awon ara to wa nbe... Awon eda alaaye na wa nbe, sugbon ara won je ti ina. Won le gbe ninu ina. Won le gbe ninu ina. Bakanna, Varunloka, ni ori Venus, gbogbo awon aye won yi, ni won ni orisirisi ara. Gege bi ibi e le ri iriri yi ninu omi, awon eda inu omi, won ni ara to yato. Fun odun lori odun awon eranko inu omi wa, won ngbe ninu omi, o si re won lorun. Sugbon kete ti e ba fa a sori ile, a ku. Bakanna, e ni itelorun lori ile, sugbon gbere ti won ba fi yin sinu omi, wa ku. Nitori pe ara yin, idasi ara yin yato, ara ti re, idasi ara re yato, idasi ara eye... Eye na, eye nla, ole fo, sugbon fifo re ise owo Olorun ni. Sugbon ise owo yin, won ni jamba, jamba. Se e ri? Nitoripe won je ogbon arekereke.

Bee na eto na ni yi. Gbogbo awon eda alaaye ni won ni iru ara ti o ye won. Dehino 'smin yathā dehe (BG 2.13). At kini idanida ara na? Nisinyi, won se alaye re ni bi, wipe bi a se npara wa da? Bawo ni... Sugbon, sugbon, sugbon, nitori isoro kan wa fun wa nitoripe a ti wa ninu ninu ero okan ati ma fi ara yi se ni pi pe pelu emi. Nisinyi, akoko A-B-D eko ijinle emi ni lati ni imo wipe "Emi ki se ara yi." Ayafi ti a ba ni igbagbo yi dajudaju wipe "Emi ki se ara yi," e o le se ilosiwaju nipa ti emi. Bee na eko kini ninu Bhagavad-Gita so fun ni ba yi. Bee na ohun ni yi, dehino smin na. Nisinyi, dehi, emi na. Emi, dehi tumo si emi. Eni ti o ba ti gba ara yi, ara aye yi, a npe ni dehi. Bee na asmin, o wa nbe. O wa nbe, sugbon ara re nyi pada.