YO/Prabhupada 0085 - Asa ti imo tumo si imo nipa ohun ti emi



Lecture on Sri Isopanisad, Mantra 9-10 -- Los Angeles, May 14, 1970

Awon ojogbon ti s'alaye fun wa wipe wi pe ere kan mbe ninu asa imo, ati wipe ere miran tun wa lati gba ninu asa aimokan." Bee ni laana a ti se alaaye die nipa iye ohun ti o nse asa aimokan ati ohun ti o je awon asa ti imo. asa ti imo tumo si imo nipa ohun ti emi. Iyen ni imo gidi. sugbon ilosiwaju ti imo fun igbadun tabi lati dabobo fun ara asan yi, iyen ni asa aimokan. Nitoripe bi o ti le wu ki e gbiyanju to lati dabobo ara yi, ipa ona adayeba re di dandan. Kini yen? Janma-mṛtyu-jarā-vyādhi (BG 13.9). E ko le ran ara yi lowo lati kuro ninu ibi ati iku,, ati nigba to ba wa laaye, aarun ati idarugbo; Bee na ni awon eniyan se nsise kara-kara fun kiko asa imo ti ara yi, biotileje wipe won nri bi ni gbogbo akoko ara yi ndibaje. Won ti se aami iku si ara na lati igbati won ti bi. Iyen daju. Bee na ni e ko le da ona adebaye ti ara yi duro. E gbodo daju ko eto ara yi, ni idaruko, ibi, iku, idarugbo ati aarun.

Bee ni Bhagavata si so wipe, nitorina, yasyātma-buddhiḥ kuṇape tri-dhātuke (SB 10.84.13). Nipa eroja meta pataki ni ara yi ti wa: ikun, bile ati ategun Eyi ni ikede Vediki ati itoju Ayurvediki. Apo ikun, ororo ati ategun ni ara yi. Ni ojo arugbo iyi-ka ategun ninu ara a di wahala; fun idi eyi eni arugbo a di alaisan, oni ruru aise dede ara. Bee ni Bhagavata so wipe, "Eniti o ba ti gba idapo oro, ikun ati ategun gegebi ara re, o je omugo." Dajudaju, eyi je otito Ti a ba gba idapo oro, ikun ati ategun bi ara eni... Bee ni eni to loye, ojogbon nla, onimo sayensi to ga, se o tumo si wipe o je idapo oro, ikun ati ategun? Rara o. Asise na niyi. O yato si oro tabi ikun tabi ategun. O je emi Ati pe gege bi kadara re, o nfihan, o nfi ebun re han. Bee ni won o loye kadara yi, ofin esan. Kilode ti a nri opolopo awon eniyan ti won yato?