YO/Prabhupada 0086 - Ki lo fa iyato won yi



Sri Isopanisad, Mantra 9-10 -- Los Angeles, May 14, 1970

Kilode ti anri opolopo eniyan ti won yato? Ti o ba je idapo oro, ikun ati ategun, kilode ti won o jora? Bee ni won o ko eko yi. Ki lo fa iyato won yi? Won bi enikan sinu oro pupo; won bi elomiran, ko tile le ri ounje ojoo lee meji lojumo bi o tile je wipe o nse laalaa loju lile. Ki lo fa iyato yi? Kilode ti ikan se ni ipo to dara? Kilode ti ikeji ko ni? Bee ni ofin esan se wa, fun olukaluku.

Bee ni eyi je imo. Nitorina Isopanishad so wipe anyad evāhur vidyayā anyad āhur avidyayā. Awon ti won wa ninu aimokan, won nse iru eko miran fun itesiwaju imo. ati pe awon ti won je onimo gidi, awon na nko eko ni ona miran. Awon eniyan ti ki se pataki, won lodi si akan wa, isokan Olorun. O ya won lenu. Gargamuni nso fun mi ni irole aana wipe awon eeyan nbere "Nibo ni e ti nri owo pupo bayi? E nra awon opolopo oko ati awon ini ile ijosin nla nla. e si ntoju adota, ogota eniyan lojoojumo ti won si ngbadun. Bawo le yi se je? (rerin) Bee ni o se ny a won lenu. O si nya awa na lenu idi e ti awon alaibikita won yi se nsese lile lile ki won kan fi le fi ounje sinu. Bee na ni Bhagavad Gita so wipe, yā niśā sarva-bhūtānāṁ tasyāṁ jāgrati saṁyamī. A nri bi awon eeyan yi se nsun, awon si nri bi a se nfi akoko wa sere. Eyi je iri to dojuko ra. Bawo? Nitoripe isewawu won yato, isewawu ti wa na si yato. Nibayi, eni ti o loye nikan lo le so isewawu ti tani lo yé.

Won se alaaye awon nkan won yi dara dara ninu awxon iwe Vediki. Imiran wa, bi eyi se je Isopanishad, bakanna, Upanishad miran tu wa, Garga Upanishad. Bee naa ni eyi je ijiro laarin oko ati aya, to logbon pupo. Oko nko aya re. Etad viditvā yaḥ prayāti sa eva brāhmaṇa gargi. Etad aviditvā yaḥ prayāti sa eva kṛpanā. Asa iko imo gidi, eniti... Gbogbo eni la bisaye bee na ni gbogbo eniyan ni o ku. Ko si iyato ero nipa eleyi. Awa ma ku awon na o si ku. Won le so wipe "E nronu ibisaye, iku idarugbo ati aarun. Se iyen wa tumo si wipe nitoripe eyin nse eko isokan Olorun, eyin ma ni ominira lowo ipile merin ijiya ti idanida?" Rara. Iyen ki se ododo. Ododo oro ni wipe, Garga Upanishad so wipe, etad viditvā yaḥ prayāti Eni ti o ba fi ara yi sile leyin ti o ba ti ni imo eni ti oun nse, sa eva brāhmaṇa, o je brahmana. Brahmana... A nfun yin ni okun mimo na. Kilode? E kan se iwonba yin lati ni oye aramada ile aye yi. Iyen lo nje brahmana. Vijanatha. A ti kaa ninu ese iwe yi , vijanatha. Eni ti o ba fi ara yi sile leyin igba ti o ba ti ni oye awon nkan daju, oun ni brahmana.