YO/Prabhupada 0102 - Iyara ti okan



Lecture on SB 5.5.1-8 -- Stockholm, September 8, 1973

E ti ni ọkọ ofurufu ni bayi. Iyen dara. Sugbon e ko le de koda awon isogbe aye orun. bee ni ti e ba fe lo si orun elemi, nigbana e ni lati se ọkọ ofurufu ti o yara bi okan. Tabi ti o yara bi ategun. awon oni sayensi won mo iyara ategun, ohun ti nse iyara imole.. Bee ni lori awon iyara yi, iyara okan ju gbogbo won lo. Awon oni sayensi wan mo iyara ategun ati imole. Okan si tun ni iyara siwaju si. E ti ni iriri. E wa ni ijoko nibi bayi. Lesekese, ni iseju kan, e le losi orile-ede America, India,, lesekese. E le lo si ile yin. E le ri awon ohun nkan - pelu okan, dajudaju; iyara okan. bee na Brahma-saṁhitā so wipe, ti e ba le se oko-ofurufu paapa to ni iyara okan gan, ti ni ni iyara ategun - panthās tu koṭi-śata-vatsara-sampragamyaḥ - ati pelu iyara bayi ti e le lo fun araadota-oke odun, ti e ko tun ni ri ibi ti Goloka Vrndavana wa. Sibe, e ko le ri. Panthās tu koṭi-śata-vatsara-sampragamyo vāyor athāpi manaso muni-puṅgavānām (Bs. 5.34). Ko nse wipe awon ācārya tèlè ati awon yoku, pe nwon ko mo. ohun ti o je oko ofurufu, kini iyara, bi a se nsare. E ma se lero oponu, bi igba wipe won ti da nkan sile. Ko je nkankan, koda ko tile nse ikerin-kilasi, idamewa kilasi. Awon oko ofurufu ti won dara wa nibe. Bayi nibi ni awon idaba wipe e le ko oko ofurufu ti o le sise lori iyara ti okan. Aba kan niyi nibi bayi - e dan wo. E lese oko-ofurufu to le sare ni iyara ti ategun. Won ni lero pe ni iyara imole ti a ba le ko oko -ofurufu kan, sibe yi o si gba ogoji egbe gberun odun lati de ori orun togajulo. Won nse lero wipe, ti o ba le see se.

Sugbon bi a ti le f'oju inu wo, awon ti won nsise pelu boluti ati awon eso, bawo ni opolo dindinrin, ti won le ko iru ohun be? Iyen ko le see se. O nilo opolo miran. Awọn yogīs le lọ, awọn yogīs le lọ. gege bi Durvāsā Muni. O si lo si Vaikuṇṭha-loka, O si ri Olorun Visnu tikalarare ni Vaikuṇṭha-loka, lati toro idariji nitoripe ina Olorun nle leyin lati pa. O fi abuku kan vaisnava kan. Itan miran ni yen. Nítorí náà ni ọna yi iyen je ohun ti igbesi aye omo eniyan wa fun gangan. lati ni oye nipa Olorun ati awon agbara Re ati lati se isoji ajose wa atijo pelu Re. Iyen ni owo wa akoko. Sugbon o se ni laanu pe won ti gba ise ninu awon ile ise-irin, awon ise to yato, lati sise bi awon elede ati awon aja, ti o si nba won ni gbogbo agbara je. Ko nse inilara nikan, iwa won na, won nse ise lile gan, bee na lehin igba ti won ba ti sise lile won gbodo mu oti amupara. lehin igba ti won ba ti mu oti, wan gbodo jeran. lehin nkan meji wonyi, won si nilo ibasepo laarin Okurin ati Obirin. Be na ni sise bayi, ni won se pa won mo sinu okunkun. nibi na, awon ese ti Ṛṣabhadeva won yi si nkilo fun wa. O si n ikilo, O nsoro si awọn ọmọ rẹ, sugbon a le ya l'ẹkọ. O so wipe: nāyaṁ deho deha-bhājāṁ nṛloke kaṣṭān kāmān arhate viḍ-bhujāṁ ye (SB 5.5.1). Itumo Kāmān ni awon nkan aye yi tose pataki O le ri awon nkan aini aye rẹ ni rọọrun gan. Nipa riro oko, e o ri awon eyoes. Ti malu ba wa, a si fun yin ni wara O tan. Iyen na to be. Sugbon awon olori ijoba nse eto, wipe ti awon eniyan ba ni ifokan bale pelu iṣẹ agbẹ, awon oka kekere ati wara, ta ni o ma sise ninu ile-ise irin nigba na? Nitorina won nbere owo-ori ki e ma ba le gbe paapa ile- aye to rorun. Ipo nawon nkan ni yi. Ti e ba fe paapa, Awon ijoba ode oni won o ni gba fun yin. Won fi ipa mu yin sise bi awon aja, elede ati kẹtẹkẹtẹ. Bi ipo nkan se ri ni yen.