YO/Prabhupada 0114 - Okurin eni jeje kan tí orúkọ rẹ jẹ Olorun,O si nse akoso gbogbo eniyan



Lecture -- Laguna Beach, September 30, 1972

Nínú iwe mimo Bhagavad-gitā won so wipe,

dehino 'smin yathā dehe
kaumāraṁ yauvanaṁ jarā
tathā dehāntaraṁ-prāptir
dhīras tatra na muhyati
(BG 2.13)

Eyin, emi - gbogbo wa- ni a wa ni iti-mole ninu ara yi.. Emi okan ni mi; emi ni eyin na. Iyen ni imoran Vediki, ahaṁ brahmāsmi: "Brahman ni mi." Iyen tumosi ẹmí.. Kii se Parabrahman, ma ṣe aṣiṣe. Parabrahman ni Ọlọrun. Brahman ni gbogbo wa, ipa ati ese Olorun, awwon erunrun. Sugbon kii se Atobiju, atobiju yato. Gege bi e se je omo orile-ede America, sugbon Mr. Nixon ni àare yin. Sugbon o ko le so wipe "Nitori emi je omo Amerika, nitorina emi ni Ogbeni Nixon." Iyen o ol e sọ. Bakanna ni, iwo, emi, gbogbo wa, Brahman, sugbon ti ko tunmọ si awa ni Parabrahman Parabrahman ni Olorun. Īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ (Bs. 5.1). Īśvaraḥ paramaḥ. Īśvara tumo si oludari. Nítorí náà, gbogbo ọkan ninu wa ni oludari si diẹ l'aàyè. Ẹnikan ndari ìdílé rẹ, ndari ile-ise rẹ, owo, ndari ọmọ-ẹhin rẹ. Ni kẹhin, o wa ndari aja kan. Ti ko ba ni lati sakoso ohunkohun, o si ntọju aja kan lati sakoso, aja ohun ọsin , ológbò ohun ọsin. Nítorí náà gbogbo eniyan fe lati je oludari. Otito oro niyen. Sugbon Oludari Atobiju ni Olorun. Nibi ki-lati npe oludari ni ẹnikan ti o ndari re. Emi le sakoso omo-lẹhin mi, sugbon ẹnikan miran n dari mi, nipa oluko igbala mi. Bee ni ẹnikẹni ko le so pe "Emi ni oludari to gaju." Rara. Nibiyi wa ri awọn ti a npe ni -oludari, dájúdájú oludari si àye diẹ, sugbon oun na ni alakoso. Ṣugbọn nigbati o ba ri ẹnikan ti o je oludari nikan, ti ẹnikẹni ko dari re, oun ni Olorun. Lati ni oye Olorun ko nira pupọ. Gbiyanju lati ni oye wipe gbogbo eniyan ni o ndari, olukuluku ọkan ninu wa, sugbon ni akoko kanna ni dari nipa ẹlo miran. Sugbon a ri eni jeje kan tí orúkọ rẹ jẹ Olorun. O si nse akoso gbogbo eniyan, sugbon ẹnikẹni ko ni dari lori re. Ìyẹn ni Ọlọrun.

īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ
sac-cid-ānanda-vigrahaḥ
anādir ādir govindaḥ
sarva-kāraṇa-kāraṇam
(Bs. 5.1)

Nítorí egbe isokan Olorun yi jẹ ijinle sayensi gidigidi, ti a mu l'aṣẹ ati ti o se ni loye nipa bọgbọn eniyan. Nitorina ti o ba le jowo gba anfani ninu egbe isokan Olorun yi, iwọ yoo ni anfaani. Aye rẹ yoo jẹ aseyori. Ero ti aye rẹ yoo wa ni seese. Ìyẹn ni kan o daju. Ki e gbiyanju lati ka awon iwe wa. A ti ni ọpọlọpọ awọn iwe. E le wa wo , ki e ri ni idaju bi awon omo-eleyin wa se ntesiwaju ninu egbe isokan Olorun. E le gbiyanju lati ko eko lọwọ wọn nipa asepo pelu won O kan dabi ti o ba fẹ di onise-irin, wa wo ile-ise adahunse ati ni asepo pelu awon osise, siseero, ati ki o maa tun di mekaniki, technologist. Bakanna, a ti nsii awọn ile-ijosin wọnyi lati fun gbogbo eniyan ni anfaani lati ko bi lati lọ si ile, bi o ṣe le lọ si ile, ... pada, bi o ṣe le lọ si ile, pada si Metalokan. Ise wa niyen. O si jẹ ijinle sayensi gidigidi ati ni aṣẹ, Vediki. A ti n gba imo yi ni taara lati ọdọ Olorun, Atobiju Eledumare. Ìyẹn ni Bhagavad Gita-. A ti nse fifihan Bhagavad Gita-bi o ti jẹ, laisi awon isokuso. Olorun wi ninu iwe mimo Bhagavad Gita-wipe Oun ni Atobiju Eni-ti Metalokan. Awa na ngbe awọn imọran kanna sile , pe Atobiju Eni-ti Metalokan ni Olorun. A o yi nkankan pada. Olorun wi ninu iwe mimo Bhagavad Gita-, "Di olufokansin mi" Fi Mi sinu ero re nigbagbogbo. Teribale fun Mi." A nkọ gbogbo ènìyàn wipe "E fi Olorun sinu ero yin nigbagbogbo - Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare/ Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare." Nipa kike pa Hare Krishna mantra yi, e o maa se ero Olorun nigbagbogbo.