YO/Prabhupada 0115 - Owo mi ko ju lati se ijise Olorun fun awon eniyan



Lecture -- Los Angeles, July 11, 1971

Nitorina, inumi dun pe awon omo-okurin wonyi si n ranmi lowo ni itankale isokan Olorun yi, Olorun yio si bukun wọn. Emi o jamo nkankan. Mi o si l'agbara. Owo mi ko ju lati se ijise Olorun fun awon eniyan. O kan da bi olufiwe-ranse : owo re ni lati pin awon leta. Kole ṣeduro fun nkan towa ninu leta Esi... Leyin kika leta na, eniti won ko leta si le ni ero kan, sugbon iyen kii se idalohun ti olufiwe-ranse. Bákan náà, ojuse mi ni, ohun ti mo ti gba l'atowo d'owo awon ojise, lat'odo Oluko mi. Mo kan nse afihan ohun kanna, sugbon laisi eyikeyi idaru-dapo. Owo mi niyen. Ojuuṣe mi niyen Mo gbọdọ se afihan awon nǹkan ni ọna kanna ti Olorun se gbekalẹ gangan bi Arjuna se gbekalẹ, bi awon ācāryas wa ti gbekalẹ, Oluwa Caitanya, ati ni ìkẹyìn Oluko igbala mi, Bhaktisiddhānta Sarasvatī Gosvāmī Mahārāja. Nítorí náà, bakanna, ti e ba gba isokan egbe Olorun pelu emi kanna, ti e ba pin fun awon eniyan miiran , fun awon ara orile-ede yin, o dájú pé yio je munadoko, nitori ko si idaru-dapo nibẹ. Ko si igberaga. Ko si iyanje. O jẹ ẹmí ifokansin mimo. Ki e kan fi se iwa wu ati ki e si pin kà. Aye yin yio si wa lógo.