YO/Prabhupada 0118 - Iwaasu wa ki se ohun ti o soro rara



Lecture on SB 1.5.8-9 -- New Vrindaban, May 24, 1969

Ẹni ti o ba jowo emi re fun Krishna, tabi Ọlọrun, jẹ olorire gidi gan. Bahūnāṁ janmanām ante jñānavān māṁ prapadyate (BG 7.19). Ẹni ti o jowo emi re, oun kii se eniyan lasan . O si wa tobi ju gbogbo ọjọgbọn, gbogbo awon amoye, gbogbo awon yogis, gbogbo awon karmīs. Akikanju eniyan, ni eni ti o ba jowo emi re. Nitorina o je majemu pataki. Nítorí ẹkọ wa, egbe ifokansin Olorun , láti s'afihan iwe mimo Bhagavad-Gita gege bi o ti ri, jẹ ilana ti nkọ eniyan bi a se ni lati teribale fun Krishna, tabi Ọlọrun. O pari. Nitorina ni Krsna si so wipe ifokan tanni ni... ko si eni ti o ma gba. Sugbon ti enikan ba gb'ewu na "Jowo teriba ..." Nítorí náà, nigba ti o ba lọ lati waasu, o si mọ awọn oniwaasu ti won ma n' ni kolu. Gege bi Jagāi-Mādhāi se ko lu Nityānanda Prabhu. Ati nigbati won kàn Jesu Kristi Oluwa mọ agbelebu, pa ... Bẹ naa ise oniwaasu ni ewu. Nitorina Olorun wí pé, "Awon osise pápá wonyi ti won gba išẹ waasu ti Bhagavad-Gita bi o ti ri, yi, won je eni ọwọn si mi pupo pupo. Won s'owon si mi pupo. " Na ca tasmān manuṣyeṣu kaścin me priya-kṛttamaḥ (BG 18.69). "Ko si eniti o s'owon si mi ju ti eni ti o wàásù ti igbekele ododo fun awọn eniyan."

Nitorina ti a ba fẹ se ife Olorun, a ni lati gba ewu yi. Olorun, oluko igbala. Oluko igbala mi gba ewu yi lati se ise iwaasu, osi fun wa lokun lati le se ise waasu na. Awa na tun n'be yin láti gba iṣẹ ìwàásù yi. Bẹ ni iṣẹ ìwàásù yi, sibẹsibẹ, mo fe sọ pé, mo fe sọ pé, a nse bi alaini... Bi alaini - ki se pe ko dara, sugbon gbimo pe emi ko leko pupo. Gẹgẹ bi ọmọkunrin yi . Ti mo ba rán fun iṣẹ ìwàásù , ko leko pupo bayi. Kii se amoye. Kii se omowe. Sugbon oun naa le wàásù. Oun naa le wàásù. Nitori iwaasu wa ki se ohun ti o soro rara. Ti a ba lọ lati enu ilekun si ilẹkun ti a kan nbeere lowo awon eniyan, "Ayànfẹ mi Ọgá, e kepe Hare Krishna." Ti o ba si je eni ti o ni ilosiwaju die, "Jọwọ gbiyanju lati ka iwe imoran ti Oluwa Caitanya. O dara pupo. A se yin ni anfaani." Awọn ọrọ mẹta mẹrin yi yio sọ nyin di oniwaasu. Se eyi je nkan ti o le ni sise? O le ma je eniti o kẹkọọ pupo, Ọmọwé ti o dara, oludero ti o dara. Ki o kan sọ pé... Ẹ lọ lati ilẹkun si ilẹkun : "Ayànfẹ mi Ọgá, eniyan ti o kẹkọọ pupo ni yin. Fun iwon igba die, e da eko yin duro. Kì e kan kepe Hare Krishna."