YO/Prabhupada 0121 - Nítorína ni ipari Olorun ni O n ṣiṣẹ



Morning Walk At Cheviot Hills Golf Course -- May 17, 1973, Los Angeles

Kṛṣṇa-kāntī: Awọn onisegun ti nse ' iyanu fun iru iseda ọpọlọ eniyan.

Prabhupāda: Beeni, Beeni.

Kṛṣṇa-kāntī: O ya won lenu.

Prabhupāda: Sugbon won nse ' were. Kii se ọpọlọ ni o n ṣiṣẹ. Emí ọkàn ni o n ṣiṣẹ. Ohun kanna: awọn ẹrọ kọmputa. Awọn were yio ro pe ẹrọ kọmputa ni o n ṣiṣẹ. Rárá o. Eniyan n ṣiṣẹ. O si nti awọn bọtini, lẹhinna o ṣiṣẹ. Bibẹkọ, kini iwulo ti ẹrọ yi? Ti o ba tọju ẹrọ na fun egbegberun odun, ko ni ṣiṣẹ. Nigba ti elomiran ba wá, ti o ti bọtini, lẹhinna ni yio ṣiṣẹ. Nítorí náà tani o n ṣiṣẹ? ẹrọ lo n ṣiṣẹ tabi eniyan lo n ṣiṣẹ? Awọn eniyan na tun jẹ ẹrọ miran . O si n nṣiṣẹ nitori oju ti Emi Mimo, Ọlọrun ti o wa nibe. Nitorina, ni igbehin oro, Ọlọrun ni O nṣiṣẹ. Okú eniyan ko le ṣiṣẹ. Iwonba asiko teyan le gbe ninu aye yi gbarale iwonba asiko ti Paramātmā ba wa ninu ara eyan na Koda bi ātmā, emi, ba wa nibe, ti Emi Mimo ko ba fun l'ogbon ko le ṣiṣẹ. Mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca (BG 15.15). Ọlọrun nfun mi loye, "Iwọ ti bọtini yi." Nigbana ni mo ti bọtini yi. Nítorína ni ipari Olorun ni O n ṣiṣẹ. Elomiran, eniyan ti ko l'eko ko le wá lati ṣiṣẹ le lori nitori ko l'oye. Ati enikan pataki ti o ko eko , o le ṣiṣẹ. Bẹ ni nkan wọnyi se nboju lọ . Nigbeyin o je ise Olorun. Ohun ti o nse iwadi, ọrọ sisọ rẹ, iyen na tun je sise ti Olorun. Olorun fi fun nyin ni ... Iwọ, ki o gbadura si Olorun fun ohun elo yi. Olorun nfi fun nyin. Nigba miran ni o le ri lairotẹlẹ ti ṣàdánwò jẹ aseyori. Nítorí náà, nígbàti Olorun rí i pé e ti wa ni yonu pupo ninu ṣàdánwò, "Ko buru ṣe ." O kan dabi igbati Yaśodā Mā gbiyanju lati di Krishna, ṣugbọn ko le ṣe. Ṣugbọn nigbati Krishna gba, o si ṣee ṣe. Bakanna, airotelẹ yi tumo si pe Olorun se iranlọwọ fun ọ: "Ko buru , o ti ṣiṣẹ àṣekára pupo, gba esi yi." Ohun gbogbo ni Olorun. mattaḥ sarvaṁ pravartate (BG 10.8). Won ti se lalaaye. Mattaḥ smṛtir jñānam apohanaṁ ca (BG 15.15). Ohun gbogbo ni o nti odo Olorun wa.

Svarūpa Dāmodara: Wọn si wí pé, "Olorun kò fun mi ni awọn igbesẹ to yẹ lati ṣe awọn adanwo na."

Prabhupāda: Bẹẹni, o si fun nyin. Bibẹkọ bawo ni e se nṣe . Ohunkohun ti e ba nṣe, iyen jẹ nipa oore ọfẹ Olorun. Ati ti o ba si tun nni oju rere, yiO si fun nyin ni awọn ohun elo pupo sii. Olorun yio fun nyin ni awọn ohun elo , yio si fi ojurere Rẹ han yin, gẹgẹ bí ẹnyin ti fẹ, ko ni ju be lo. Ye yathā māṁ prapadyante tāṁs tathaiva... Niwọn tuwonsi ti e ba se teriba si Olorun, awọn oye ati ogbon na yio si wa. Ti e ba se teriba ni kikun, ni kikun na ni oye ati ogbon na yio si fi wá. Bi o ti wa ni ninu ni iwe mimo Bhagavad-Gita. Ye yathā māṁ prapadyante tāṁs tathaiva bhajāmy aham (BG 4.11).