YO/Prabhupada 0134 - Ema fiku pa, sugbon eyin fiku pa awon eda



Morning Walk -- October 4, 1975, Mauritius

Prabhupāda: Awon alaafu onigbagbo beere lowomi pe " kilode ti esin wa seni iloseyin? kini nkan tase?" Mo sofun wan, " kilo ku teyin otii se?" (Erin)

Cyavana: Beeni.

Prabhupāda: lati ibere leti fehin si awon itosona Krisiti, 'Ema fiku pa', sugbon eyin fiku pa awon eda. kilo ku teyin otii se?

Elesin 1: wan sowipe Okurin gbudo ni idari lori gbogbo awon eranko, nitorina..

Prabhupāda: Nitorina egbudo pa wan lati le jewan, iru ironu wo niyen. " Ti baba awon omode ba ni idari lori wan, se iyen sowipe Baba na gbudo je awon omo re." Awon asiwere wanyi, wansin pe ara wan ni Olori esin.

Puṣṭa Kṛṣṇa: Prabhupāda, taban rin lori ilele tabi tawa ban mii awa na fiku pa awon eda, ti Olorun ba de sowipe "Ema fiku pa awon eda", se ise tawa o le se koniyen?

Prabhupāda: Rara. Ema moomo fiku pa awon eda. sugbon teyin ooba mo, wan le dariji yin. ...na punar baddhyate. Āhlādinī-śakti, agbara idunnu. Agbara idunnu yi kole fun Krsna ni inira. sugbon o le fun awon eyan ni inira. Inira loje funwa, awon eda. Osupa Wura ( oruko ile-oti?), gbogbo eyan lon losibe lati gbadun sugbon oun wonu ese. Nitorina iru ise bayi kole funni idunnu, inira loma fun. inira to po lowa ninu eto, imọ akọ tabi abo Egbudo toju awon omode, egbudo bimo. Inira loje. Egbudo sonwo fun ibimo na ni ile-iwosan, omo na asi losi ile-iwe, toba ni aisan, egbudo sonwo fun ologun Seti ri wipe, idunnu lati asepo laarin okurin at'obirin, inira to p lon tele. Tāpa-karī. Agbara lati gbadun yi wa ninu gbogbo awon eda sugbon nionba kekere, sugbon lesekese tonba lo, inira ma tele. agbara kanna lowa ni ijoba orun, Ijo Krsna pelu awon gopi, kosi inira nibe. Igbadun loje. (iduroo) ...Tawa ba jeun toda, o lee funwa ni'nira

Cyavana: Aisan re ma posi.

Prabhupāda: Aisan na ma posi. Nitorina tapasya ni ile-aye yi wa fun, taba le fi gbogbo eleyi sile fun ara wa, iyen lodaju.