YO/Prabhupada 0159 - Nisin wan s'eto lati ko awon eyan bonsele sise gan



Lecture on SB 5.5.15 -- Vrndavana, November 3, 1976

Ni awon Ilu to tobi bi Calcutta, Bombay, London, NewYork, gbogbo eyan lon sise gan. Konsepe ninu awon ilu to tobi wanyi awon eyan le ri ounje wan je lai sise to le. Rara. Gbogbo eyan gbudo sise. Gbogbo eyan den sise gan. Se rope gbogbo eyan wa lori ipo kanna? Rara. Kolese se. ipin. Ipin. Okurin kan sise gan laaro tit i daale, fun wakati mẹrin-le-logun; sugbon capātīs meji pere lonri gba, otan. Awa ti ri ni Bombay. Iru aye ton gbe si baje tojepe, lasan gan atupa kẹrosínì lon lo. Ibi ton gbe si doti gan. Se iyen jewipe gbogbo eyan ni Bombay lon gbe aye igbadun? Rara. Gege na, nigbogbo ilu wanyi. Kolese se. Kosi besele ni liosiwaju ninu oro-aje lati ise nikan. Kolese se. teyin ba sise tabi teyin o ba sise, ounkooun teba mani loma wa siyin. Nitorina loye ka lo agbara wa fise ... mal-loka-kāmo mad-anugrahārthaḥ. Agbudo lo agbara yi lati fi fun Krsna ni itelorun. Nkan toye ka se niyen. Agbudo lo agbara wa fun awon nkan bayi, emalo ni ilokulo nitoripe " efi ki inu yiin dun. Moma se bayi, moma se toun. Ma pa owo bayi..."

O dabi irohin amokoko. Amokoko ti bere sini s'eto nkan tofe se. Oni awon koko die, osin s'eto nkan to fese, " Nisin mo ni koko merin ti mo fe ta. Moma j'èrè tin ba ta wa tan. Lehin na moma ni koko mewa. Lehin na a ta awon koko mewa wanyi, ma j'èrè si. Tin ba tini koko to po to ogun tabi ọgbọn, tabi ogoji. Bayi moma di Olowo. Toba ti ya , mole fe iyawo sile, ti iyawo mi o ba ni igboran simi , ma fun n'Iṣakoso bayi. To ba se aigboran, ma fun niipa bayi." Nipa to naa ese, o fun ikoko re nipa, ikoko na si wo lule. (Erin) gbogbo ala toni ti tan. Seyin ti ri bayi? Gege na, awa na laala. Pelu awon ikoko die tani, gbogbo wa laala " Awon ikoko yi ma posi, wan posi, wan posi," lehin tan. Ema sironrun, oyeke s'eto. Guru, ati Oluko ninu eto emi, ati Ijoba gbudo foju si lati jewipe " Awon oniranu yi o gbudo s'eto kankan. "Awon oniranu wanyi o gbudo seto kankan lati ni idunnu." Na yojayet karmasu karma-mūḍhān. karma-jagat niyen, aye yi. Bi ile aye yi se ri niyen. Wanti ni iwa tele, kini iwulo? Loke vyayāyāmiṣa-madya-sevā nityāstu jantuḥ. Gege bi aye ako ati abo. Iwa adayeba ni Imo ako ati abo je. Eyan o ni lati losi ile-iwe eko giga lati mo bonse gbadun imo ako ati abo. iwa adayeba loje. Koseni ton ko enikonkon lati rerin, tabi lati sukun tabi lati ni asepo laarin Okurin ati obirin." Oni owe Bengali kan to sowipe, iwa adayeba loje. Awon eyan o ni lati losi ile-iwe fun karma yi. Nisin wan s'eto lati ko awon eyan bonsele sise gan. Ilokulo asiko wa niyen. Awon ile-iwe gbudo ko awon eyan bonsele ni imoye Krsna, konse fun iru awon nkan bayi. Ilokulo asiko ni gbogbo eleyi je, nitoripe eto yi o le ni ilosowaju. Tal labhyate duḥkhavad anyataḥ sukhaṁ kālena sarvatra gabhīra-raṁhasā. Ofin Iseda ton sise niyen, Prakṛteḥ kriyamāṇāni guṇaiḥ karmāṇi sarvaśaḥ (BG 3.27).

Nitorina ninu awujo Veda awon ni itelorun ninu ipo tonwa laye, awon brāhmaṇa, kṣatriya, vaiśya, śūdra. Ounkoun toba ni lati ore-ofe Olorun, o telorun bayen. Wansi lo agbara wan fun ise toma je kon ri ore-ofe Krsna gba. Nkan tafe niyen, basele teriba fun Krsna. Lehin na ahaṁ tvāṁ sarva-pāpebhyo mokṣayiṣyāmi (BG 18.66). Ipaari niyen. Ni Orile- ede India, ati riwipe.. Awon aalufa, ṣis, ton ko orisirisi iwe to po, inu ahere lon gbe. awon Oba tabi ksatryia nikan lon gbe ninu awon aafin. Awon eyan to ku, ile aye to rorun lon gbe. Konsepe wan lo asiko wan ni ilokulo fun ilosiwaju oro-aje, tabi ile-giga, Awujp Veda ko niyen. Awujo awon esu leleyi.