YO/Prabhupada 0175 - Lati so awon kuroo di siwani ni itumo dharma



Lecture on SB 1.8.33 -- Los Angeles, April 25, 1972

Awon iwe tio ni nkankan se pelu Olorun, tad, tad vayasam tirtham, Iru iwe wanyi dabi ibi ti awon eye kuroo tin gbadun. Niboni eye kuroo man gbadun? Ninu ile- idoti. Sugbon eye siwani, inu omi to mo ninu ogba to da lontin gbadun. laarin awon eranko, iyasoto na wa. Egbe awonn eye siwani ati egbe awon eye kuroo. Iyasoto t'aseda. Eye kuroo ko ni loba awon eye siwani. beena ni awon eye siwani o ni lo ba awon eye kuroo. gege na ninu awujo awon eda, ani awon eyan toda bi kuroo ati siwani Awon okurin ton dabi siwani ma wa sibi nitoripe gbogbo nkan ti awan se daju, imoye to da, ounje to da, eko to da, aso toda, okan to da, gbogbo nkan to da. sugbon okurin ton dabi eye kuroo wan losi ile kumọ, tabi akojo idaraya, ton jo ni ihoho, ati orisirisi nkan bayi. Se ti ri bayi. Gege na fun awon eyan ton dabi eye siwani ni egbe imoye Krsna yi wa fun. Kon se fun awon Okurin ton da bi eye kuroo. Rara. Sugbon awa le so awon kuroo di siwani. Imoye wa ni yean. Awon eyan ton dabi eye kuroo wanti huwa bi eye siwani nisin. A le se iru nkan bayi. Anfanni imoye Krsna niyen. Ninu ile aye yi, awon siwani ti di kuroo. Krsna sowipe: yada yada hi dharmasya glanir bhavati (BG 4.7). awon eda wa ninu ewon ara eda tani, sugbon o si fe gbadun ara re, ara kan si keji, ara kan si keji, ara kan si keji. Ipo wa niyen. Sugbon lati so awon kuroo di siwani ni itumo dharma. dharma niyen. Gege bi okurin ti o keko, ti o l'asa, sugbon toba keko gbogbo iwa yi letan. pelu eko, ati ikẹkọ. O lese se nitoripe ani ara eda eyan. Kosi bi mosefe fun aja ni ikẹkọ toma so di elesin. Iyen ti le ju. O se se na. Sugbon mi o ni iru agbara bayi. Oluwa Caitanya Mahaprabhu ti se. Nigbaton koja ninu igbo , Jharikhanda, awon ẹkun, awon ejo, awon agbọnrin, gbogbo awon eranko, wan di elesin Olorun. Caitanya Mahaprabhu le se iru nkan bayi..nitoripe Olorun fun ara re loje. O le se ohunkoohun. Awa o le se iru nkan bayi. Sugbon awa le sise ninu awon awujo eyan , kosi isoro kankan teyan na baje elese to ga gan. Toba le tele awon ilana taba fun, oun na le ya si mimo. Nkan ton pe ni dharma niyen. Lati da awon eyan pada si ipo alakoko wan nitumo dharma. dharma niyen. Orisirisi ipo lowa. sugbon ipo t'alakoko niwipe nkankanna la je pelu Olorun, toba de yewa pe nkankan laje pelu Olorun, ipo aye wa niyen. nkan ton pe ni ipo brahma-bhuta leleyi (SB 4.30.20), pe ani oye nipa imo Brahman.