YO/Prabhupada 0195 - Ton l'agbara l'ara, ni okan, ni ipinnu lati losiwaju



Lecture on SB 7.6.5 -- Toronto, June 21, 1976

Pradyumna: Isotunmo: " Nitortina, taba wa ninu ipo ile aye yi, bhavam asritah, enikeni toba fe se iyasoto laarin nkan tio da ati nkan to da gbudo gbiyanju lati le de ipo to gaju ninu ile-aye yi, afi t'ara wa ba wa l'aaye, tio sini run sile pelu ojo arugbo."

Prabhupāda:

tato yateta kuśalaḥ
kṣemāya bhavam āśritaḥ
śarīraṁ pauruṣaṁ yāvan
na vipadyeta puṣkalam
(SB 7.6.5)

Ise fun awon eda eyan leleyi, pe śarīraṁ pauruṣaṁ yāvan na vipadyeta puṣkalam. T'ara ba lagbara tosi wa l'aaye ale sise dada lojojumo, nkan pataki ni ilera to da, egbudo lo dada. Egbe imoye Krsna yi fun awon eyan to yole ko loje. Rara. Fun awon okurin to l'agbara lo wa fun: Ton l'agbara l'ara, ni okan, ni ipinnu lati losiwaju - wan l'agbara ninu gbogbo nkan - opolo wan gan l'agbara. Fun iru awon eyan bayi lowa fun. Nitoripe agbudo jise opin aye to gaju. Sugbon ibanuje towa niwipe awon wanyi o mo nkan ti ipo to gaju ninu aye yi je. Nisin nkan tose ri ni: awon eyan o mo nkan ti ipinnu aye yi je. Enikeni toba wa ninu ile-aye yi, owa ninu maya, itumo re niwipe, kole mo nkan ti ile-aye wa fun. Na te viduḥ, awon omo, svārtha-gatiṁ hi viṣṇu. Svārtha-gati. Awon eyan o mo ju ara wan lo. Wan sowipe Imotara eni l'ofin alakoko ninu ile-aye yi. Sugbon awon eyahn yi o mo nkan ti imotara eni je. Kada ko pada losi ijoba orun - nkan toje imotara eni - a pada wa sinu ile aye bi aja. Se imotara eni leleyi je? Sugbon awon eyan yi mo. Bi ofin ile aye yi sen sise, awon eyan yi o mo. Na te viduḥ. Adānta-gobhir viśatāṁ tamisram. Matir na kṛṣṇe parataḥ svato vā.

matir na kṛṣṇe parataḥ svato vā
mitho 'bhipadyeta gṛha-vratānām
adānta-gobhir viśatāṁ tamisraṁ
punaḥ punaś carvita-carvaṇānām
(SB 7.5.30)

Imoye Krsna niyen... Matir na kṛṣṇe. Awon eyan o fe yi okan wan si imoye Krsna. Kilode? Matir na kṛṣṇe parataḥ svato vā. Pelu ilana awon eyan imi. Gege bi awa sen gbiyanju lati pin imoye Krsna yi ninu gbogbo agbaye, paratah. Svato, itumo svato ni funarare. Pelu ise t'araeni. Gege bi monse ka Bhagavad-gītā tabi Śrīmad-Bhāgavatam ati awon iwe mimo Veda. gege na, matir na kṛṣṇe parataḥ svato vā. Mitho vā, itumo mitho vā ni "akojopo." Nisin awon feran awon akojopo gan. gege na eyan o le ni imoye Krsna lati ise agbara re, tabi lati ipinnu awon elomi, tabi loati awon akojopo. KIlode? Gṛha-vratānām: nitoripe idi fun aye re ni wipe " Mofe joko sinu ile yi." Gṛha-vratānām. Ile-aye oniile nitumo Grha, ara nitumo grha, agbaye yi nitumo grha. Awon grha to po gan lowa, awon nla atio kekere.