YO/Prabhupada 0305 - We Say God is Dead. So We Have to Uncover Our Eyes From this Illusion



Lecture -- Seattle, October 2, 1968

Prabhupāda: E tesiwaju.

Tamāla Kṛṣṇa: " Awon eda dabi molekulu lati ina orun, sugbon Krsna dabi ina gbigbona orun. Oluwa Caitanya ti juwe awon eda bi ina kekere ton jade latinu ina Olorun de dabi ina orun. Oluwa si mu ese-iwe yi lati Visnu-Purana, wan si salaaye ninu e wipe gbogbo nkan ninu agbaye yi, lati agbara Olorun lonti jade. Fun apeere, gege b'ina sen jade lati ibikan sen funwan ni'na ati oru, gege na, Olorun le wa nibi kan ni ijoba re l'orun, sugbon a si le ri agbara re nibikibi."

Prabhupada: Nisin, eleyi rorun gan. Egbiyanju lati ni oye nipa re. Gege bi atupa yi, ibi kan lowa sugbon ina re tan kakiri ninu gbogbo yara, gege na ounkoun teba ri, toje iyanu agbaye yi, agbara Olorun loje. Sugbon Olorun wa nibi kan soso. Iwe Brahma-saṁhitā ti salaaye wipe: govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi. Eyan loje. Gege Olori-ede yin Mr. Johnson, o joku ninu yara re ni Washington sugbon a le ri gbogbo agbara re ninu gbogbo orile-ede na. Ti iru nkan bayi lesese ninu aye tawa yi, gege na Krsna, tabi Olorun, eda to gaju lese, O si wa nibi kan soso, ni Vaikuntha, tabi Ijoba Olorun, Sugbon agbara re n'sise. Apeere imi to wa ni orun. Ele ri wipe orun wa nibi kan soso, sugbon ina orun wa lori gbogbo agbaye. Ina orun yi wa ninu yara yin. gege na, ounkoun teyin ban lo, ifihan agabra Olorun ni gbogbo wa je. Awa o yato si. sugbon ti sanma maya ba ti bomi loju kosi bi mose le ri ina orun. gege na, ti atinuda ile-aye ba ti bomi, kosi bimo sefe ni oye nipa Olorun. Lehin na awa ma sowipe Olorun ti ku. Gege na agbudo laa oju wa lati nu itanraeni wanyi. Lehin na ele ri Olorun fun ara yin. " Olorun leleyi." Beeni. Ninu Brahma-samhita wan ti salaaye wipe,

premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena
santah sadaiva hrdayesu vilokayanti
yaṁ śyāmasundaram acintya-guna-svarūpaṁ
govindam ādi-purusaṁ tam ahaṁ bhajāmi
(Bs. 5.38)

Olorun gbogbo agbaye yi, Śyāmasundara l'oruko re. Śyāmasundara. To dudu nitumo Śyāma, sugbon to lewa gan. Eda to lewa gan yi, eda to gaju, Krsna, gbogbo awon eyan mimo lon foju ri nigbogbo 'gba. Premāñjana-cchurita-bhakti-vilocanena. Kilode ton sen ri? Nitoripe wanti laa oju wan pelu ipara ife si Oluwa. Gege b'eyan to ba ni irora oju, o le fi ipara lati awon ologun fi pa, nigbato ba ya, oju na asi bere sini rtian dada, eleri awon nkan dada. gege na, ti awon oju lasan teni ba ti ni ipara ife si olorun yi, lehina lema ri Olorun, " Olorun leleyi," Eyin o ni sowipe Olorun ti ku. Sugbon egbudo yo ibora yi kuro egbudo gba egbe imoye Krsna yi sokan teba fe yo ibora yi kuro.

Ese pupo.