YO/Prabhupada 0307 - Not Only Thinking of Krishna, But Also Working for Krishna, Feeling for Krishna



Lecture -- Seattle, October 2, 1968

Prabhupada: O ti soro okan re, " Oya jeka lo si egbe ISKCON ton sese daale," ese yin ma rin wa sibi. Ironu, Ifura, tokantokan, awon ise okan wa leleyi. gege na okan man ronu, asi fura, lehin na a sise. Gege a egbudo gbokan le, keesi ronu nipa Krsna, sugbon egbudo sise fun Krsna, kee ni ifarasi Krsna. Sasaro to pe niyen. Nkan ton pe ni samadhi leleyi. Okan yin o le jade. Egbudo jeki okan yin ko bale ronu nipa Krsna, keeni ifara si Krsna, ke sise fun Krsna. Sasaro to pe niyen.

Okurin(2): Ki lema se pelu oju yin? Sema paade?

Prabhupada: Beeni, ikan ninu awon iye-ara ni oju wa je. Iye-ara wa to gaju l'okan wa je, labe bãlẹ yi, asi ni awon komisona tabi awon olori gege na oju, owo, ese, ahon, awon iye-ara mewa gbogbo wan lon sise labe idari okan wa. lati iye-ara wa ni okan man sise. Nitorina afi teyin ba jeki awon iye-ara yin sise gege bi okan yi, kosejo pe eyin ni ilosiwaju. Idamu ma wa. T'okan yin ban ronu nipa Krsna sugbon oju yin ri nkan imi, Idamu ma wa. Egbudo gb'okan yin le Krsna, lehin na awon iye-ara to ku ma sise fun Krsna. Bhakti niyen.

sarvopādhi-vinirmuktaṁ
tat-paratvena nirmalam
hṛṣīkeṇa hṛṣīkeśa-
sevanaṁ bhaktir ucyate
(CC Madhya 19.170)

Hṛṣīka, iye-ara nitumo hṛṣīka. teyin ba fi awon iye-ara yin ninu ise oga iye-ara gbogbo wa.... Hrsikesa ni oruko imi ti Krsna, tabi olori iye-ara wa. Itumo iye-ara niwipe, edakun ejeko ye yin. Gege bi owo wa. Owo wa n'se dada, sugbon ti owo yi ba rọ tabi ti Krsna ba yo agbara re kuro, lehin na owo yin o le wulo mo. Kosi besele yipada. Nitorina oga ko leje s'owo yin. Eyin ronu pe "Emi ni oga owo mi nimoje." Sugbon niotooro oga ko leje. Krsna ni oga. Nitorina teyin ba jeki iye-ara yin sise fun oga gbogbo iye-ara wa, nkan ton pe ni bhakti niyen, ise ifarasi Olorun. Nisin awon iye-ara mi nsise funmi. Mosi ronuwipe " Fun igbadun ara mi tabi iyawo mi ni ara yi wafun," awon orisirisi nkan to po, " orile-ede mi, awuujo mi." Eto yiyan leleyi. Sugbon teyin ba wa sori ipo emi, oma ye yin wipe " Nkankanna nimo je pelu Eledumare; nitorina gbogbo nkan ti mon se ni lati fun Eledumare nitelorun." Bhakti niyen. Sarvopādhi-vinirmuktam (CC Madhya 19.170), igbala lati gbogbo awon eto yiyan. Ti iye ara yin ba yasi mimo, ati nigba teyin ba sise fun olori iye-ara gbogbo wa, nkan ton pe ni ise ninu imoye Krsna niyen. Kini ibeere yin? Lati sasaro, agbudo jek'okan wa sise bayi. Lehin na a wa ni pipe. bibeko, okan wa o le duro sibi kan Okan wa o le duro sibi kan nitoripe iwa to ni niyen, iwa ironu, ifura ati ise tokantokan. gege na egbudo fun okan yin leeko lati ronu nipa Krsna ema ni ifarasi Krsna, ema sise fun Krsna. Lehin na samadhi niyen. Sasaro pipe niyen.