YO/Prabhupada 0329 - Kill a Cow or Kill a Vegetable, The Sinful Reaction is There



Room Conversation -- April 23, 1976, Melbourne

Mr. Dixon: Ofin pe ki awon eyan ma jerena, se lati otito oro wipe awon erank na l'emi...

Prabhupada: Awon efo gan l'emi.

Mr. Dixon: Beeni. Mon bere nitoripe morowipe awon eranko ni ipo to gaju awon efo lo abi?

Prabhupada: Kosejo ipo to gaju. Imoye wa niwipe iranse Olorun laje. gege na Olorun gbudo jeun kato jeun. Ninu iwe Bhagavad-gita.. Ema ri ese-iwe yi. Patraṁ puṣpaṁ phalaṁ toyaṁ yo me bhaktyā prayacchati (BG 9.26). gege beyin se wa sibi. Tin ba fe funyin ni nkan je, oye kin bere lowo yin, "Mr. Nixon, ir ounje wo lefe?" Eyin na ma sofunmi, " Nkan bayi bayi nimo fe." Lehin na, ma fun yin ni nkan teba bere, inu yin a si dun. Gege na Krsna wa ninu ile-adura wa, awa na sin duro lati fun ni nkan to ba fe?

Guru-krpa: " Teyan ba fi ife ati ifarasi fi funmi mi ni ewe, idodo,, eso tabi omi, masi gba be."

Prabhuada: Patraṁ puṣpaṁ phalam.. Oun bere awon nkan to jepe enikeni le fun. ewe kekere, patram, idodo, puspam, eso kekere, ati omi die tabi wara. Nkan tan fun niyen. Ale se nkan orisirisi pelu awon nkan merin wanyi, patraṁ puṣpaṁ phalaṁ toyam (BG 9.26), lehin ti Krsna ba jeun tan , awa na ma jeun. Iranse laje, ounje ti Krsna ma jeku lawan je. Awa okin se alai-jeran tabi awon ton jeran. Prasad-ian niwa. Awa o ronu efo tabi eranko, nitoripe teba fi ku pa oukoun egbudo jiya fun. gege bi ofin iseda se so, awon eranko, ti o lowo ounje lonje si awon eranko ton lowo. Eranko pelu owo lawa na je. Awon eda eyan, eranko pelu owo na niwa, eranko niwan - sugon wa l'ese merin, ko sowo kan kan. awon eranko ti o lese, efo niyen je. Apadāni catuṣ-padām. Awon erank ti wan o lese ounje lonje fun awon ton lese merin. gege awon maalu sen je koriko, beena ni awon agutan na sen je koriko. Gege kosi nkan nla pe eyan je'fo. Awon agutan ati maalu niyi ju wa lo, nitoripe awon o kin je ju koriko lo. Awa o se iwaasu fun awon eyan lati di maalu tabi agutan. Rara. Awan sewaasu kon di iranse Krsna. gege na ounkoun ti Krsna ba je, awa na ma je. Ti Krsna ba sowipe " E funmi leran, ati eyin," ama fun, awa na asi je. Gege na ema rowipe awa fe ki gbogbo eyan di alai jeran. Rara. Imoye wa koniyen. Nitoripe eyin fiku pa awon eda, kobaa je eranko tabi ewe. Sugbon egbudo fiku pa teba fe gbe ninu aye yi, ofin iseda niyen.

Mr. Dixon: Beeni.

Prabhupada: Gege na ona yen ko lawa fe gba.

Mr. Dixon: Kilode teyin sen sowipe dandan ni..

Prabhupada: Ofin loje, ema jeran nitoripe agbudo toju awon maalu fun wara. Teba si pa wan je, nibo lati fe ri wara?

Mr. Dixon: Gege na wara se pataki gan.

Prabhupada: O se pataki gan.

Mr. Dixon: Ninu eto ounje fun gbogbo agbaye, se ile aye a da toba jewipe awon eyan o jeran mo.

Prabhupada: rara, Wara se pataki gan. Awon ounje imi toni ajira na se pataki. gbogbo e si wa ninu wara.

Mr. Dixon: Se ko lese se ke ri gbogbo awon ajira yi ninu awon woru irugbin?

Prabhupada: Ninu woru irugbin, rara. Sitasi lo wa ninu wan. Gege bi sayensi iwosan se so, oye ka je ounje merin: awon sitasi, awon carbohydrate, awon amuradagba ati awon ora. Ounje to pe niyen. teba si je , iresi, dal ati oka, ele ri awon nkan wanyi. Oka ati ewa ni awon nkan amuradagba. wara na sini nkan amuradagba. Awon amuradagba wanyi si se pataki gan funwa. A le ri ora ninu wara na. ora na se pataki awon efo, carbohydrate ati sitasi. teba se ounje pelu gbogbo nkan wanyi, inu yin ma kun. teba si fun Krsna, asi ya si mimo. Lehin koni si ese kankan ninu e mo. Biboko, teba pa awon efo, ese niyen na nitoripe oun na lemi. eyin o gbudo fi ku pa elomi. Suggbon egbudo wa laaye. Ipo tiyin niyen. Ona abayo to wa ni ke je prasadam. Ti ese ba wa teyan ba je efo tabi era, eni ton je loma jiya. Awa kon je ajeku, otan.