YO/Prabhupada 0393 - The Purport to Nitai Guna Mani Amara



Purport to Nitai Guna Mani Amara

Orin Locana Dāsa Ṭhākura, imusin Oluwa Caitanya Mahaprabhu loje. O ti ko orisirisi iwe lori aye ati eko Oluwa Caitanya mahaprabhu. O sowipe Oluwa Nityananda ni awon amuye to dara gan, guṇa-maṇi. Itumo Guṇa-maṇi ni iyebiye gbogbo amuye to dara. beena nitāi guṇa-maṇi āmār nitāi guṇa-maṇi. O sin tunso pe Oluwa Nityananda ni orisun gbogbo amuye to dara. Āniyā premera vanyā bhāsāilo avanī. pelu awon iwa mimo toni, osi fun gbogbo agbaye ni ife Olorun. Pelu aanu re lasele mo nkan ti ife Olorun je. Premer vanyā loiyā nitāi āilā gauḍa-deśe. Nigbati Caitanya Mahāprabhu fi ile sile lati gba sannyas, o fi ile Olori Ise patapata ni Jagannatha Puri. Beena lehin igba to gba sannyas, nigbato fi ile re ati orile-ede re sile, Oluwa Nityananda Prabhu si tele losi Jagannatha Puri. lehin igba die, Olorun Caitanya si beere lowo re pe " Ti awa mejeji ba duro sibi, talofe se'waasu ni Bengal?" gauḍa-deśa ni oruko imi fun Bengal. Pelu ase Oluwa Caitanya Mahaprabhu, O mu ikun omi ife t'olorun wa, osi pin fun gbogbo Bengal, gauḍa-deśa. ninu ikun omi Olorun yi, gbogbo awon olufokansi si ri somi na. afi awon tio je olufokansi nikan ni o ri somi, sugbon omi na si gbe won lo. dīna hīna bāche. Sugbon Nityananda Prabhu, Kose iyasoto kankan laarin awon olufokansi ati awon alainigbagbo. Dīna hīna patita pāmara nāhi bāche. Olowo tabi talaka, alakowe tabi òmùgọ, gbogbo eyan lole gba ilana t'Oluwa Caitanya Mahaprabhu, wansi re somi ife t'Olorun. brahmār durlabha ni iru ife fun Olorun bayi. Brahma gan toje oluko patapata ninu agbaye yi, kole towo. sugbon pelu ore-ofe Oluwa Caitanya Mahaprabhu ati Nityananda Mahaprabhu, won le pin ife Olorun yi fun gbogbo agbaye laisi iyasoto kankan. Beena ābaddha karuṇā-sindhu, o dabi omi okun nla ton ti lati gbogbo egbe gbe. Omi okun ife Olorun je omi okun nla, sugbon ko'ponsedanu Beena Nityananda Prabhu si la ona ninu okun yi, osi mu omi okun yi wa si gbogbo enu ona gbogbo eyan. Ghare ghare bule prema-amiyāra bān. Wansi pin omi okun ife Olorun yi si gbogbo ile ni Bengal. Niotooro ni Bengal awon eyan si ife to kun fun Oluwa Caitanya Mahaprabhu ati Nityananda Prabhu. Locan bole, nisin onkowe tin soro fun ara re, pe enikeni tio ba ba l'afanni ore-ofe ti Oluwa Nityananda Prabhu ti funwa, Nkan to ro niwipe iru eyan bayi ti pokunso fun ara re.