YO/Prabhupada 0399 - The Purport to Sri Nama, Gay Gaura Madhur Sware



Purport to Sri Nama, Gay Gaura Madhur Sware -- Los Angeles, June 20, 1972

Gāy gauracand madhu sware. Orin ti Bhaktivinoda Ṭhākura ko leleyi. O sowipe Oluwa Caitanya, Gaura nitumo Oluwa Caitanya, Gaurasundara, ara pupa. Gāy gauracand madhur sware. Pelu ohun to lewa, o korin mahā-mantra, Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare, Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare.

Ninu orin yi to lewa gan, on korin lati so fun wa wipe agbodo tele lati korin mahā-mantra. Bhaktivinoda Ṭhākura advises, gṛhe thāko, vane thāko, sadā 'hari' bole' ḍāko. Itumo Gṛhe thāko niwipe bobatie jepe olori ile leyin je, tabi ewa ninu aginju bi alufaa, kosi iyato kankan, sugbon egbodo korin mahā-mantra, Hare Kṛṣṇa. Gṛhe vane thāko, sadā 'hari' bole' ḍāko. Ekorin mahā-mantra yi ni gbogbo igba. Sukhe duḥkhe bhulo nā'ko, " Ema gbagbe lati korin ninu idunnu tabi ibanuje." Vadane hari-nāma koro re. Ninu eto orin kiko yi, koseni tole daaduro, nitoripe ninu ounkooun ipo tinba wa, mole korin mahā-mantra, Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare, Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare.

Beena Bhaktivinoda Ṭhākura ti funwa ni imọran, wipe ema fojusi boya eni idunnu tabi ibanuje, sugbon ema korin mahā-mantra yi lo." Māyā-jāle baddha ho'ye, ācho miche kāja lo'ye. E ti bosinu idimu agbara aimokan aye yi. Māyā-jāle baddha ho'ye, gege bi apeja sen mu, orisirisi eja lat'omi okun. Beena lawa se wa nini idimu agbara ile aye yi, nitoripe awa o si ni ominira kankan, nitorina gbogbo nkan t'anse o wulo. Awon ise teyan ba n'se toba ni ominiran si wulo, sugbon teyan na o ba ni ominiran, ninu idinmu māya, ominiran wa o wulo. Nitorina, ounkoun tanse, kole wulo. Lai mo ipo wa, agbodo sise pel'agidi, pelu titẹ agbara ile aye yi, ilokulo asiko wa leleyi. Nitorina, Bhaktivinoda Ṭhākura sowipe, "Nisin eti ni imoye to da ninu ara eda eyan yi. E korin Hare Kṛṣṇa, Rādhā-Mādhava, gbogbo awon oruko wanyi. Kosi ipadanu kankan, sugbon ijere to po." Jīvana hoilo śeṣa, nā bhajile hṛṣīkeśa. Nisin gbogbo wa ma ku lai pe yi, Koseni tole sowipe, " Masi wa laye, Masi wa fun odun ogorun si." Rara, leyikeyi asiko a le ku. Nitorina, o funwa ni'moran jīvana hoilo śeṣa: Ile aye wa le paari leyikeyi asiko, awa o dele sise fun Hṛṣīkeśa, Kṛṣṇa. Bhaktivinodopadeśa. Nitorina Bhaktivinoda Ṭhākura ti funwa nimoran pe, ekbār nām-rase māto re: "Edakun emu s'okan, nām-rase, kiko orin oruko mimo yi. Eti ara yin bo omi okun yi. Ibeere akn soso mi niyen."