YO/Prabhupada 0413 - By Chanting, We can Come to the Highest Stage of Perfection



Lecture on SB 1.16.26-30 -- Hawaii, January 23, 1974

Ipo meta lowo ninu eto orin kiko. T'alakoko ni orin kiko pelu asise, ibere. Awon asise mewa lowa. Ati salaaye nipa won aimoye igba. T'awa ban korin pelu awon asise wanyi, ona t'alakoko niyen. Taba korin laisi awon asise wanyi. Konsepe orin na ti di mimo nitoripe kos'asise mo. Eyin tin gbiyanju lati yo awon asise ninu e kuro, sugbon koi ti di mimo. Sugbon teyin ba bere sini korin mimo, aseyori niyen. Nāma, nāmābhāsa, ati śuddha-nāma. Ipo wa ni... Ati salaaye tele. Ema ri ninu Caitanya-caritāmṛta, ninu ejo laarin Haridāsa Ṭhākura ati brāhmaṇa. lati orin kiko yi, a le wa sori ipo to gaju. Ni ibere awon asise to po lee wa, sugbon taba gbiyanju lati fi awon asise wanyi sile, lehin na ati de ipo nāmābhāsa. Itumo Nāmābhāsa niwipe koiti di mimo sugbon o ku die. Nāmābhāsa, ati śuddha-nāma. Teyan ba korin śuddha-nāma, Oluko mimo Olorun, lehin na o wa lori ipo kanna t'ife fun Krsna. Ipo to gaju leleyi. ninu ipo nāmābhāsa, laarin ipo mimo ati eyi toni asise, mukti niyen. Eyin m adi mukta eni toti bo lowo idimu aye yi. t'awa ban korin pelu awon asise wanyi, awa o le kuro ninu ile aye yi. Bhaktivinoda Ṭhākura sowipe, nāmākāra bahira haya nāma nāhi haya. Nkan tan ka, "Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa,"sugbon konse Hare Kṛṣṇa. Nāmākāra, nāma bahira haya, nāmākāra, nāma nāhi haya.

Beena agbodo korin yi pel'okan mimo. Sugbon awa ogbodo ni ibanuje. Nitorina agbodo korin pel'okan wa. nitoripe awa ooti de ipo mimo yi. Nitorina, pel'agidi... Gege bi omode ni iloe-iwe eko. Nibat'awa kere ni ile-iwe eko. Oluko mi sofun mi, " ko iwe mewa, iṣọwọkọwe itumo re niwipe tinba se iṣọwọkọwe fun oju iwe mewa, iṣọwọkọwe ti oni a si da. Beena t'awa o ba le korin fun igba merin din logun, nibo lejo pe awa fe korin Hare Krsna? Beena ema se nkan eke. nkan ti mofe so niwipe e se nkan to daju. nkan t'afe niyen. Teba fe nkan to daju ema se nkan eke. Se mo nkan toje eke? Ninu awon ile-ologun. Wan ni igo to kun fun omi nikan. Igo na si pupa. Sugbon igo pel'ogun gidi yato si... (l'egbe) Rara, isiin ko. Awon ogun gidi o ni iwulo fun awon igo wanyi. Teyan ba le korin laisi asise, kṛṣṇa-nāma kan , eyan na ti bo lowo idimu aye yi. L'eyokan soso. Eka kṛṣṇa nāme yata pāpa haya, pāpī haya tata pāpa kari baro nāhi.

beena śaucam,Imora ninu ati nita nitumo śaucam, śaucam. Inu wa gbodo wa mimo, pelu ironu mimo, laisi idoti kankan. awa ogbodo rowipe enikan je ota siwa. Ore ni gbogbo eyan je. "Okan mi o da.. nitorina mon rowipe enikan je ota simi." Orisirisi aami lowa. Beena śaucam, eyan gbodo wa mimo ninu okan re bi'ta na. Satyaṁ śaucaṁ dayā. dayā moti salaaye tele. Lati ni aanu fun awon ton woo sile nitumo Dayā Eni toti wolule, eni to wa ninu ibanuje. Beena niotoro, gbogbo olugbe aye isin woo lule, Kṛṣṇa sowipe,

yadā yadā hi dharmasya
glānir bhavati bhārata
abhyutthānam adharmasya
tadātmānaṁ sṛjāmy aham
(BG 4.7)
paritrāṇāya sādhūnāṁ
vināśāya ca duṣkṛtām
dharma-saṁsthāpanārthāya
sambhavāmi yuge yuge
(BG 4.8)

Lasiko t'awayi ni Kali, Kali-yuga, Esu ni gbogbo won. Gbogbo won esu. Niotooro nigbami Krsna ni lati wa fun ara re lati wa pa awon esu wanyi. Kalki avatara niyen. Jayadeva Gosvāmī ti salaaye eto na. kini yen? Keśava dhṛta-kalki-śarīra jaya jagadīśa hare. Kalau, dhūmaketum iva kim api karālam, mleccha-nivaha-nidhane kalayasi karavālam. Mleccha, awon mleccha, oro yi, yavana, Awon oro wa ninu ede veda, mleccha, yavana. Awon ton jeran nitumo Yavana. Yavana. Iyen o wipe awon oolugbe Europu ati America nikan lon je yavana, rara awon olugbe India na pelu. Rara. Enikeni to ban jeran, Yavana na loje. Eniton jeran nitumo Yavana. awon ton doti nitumo mleccha. Eni ti koba le tele awon ofin Veda lonpe ni mleccha. Gege bi awon musluman sen pe awon eyan ni kafir. Eni tio le tele esin Musluman lon pe ni kafir. Ipinnu awon elesein leleyi. awon Kristeni pe won ni "alainigbagbo." Eniti ko ba tele esin Kristeni, ni won pe ni alainigbagbo. Se beeko? Beena, enikeni tio ba le tele awon ofin Veda lon pe ni mleccha. Asiko ma wa toje pe koseni toma tele awon ofin Veda yi, Nitorina, mleccha. Beena mleccha-nivaha, nigbati gbogbo awon eyan ba di mleccha tan, tio si enikeni ton tele awon ofin Veda, mleccha-nivaha-nidhane, nigbana koni si iwaasu mo, pipa awon eyan nikan.