YO/Prabhupada 0424 - You Take Full Advantage of this Vedic Culture



Lecture on SB 1.1.1 -- New York, July 6, 1972

Ede Sanskrit se pataki gan, wan si jerisi ni gbogbo agbaye. nipataki ni orile-ede Germany, wan feran Sanskrit gan. Awon akeko lati Orile-ede Germany wa ton le soro ninu ede Sanskrit fun aimoye wakati. Wansi je akeko to daju lori ede Sanskrit. Ikan ninu awon egbe mi, o wa ni Sweden nisin, o sowipe "Nigbati akeko orile-ede India kan ba wa si ilu lati London" Ni asiko awon Oni-geesi, awon aralu India ma losi London, wan si gba eri-iwe nibe, Asi d'Okurin pataki. Ilana to wa ni gbayen niyen. beena toba tin pada sile asi se irin ajo losi awo ilu ni Europu. Beena ni Germany wansi se idanwo fun awon akeko omo-ilu India lati mo iwonba nkan to mo nipa asa India. Beena egbe mi yi oruko re tele ni Ernst Schulze, nisin Sadānanda Swami loruko re, beena lesekese tawa ba riwipe, awon akeko wanyi o mo nipa asa India lesekese lama paati segbe, "Iranu leleyi." beena, awon ton je omo-ilu India, nipataki ton wa ninu akojopo yi, pe teba fe fun orile-ede yin logo, lehin na egbodo ti awon iwe Veda yi siwaju. Kosi besele ni ilosiwaju ju awon ilu geesi pelu ogbon imo-ero. Kolese se. Wan ti ni ilosiwaju ju wa lo. Odun ogorun siwaju. Ounkoun ero teyin ba daale, wanti da iru sile odun ogorun seyin ni awon ilu geesi. Kosi besele ju wan lo. Beena teba fe kon fun orile-ede yin logo, e tisiwaju asa Veda yi pelu okan at'aya yi gege bi mon sen se. Beena bawo ni awon eyan sen gba? Koko oro na daju. Aimoye awon swami ton siwaju mi losi ilu yi, sugbon o soro fun won lati da nkan gidi sile. Wan gba owo die wansi pada. Otan. Egbe imoye Krsna wa yi yato, awa o ri be. Afe fun awon ilu geesi wanyi ni nkan. Ise wa niyen. Awa o wa lati toro, afe fun yin ni nkan, Ise apinfunni temi niyen. Won wa lati toro, " E funmi ni'resi, efunmi ni dahl(ewa), e funmi l'oka, e funmi l'owo," sugbon emi wa lati fun won ni asa India. Iyato to wa niyen. Beena eyin akeko Europu, America, e gbiyanju lati mu asa Veda yi ni pataki. Mosin sise gan pe kin to ku, mole fi awon iwe sile tele ka lehin iku mi. E lo dada. E lo dada. E ka awom sloka wanyi dada, e gbiynaju lati ni oye nipa awon oro wanyi laarin ara yin. Nityaṁ bhagavata-sevayā. Ise apinfunni wa niyen. Naṣṭa-prāyeṣv abhadreṣu nityaṁ bhagavata-sevayā (SB 1.2.18). Abhadra, oun to wa lokan wa si doti gan. A le ya awon nkan idot yi lokan wa si mimo pelu imoye Krsna. Kos'ona imi.

śṛṇvatāṁ sva-kathāḥ kṛṣṇa
puṇya-śravaṇa-kīrtanaḥ
hṛdy antaḥ stho hy abhadrāṇi
vidhunoti suhṛt satām
(SB 1.2.17)
naṣṭa-prāyeṣv abhadreṣu
nityaṁ bhāgavata-sevayā
bhagavaty uttama-śloke
bhaktir bhavati naiṣṭhikī
(SB 1.2.18)

Ilana to wa niyen. Śṛṇvatāṁ sva-kathāḥ kṛṣṇa, Kṛṣṇa wa ninu okan yin. Kṛṣṇa fe ranyin lowo latinu ati lati'ta. Lati'ta oti funwa ni irisi re ninu ile-ajosin. Ele gbiyanju lati sise Fun. O ti ran iranse re, oluko mimo ,lati salaaye fun yin nipa Krsna, ati wipe osi le ran yin lowo latinu gege bi Paramatma. Krsna si dara. Krsna ti wa nitori iya ti gbogbo wa je ninu ile aye yi, O sin pe wa, sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja (BG 18.66). Beena bhāgavata-sevayā, nityaṁ bhāgavata-sevayā (SB 1.2.18). itoju okan wa, ceto-darpaṇa-mārjanam (CC Antya 20.12). Ilana to wa niyen. Nkankana laje pelu Olorun, Krsna. Asi je mimo. Ati ni idoti ninu aye wa nitoripe ati ni nkan se pelu idoti aye yi. Beena agodo yasi mimo, ilana lati lese niwipe agbodo gbo nipa Krsna. Otan.