YO/Prabhupada 0429 - Krishna is the Name of God. Krishna Means the All-attractive, All-good



Lecture on BG 2.11 -- Edinburgh, July 16, 1972

Beena ipo wa niwipe gbogbo awujo to wa nisin, tin sise pelu ipo toje wipe ara wa laje. Otooro niyen je. Nitorina, Kṛṣṇa kīrtana leleyi, egbe Hare Krsna leleyi, oni anfanni tie. Ema rowipe egbe Hare Krsna yi je nkan afori ro. Nkan latoke wa loje. mahā-mantra l'oruko re. Mahā-mantra. Mio mo boya awon eyan ton sise pel'ejo wa ni ilu yi. Ni India, awon eyan ton sise pel'ejo po gan, Won si so awon oro, lehin na eyan t'ejo geje le pade s'aaye. Enikeni toba wa ni India mo nipa awon nkan wanyi. Nipataki ni ilu Punjab, awon eyan ton sise pel'ejo po gan, ton mo lati ko awon mantra wanyi. Beena teyan ba le je ki eyan toti ku.... sugbon amowipe eyan t'ejo ba geje kio ti ku. Koni si pelu ara re mo. Sugbon koi ti ku. Sugbon ton ba ti ko mantra yi tan, eyan na ma pada s'ara re. Nitorina, ni India, tejo ba ge'yan je Won o kin fina s'ara re tabi kon sowipe o ti ku. Won ma fi sori oko omi . toba ya eni na le pada s'okan ara re. Beena, nitori aimokan tani awa na sun. Gbogbo wa lan sun. Nitorina lati le dide soke, agbodo lo maha-mantra yi. Lati jisoke. Ceto-darpaṇa-mārjanam (CC Antya 20.12). Gege bi awon omo-okurin at'obirin olugbe Europu yi ton wa pelu mi... Moni bi akeko Egbeedogun Gbogbo won lon korin Hare Krsna yi. Kon sepe won kon korin lasan. O daju fun won. Teba ba won soro won soro dada lori eto imoye. Pel'ogbon, beyan to l'ogbon. Beena bawo lonse se? Odun merin seyin, won o mo eni ti Krsna je. Boya wanti ri oruko Krsna ninu iwe-isotunmo, pe "orisa awon Hindu" loje. Sugbon otooro ko leleyi je. Krsna l'oruko Olorun. Eda ti gbogbo wa ni ifarasi nitumo Krsna, eni to daju. Itumo pe gbogbo wa ni ifarasi niwipe oun lo daju; bibeko bawo lose je eni ti gbogbo wa ni ifarasi? Eni tio da, kosi basele ni ifarasi. Nitorina, Krsna, itmuo re ni eni ta ni ifarasi. O ni gbogbo amuye to dara, nitorin lose je eni ta ni ifarasi. Isotunmo to da leleyi, itumo Olorun. T'Olorun bani oruko to daju, Krsna na l'oruko ba je. Oro-ede Sanskrit leleyi je, sugbon Olorun nitumo Krsna. Ninu awon sastra won sowipe, īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ (Bs. 5.1). Oludari nitumo Īśvaraḥ, ati paramah, oludari. Īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ (Bs. 5.1). Ilana to wa ninu iwe Veda leleyi. Beena egbe imoye Krsna wa yi o kin se egbe tonse isasoto. Egbe to daju pelu awon ilana sayensi. Egbiynaju lati ni oye nipa re. Ilana na rorun gan. Ilana to wa niwipe egbodo korin Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare/ Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare. Awa o kin se alálùpàyídà , sugbon asin bere lowo awon akeko wa, " E korin mimo yi," ki okan yin ba le yasi mimo lati gbogbo awon idoti to wa ninu e. Ilana wa leleyi. Caitanya Mahāprabhu ti salaye, Oti funwa ni ilana, ceto-darpaṇa-mārjanam (CC Antya 20.12).

Isoro tani ninu aye yi bere lati idamu tani. Idamu talakoko tani niwipe " Ara mi nimi." Niotoro gbogbo wa lawa lori ipo aye yi, ipo pe ara wa laje. beena nitoripe orisun eto na ko daju, nitorina gbogbo nkan tan daa sile, gbogbo oye tani na o daju. Nitoripe ibere imoye tani ko daju. Beena nialakoko agbodo gbiyanju lati yo èrò wanyi ninu okan wa pe ara wa laje." Nkan tonpe ni ceto-darpaṇa-mārjanam (CC Antya 20.12), fifo okan wa. Mon ronu wipe, " Ara mi nimi," Sugbon bee ko loje. Beena agbodo yo idamu yi kuro, osi rorun lati se, tabi korin Hare Krsna maha-mantra yi. Nkan tose se leleyi. Beena ibeere wa si gbogbo yin niwipe, teba mu itosona yi lati korin Hare Krsna maha-mantra. kosi ipadanu kankan, sugbon eyin ma jeere gan. Awa o bere owow kankan. Bi awon elomi ton ba fun yin ni mantra won ma bere owo. Sugbon awa sin pin l'oofe. Gbogbo yin le gba. Awon omode na le se. Awon omode po gan ninu egbe wa. Won korin wansi jo na. Kosidi fun ikeeko kankan. Kosi iye lati san. E korin... Kilode teyin o sefe se idanwo si kee baale ri ibajade to wa? Ibeere wa leleyi. Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare/ Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare. Eyan le bere, " Kilode tefe kin korin oruko Krsna toje Hindu?" Beena awa o sowipe Krsna tabi Olorun.. Olorun ni oruko to po. Awa na ti jerisi. Olorun o l'opin. Nitorina o gbodo l'oruko to po. sugbon Krsna yi loje pipe ju, nitoripe itumo re je eni ti gbogbo wa ni ifarasi. Eyin le sowipe, " Alagbara l'Olorun je." O da. Sugbon bawo lose je alagbara? Nkan imi iyen. Beena teba rowipe " Krsna je oruko orisa Hindu, kilode tonfe kin daruko na?" Beena Caitanya Mahāprabhu sowipe, "Rara." teyin ba ni oruko toyato si eleyi ele korin oruko na. Ibeere wa niwipe ke korin oruko Olorun. Teyin ba ni Oruko Olorun kankan, e korin oruko na. Ema yasi mimo. Ise apinfunni wa leleyi