YO/Prabhupada 0432 - As Long As You Are Reading, The Sun Is Unable To Take Your Life



Lecture on SB 2.3.17 -- Los Angeles, June 12, 1972

Pāvakaḥ. Dahati pāvakaḥ (BG 2.23). Awon oni sayensi nisin wan sowipe ko s'aye kankan lori isogbe orun. Otooro koni yen. Kini orun je? Isogbe ina, otan. Sugbon awon emi legbe ninu ina to ba ni ara to ye. Gege bi awa nibi, lori ile, ani ara fun ile yi. O le rewa gan sugbon ile lo je. Pelu eto iseda aye yi lase wa sibi.. Karandhara fi awon igi eke kan fi han mi. Beena wanti se awon igi eke wanyi to jo igi gidi, sugbon gidi ko loje. Beena, ara wayi dabi igi eke. Ko wulo kankan. Beena tyaktvā deham. Beena ti Krsna ba sowipe lehin igba teba f'arale.... Sugbon ara yi dabi ara eke. Gege bi aso Ele fi sile. Iyen o wipe eyan ti ku. Wanti salaaye na ninu Bhagavad-gītā: vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya (BG 2.22). Basen fi aso toti gbo fun tuntun, beena, itumo iku niwipe agbodo fi ara eke yi sile fun imi. Iku niyen.

Lehin na e gbodo sise pel'ara tuntun tegba. teba ni ara to da, ele sise dada. teba ni ara aja, ema huwa bi aja. gege bi ara na se je. Beena tyaktvā deham. Kṛṣṇa sowipe " Enikeni toba mo nipa mi l'ooto..." Beena bawo lesele mo? E gbo nipa re, lehin na o le ye yin. Lehin na o ma ye yin. ati fetisile o kin se ise to le. Sugbon egbodo gbo nipa oro na lati awon eyan ton daju. Satāṁ prasaṅgān mama vīrya-saṁvidaḥ. Teba gbo lateyan lasan, kole sise. Egbodo gbo latenu sadhu, latenu awon olufokansi. Gege bi Śukadeva Gosvāmī se salaaye fun Mahārāja Parīkṣit. tabi ke ka awon iwe na fun ara yi, ke fun ara yin nigbala. teba ka iwe Krsna, tabi Bhagavad-gita tabi Ikeeko ti Olorun Caitanya, Teban kawe, orun o le fiku pa yin. Orun o le fiku pa yin. Beena teba kawe nigbogbo'gba bawo ni orun se fe pa yin? Itumo re niwipe eti wa tayeraye. Awon eya fe gbe lasi ku. Koseni tofe ku. Gbogbo eyan mope " Mo ma ku." Sugbon ti alebu kankan ba wa, ina, lesekese lema kuro ninu yara yi. Kilode? Miofe ku. Miofe ku, Botilejepe mo mope masi ku. sugbon, kilode ti mosen kuro? "Oh, E je ki'na jo. Mole ku leni tab'ola. E je kin ku." Rara. Mio fe ku. Nitorina lasen sa kuro. Ogbon ori leleyi. Gbogbo wa lafe gb e tayeraye. Otooro leleyi. Beena teba fe gbe tayeraye, egbodo gba imoye Krsna yi Beena egbe imoye Krsna yi dara gan, osi se pataki. Gbogbo eyan lofe wa laaye. Beena niotooro, teba fe wa laaye, emu imoye Krsna yi. Ese iwe yi ti jerisi. Āyur harati vai puṁsām udyann astaṁ ca yann asau. Orun n'jade lojojumo laaro. Bi orun sen jade die die lon mu ile aye yin lo. Otan, Ise re niyen. Sugbon teyin ba fe ni idari lori iku... Orun yi lagbara gan. O le lati baa ja. Sugbon e le baja. Bawo? Teba n'ka Krsna-katha, awon oro Krsna. Uttama-śloka-vārtayā. Vārtayā. Uttama-śloka, Kṛṣṇa. Ilana to rorun leleyi. Ema lo asiko yin nilokulo, ten so iranu. Nitorina Rupa Gosvami sowipe, atyāhāraḥ prayāsaś ca prajalpo niyamāgrahaḥ. Prajalpaḥ.

atyāhāraḥ prayāsaś ca
prajalpo niyamāgrahaḥ
jana-saṅgaś ca laulyaṁ ca
ṣaḍbhir bhaktir vinaśyati
(NOI 2)

Ilea aye mimo wa tani le tan, idamu le wole sinu e... Awon ton wa ninu ile aye ise s'Olorun yi, imoye Krsna, won sorire gan. Sugbon nkan mefa le ba orire yi je. E se diedie. Kini yen? Atyāhāra. Atyāhāra, itumo re niwipe ka ma jeun ju boseye ka jeun, tabi ka ma kowo ju bose ye. Āhāra. Āhāra, ankojo itumo re niyen. Oye ka pa owo, sugbon ema pa owo ju boseye ke ni. Iyen awa o ye ka se. Nitoripe tin ba l'owo, lesekese ni maya ma.. "Na owo funmi?" Beeni. Nitorina e ma pa owo ju bo.. ju bese ni iwulo fun. tabi, āhāra jijeun. Ema jeun ju boseye. Niotooro, agbodo de ipo to je pe awa o jeun mo, awa o sun mo, awon ni imo ako at'abo mo, awa o gbeja ara wa mo. Sugbon kolese se nitoripe awa ni ara eda yi. Sugon niwonba diedie.