YO/Prabhupada 0452 - Krishna Comes Upon this Earth Once in Brahma's Day



Lecture on SB 7.9.5 -- Mayapur, February 25, 1977

Pradyumna: Isotunmo - " Nigbati Oluwa Nrsimha-deva ri omode Prahlada Maharaja to doobale niwaju ese re, Inu re dunsin olufokansi re yi. Lehin igba togbe Prahlada dide, Olorun si fi owo re sori omode na nitoripe owo re le yo iberu kuro ninu okan awon olufokansi."

Prabhupāda:

sva-pāda-mūle patitaṁ tam arbhakaṁ
vilokya devaḥ kṛpayā pariplutaḥ
utthāpya tac-chīrṣṇy adadhāt karāmbujaṁ
kālāhi-vitrasta-dhiyāṁ kṛtābhayam
(SB 7.9.5)

Beena lati d'eni t'Oluwa feran ju, nkan to rorun ni. Kole rara. Nibi ati ri apeere Prahlada Maharaja, omode omo odun marun... (isinmi) toje olufokansi, osi mo Oloroun, osi doobale fun. Amuye toni leleyi. Enikeni le se bayi. Enikeni le wa si ile-ajosin wa kosi doobale. Kilo le nibe? Beena eyan gbodo mowipe " Eledumare lowa nibi, Kṛṣṇa tabi Nṛsiṁha-deva tabi eyikeyi ninu awon irisi re to po."

Ninu awon sastra wan sowipe, advaitam acyutam anādim ananta-rūpam (Bs. 5.33). Kṛṣṇa ni ananta-rūpam. Nitorina gbogbo awon rupa je ifesi ti'risi talakoko ti Krsna. rupa t'alakoko ni ti Krsna. Kṛṣṇas tu bhagavān svayam (SB 1.3.28). rupa to po gan: Rāma, Nṛsiṁha, Varāha, Balarāma, Paraśurāma, Mīna, Tortoise, Nṛsiṁha-deva. Rāmādi-mūrtiṣu kalā-niyamena tiṣṭhan (Bs. 5.39). O si wa pelu orisirisi irisi, konsepe owa pel'ara Krsna nikan. Ninu gbogbo irisi lowa, rāmādi-mūrtiṣu. Apeere kanna, tawa ti funyin aimoye igba: gege bi orun, asiko orun, wakati merinlelogun, Beena ninu awon wakati merinlelogun tabi irisi merinlelogun, eyikeyi ninu won lowa. Konsepe nitoripe ago mejo lon lu nisin, beena ago meje ti tan. Rara. Nibomi ninu aye yi ago meje lon lu. tabi ago mesan. Ago mesan na si wa. Ago mejila na si wa. Awa si ni ago kan ti Gurukṛpa Mahārāja funwa. (Erin) O muwa lati orile-ede Japan. Osi da gan. Lesekese ele ri nkan t'ago n'so ni'bikibi -lesekese. Beena gbogbo won wa. NItorina lonsen pe Krsna lila ni nitya-lila, konsepe lila kon sele, lila keji ti tan, rara. Gbogbo nkan sele lese kanna. Nitorina lasen lo oro yi rāmādi-mūrtiṣu. Rāmādi-mūrtiṣu kalā-niyamena tiṣ... Niyamena. Lasiko toye. Gege bi orun, beena. Teletele kos'ago, sugbon pelu awon ojiji awon eyan le mo asiko to wa. Nisin gan ele mo, Nigbat'awa kere awa na lo ojiji lati mo asiko ago. "Nisin nkan t'ago n'so- gege boseje. Beena kalā-niyamena tiṣṭhan, kon se nkan niwonba diedie - nisin ojiji fi ago kan han leni, lola ago kan nibomi. Rara. Ago kanna loma je nibikanna. Kalā-niyamena tiṣṭhan. Beena, Kṛṣṇa's līlā, niyamena tiṣṭhan - gege bose je. Aimoye isogbe to wa. Nibi won bi Krsna. Nisin Vasudeva ti mu Krsna losi Vrndavana. Nkankana - lesekese lon bi saye, Krsna losi Vrndavana - ninu isogbe imi won ti bi Krsn, wan tun ti bi Krsna. Beena ni lila re sen lo. Kosi ipaari kankan, kode sejo asiko. Beeni. Gege bi Krsna sen wa sinu aye wa yi nigbakan soso ninu ajo kan Brahma. Beena, nigbati aimoye odun ba koja Krsna atun farahan, tiko ban se fun ara re,awon iranse re, amsena. Caitanya Mahāprabhu na ma farahan nigbato baya. Oluwa Ramacandra na ma farahan. Beena rāmādi mūrtiṣu kalā-niyamena tiṣṭhan (Bs. 5.39). Beena lila yi, Nṛsiṁha-deva, atun sele lasiko toye. Beena sva-pāda-mūle patitaṁ tam arbhakam. Omode kekere. T'omode kekere bi Prahlada Maharaja, le gba ore-ofe to po gan bayi lati Nrsimha-deva, ninju irisi re tole deruba awon eyan to je pe Laksmi gan o le summo... Aśruta. Adṛṣṭa aśruta pūrva. Kosi iru irisi Olorun yi teletele. Laksmi gan o mo. Sugbon eru o ba Prahlada Maharaja. O mowipe, " Oorun mi leleyi" gege bi omo kiniun o beru kiniun. Lesekese loma fo sori kiniun nitoripe o mo, " Baba mi leleyi. Iya mi leleyi." Beena, eru o ba Prahlāda Mahārāja, botilejepe Brahma ati awon iyoku gan eru sn ba won lati summo Olorun. Omo kekere lasan loje osi wa lati doobale. Tam arbhakaṁ vilokya. Beena, beena eyan l'Olorun je. Lesekese loye wipe, "Oh, omode kekere leleyi. Baba re ti fun ni idamu to po gan, nisin oti wa doobale siMi." Vilokya devaḥ kṛpayā pariplutaḥ. okan re si kun ore-ofe si. Beena, gbogbo nkan wanyi wa nibe.