YO/Prabhupada 0461 - I Can Do Without Guru - That Is Nonsense



Lecture on SB 7.9.7 -- Mayapur, February 27, 1977

gege bi ilu wa, oni ikewi kan tonpe ni Rabidranath Tagore. O si gba iwe-eri to po gan lati ile-iwe giga Oxford. Ko losi ile-iwe kankan, sugbon won si fun ni àkọlé dokita, "Dr. Rabindranath Tagore." sugbon teyin ba rowipe " Emi na magba àkọlé dokita lai losi ile-iwe giga," iwa didinri niyen. Awon eyan to yato leleyi. Beena ema farawe won. E gb'ona ti gbogbo awon eyan gba, sadhana-siddhi. Awon ofin towa ninu sastra, eyin gbodo tele. Nitorina ni sastra to po gan sewa, ati guru lati ranwalowo. teyin ba tie je nitya-siddha tabi krpa-siddha, eyin o gbodo huwakuwa. Alebu ninu iru iwa bayi po. Ema danwo. Agbodo tele Nitya.. gege bi Caitanya Mahaprabhu. Krsna ni Caitanya Mahāprabhu fun ara re, Oluwa, sugbon osi gba guru. tani guru re? Oun ni guru gbogbo eda, sugbon osi gba Isvara Puri bi guru. Krsna fun ara re, osi gba guru, Sandipani Muni, lati ko wa pe laini guru kosi besele ni ilosiwaju. Ādau gurvāśrayam. Ise t'alakoko ni lati gba guru. Tad-vijñānārthaṁ sa gurum evābhigacchet (MU 1.2.12). Ema rowipe " Moti ni ilosiwaju tojepe, mio ni lati gba guru konkon. Mole wa lai ni guru." Iranu niyen. Kolese se. " Gbodo." Tad vijñānārtham. Tad-vijñānārtham sayensi mimo leleyi. "Agodo gba." Gurum evābhigacchet samit-paniḥ śrotriyaṁ brahma-niṣṭham. Tasmād-guruṁ prapadyeta jijñāsuḥ śreya uttamam (SB 11.3.21). Teyin bafe ko nipa sayensi mimo yi, e gbodo gba guru. Tasmād guruṁ prapadyeta jijñāsuḥ śreya uttamam. Gege bi Caitanya Mahāprabhu se so, āmāra ājñāya guru hañā tāra' ei deśa (CC Madhya 7.128). Eyan o le danikan so ara r ni Guru. Rara. Kosi iru apeere kan soso bayi ninu gbogbo iwe mimo Veda. Nisin, awon asiwere wanyi , gbogbo won lont di guru lai gba olori kankan. guru ko niyen. egbodo ni idari lati se. Evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rā... (BG 4.2). Lesekese ti parampara yi ba sonu, sa kālena yoga naṣṭo parantapa, lesekese loma tan. Agbara mimoo re ti tan niyen. Ele wo aso guru, ke ma soro nla nla, sugbon kole sise kankan.

Sayensi to wa niyen. Beena Prahlada Maharaja ni guru wa. Eyan lasan ko loje. ema rowipe " Omo-odun marun loje, ko l'ogbon kankan." Rara. nitya-siddha guru to daju loje, ati agbodo gbadura fun ore-ofe re. Vaisnava thakura niyen. Vaiṣṇava ṭhākur tomāra kukkura boliyā jānaha more. Ona to resile leleyi, " O Vaisnava thakura..." gbogbo awon Vaisnava ni thakura. Eyan lasan ko niwon. Ṭhākura... Nitorina lasen pewon: Bhaktivinoda Ṭhākura, Bhaktisiddhānta Sarasvatī Ṭhākura. Beena Vaiṣṇava, Prahlāda Ṭhākura. Beena agbodo gbadura nigbogbo'gba, vaiṣṇava ṭhākura, tomāra kukkura boliya jānaha more. Orin Bhaktivinoda Ṭhākura kan wa: "Vaisnava thakura mi, emu mi aja yin," Vaisnava thakura. Bi aja, sen gboran si oga re lenu agbodo ko lati awon aja wanyi lati nigbagbo ninu oga wa. Ilana to wa niyen. Ninu gbogbo nkan agbodo keeko. Gbogbo eyan. Nitorina maha-bhagavata, won gba gbogbo eyan bi guru, lati ko nkan lowo won. niotoro ale ko lati nigboran s'ogo wa lati awon aja toba tie jepe aye wa ma ni alebu nitorina. Apeere to po gan wa, awon aja tonti ku nitori oga won. Beena.. oye ka d'aja fun awon Vaisnava. Chāḍiyā vaiṣṇava-sevā, nistāra pāyeche kebā.