YO/Prabhupada 0484 - Prema is Mature Condition of Bhava



Lecture -- Seattle, October 18, 1968

Prabhupāda: se ibeere kankan wa?

Jaya-gopāla: Kini'yato laarin bhava ati prema?

Prabhupāda: lehin igba ti bhava ba dagba loma di Prema. Gege bi mangoro kekere ati eyi toti pon. lati mangoro kere ni eyi toti pon ti wa. sugbon itowo eyi to ponn daju eyi tio pon lo. Beena, katole nife Oluwa, orisirisi ipo lowa. gege bi mangoro yi sen koja orisirisi ipo, lehin na nijokan oun na ma di pupa, toba ti pon dada, itowo re asi dun. mangoro kanna loje. konsepe mangoro imi loje, sugbon oti dagba. Bi apeere yi, ni'beere idodo ni mangoro yi je, die die a si d'eso. Lehin na diedie loma dagba. Lehina asi le gan, lehin na diedie a bere sini pupa, toba ya asi pon. Bi ilana gbogbo nkan se ri niyen. Ninu ile aye yi na, ilana mefa lowa, ipaari gbogbo nkan ni'po to keyin. Pelu apeere mangoro yi na, ale gbabee nitori on salaaye nipa idagbasoke, sugbon awon apeere aye yi o daju. gege bi mangoro na toba pon teyan ba je o da gan. Bibeko toba pon ju, o ma baje, asi wo lule, otan niyen. Ile aye yi niyen. sugbon awon nkan mimo o ri bayi. Kole tan. teyin ba de ipo ife to gaju, lehin na ipo to gaju yi ma wa tayeraye, ile aye yin ma ni aseyori. Premā pum-artho mahān. orisirisi eto pipe lowa laye yi. Elomi sin rowipe, " ipo aye yi leleyi." Awon eyan aye yi sin rowipe, " Tin ba le gbadun ara mi dada, pipe aye wa niyen." Ironu to yato imi niyen. toba de ti su won, won ma bere sini wa nkan imi to daju. Beena, ti awon eyan yi o ba ni eni tole salaaye fun won, won ma pada si nkankanna - imo ako ati abo, ati oti mimu, otan. Iwa kuwa nikan. Otan. Nitoripe koseni to salaaaye fun won. Ton sewaadi, ton wa nkan to daju, nitoripe kosi onitosona, asi pada si igbadun aiye ara tabi oti mimu - igbagbe. Onisowo, toba ni ipaadanu, isoro to po loje fun. Asi bere sini moti latri gbagbe. sugbon ona eke leleyi. Ona oabyo toye ko gba ko leleyi. Fun igba melo leyin fe gbagbe? Orun - fun igba melo lefe sun? tein ba tun ji, esi wa ninu ipo kankan. Ona to wa kan niyen. Sugbon teyin ba wa sori ipo ife Oluwa, beena eyin ma gbagbe awon iranu wanyi. Paraṁ dṛṣṭvā nivartate (BG 2.59). teyin ban je ounje to da, eyin ma fi awon ounje iranu sile tio ni itowo dada.

Bi imoye Krsna se ri niyen. Asi mu yin losi ipo to jepe eyin na ma gbagbe awon iranu wanyi. Aye to daju leleyi. Brahma-bhūtaḥ prasannātmā (BG 18.54). Lesekese teyin ba de ipo yi, aami re niwipe inu yin ma dun gan. Eyin ni ifura gbogbo ibikibi. Apeere to po gan wa. Beena teyin ba gba ile aye yi pelu Krsna, eyin na ma ni itowo odo metalokan yi ninu ile aye yi. Igba Krsna tab'Olorun nitumo ile aye yi. Bi ile aye yi se ri niyen. Bibeko, teyin ba ni imoye Krsna to daju, eyin ma riwipe ninu odo metalokan, ninu ile aye yi gan. Imoye nikan loje. Apeere kankan. Gege bi oba ati kokoro tojoko sori aga kanna, sugbon kokoro na mo wipe " mowa ge oba yi je lati mu eje. Otan. Oba na mo wipe " Mo godo se ise ijoba. Emi ni olori orile-ede yi." won joko sibikanna, sugbon imoye ori won yato. Beena, teyin ba paaro imoye okan yin, ibikibi teyin ba wa, Vaikuntha loje, kosejo kankan.