YO/Prabhupada 0559 - They Foolishly Think - 'I am the monarch of all I survey'



Lecture on BG 2.62-72 -- Los Angeles, December 19, 1968

Prabhupāda: Ifanimora ti māyā leleyi. Asi pada wa sinu aye yi. Ese iwe kan wa,

ye 'nye 'ravindākṣa vimukta-māninas
tvayy asta-bhāvād aviśuddha-buddhayaḥ
āruhya kṛcchreṇa paraṁ padaṁ tataḥ
patanty adho 'nādṛta-yuṣmad-aṅghrayaḥ
(SB 10.2.32)

Adura Prahlāda Mahārāja leleyi. Osowipe, " Oluwa mi, pel'oju idodo, Aravindākṣa," ye anye. " Awon eyan lasan, won ni igbera nipa aye yi gan, awon nirvāṇa wanyi tabi awon alainigbagbo ninu Oluwa." Vimukta-māninaḥ. Vimukta-māninaḥ. - won rope won koja idimu māyā. Ironu eke. Vimukta-māninaḥ. Fun apeere teyin ba bere sini rowipe " Emi ni olori ilu Los Angeles yi," se ironu eke ko niyen? Beena, teyan ba rowipe " Nisin moti de ipo nirvana tabi moti wolu sinu Eledumare." Ele ronu bayi. māyā yi lagbara gan. Eyin le ni igberaga nitori iwa eni pataki yi. Vimukta-māninaḥ. Bhāgavata sowipe, tvayy asta-bhāvād aviśuddha-buddhayaḥ (SB 10.2.32). " Sugbon nitoripe awa eyan wanyi o sewaadi fun ese yin bi ododo, nitorina imoye won doti, won rowipe " Nkan bayi bayi nimi." Aviśuddha-buddhayaḥ. "Ogbon won, ati imoye toni si doti." Nitorina āruhya kṛcchreṇa. " Won se awon awe gbigba pelu inira to po gan." Gege bi awon elesin Buddha, awon tio sin esin na, nkan imi niyen. sugbon Buddha fun ara re gan tele awon ofin. O fi gbogbo nkan sile lati le fokan le sasaro. Talon sebe nisin? Koseni kankan. Ipo talakoko ti Śaṅkarācārya niwipe " laalakoko egba sannyasa keto bere sini soro wipe eyin fedi Narayana." Talo n'gba sannyasa? won kan ronu lasan. Looto, ogbon ori won doti, imoye won doti. Nitorina pelu gbogbo igbiyanju wanyi, āruhya kṛcchreṇa param ni ibajade to wa nibe, botilejepe won ma gunke titide milli 25,000, kosi bon sele ri idaabo kankan, nibo ni osupa wa, nibo ni ( kose gbo). Won si ma pada wa si ilu Moscow yi, otan tabi Ilu New York, otan. Awon apeere to wa leleyi. Tonba ti losoke won bere sini ya aworan. "Oh, isogbe yi ri bayi, osi kere gan. Mon se iyika lataaro daale ni wakati kan leemeta lojojumo." Odaa bee,. Edakun e pada wa sibi. (Erin). Otan. Māyā si lagbara gan, a sofun yin wipe, "Beeni, oda gan. Eyin ti ni ilosiwaju gan ninu imoye sayensi yin, sugon edakun e pada. e pada sibi. Bibeeko ama fiyin sinu omi okun Atlantic." Otan. Won sini igberaga, " Oh ati ni ilosiwaju. Odun mewa si isin, ele ra awon iwe iwole lati losori osupa." Se mo, ni Russia won ta ile wonsi polowo pe " omi okun Moscow wa nibi. Ati rin ipe akiyesi sori omi okun.. " Awon isokiri ton so niyen. Sugbon won o le sinu isogbe to sunmo wa ju, ka ma wa soro nipa sanma mimo. Teyin bafe losi sanma mimo ati Vaikunthaloka, lehin na egba ilana to rorun yi, Hare Krsna. Otan.

Alejo: Monife nipa eto Oluwa.

Prabhupāda: (lai fokan si alejo ton soro) ibukun t'Oluwa Caitanya leleyi. Namo mahā-vadānyāya. Nitorina Rūpa Gosvāmī sowipe, " Eyin leda alaanu to gaju Nitoripe eyin ni ibukun too gaju. "Kṛṣṇa-prema-pradāya te (CC Madhya 19.53). " Eyin sin funwa nife Krsna, tole mumi losi odo metalokan Krsna." Ibukun to gaju fun awujo eda leleyi. Sugbon awon didinrin won yi kole ye won. Kini mole se? Daivī hy eṣā guṇamayī (BG 7.14). māyā lagbara gan. Taba sowipe " iwe kekere leleyi, Irin ajo to rorun si awon isogbe imi," Awon eyan wanyi o ni gba. Wonsi pada lo s'eto lati losi awon isogbe orun wanyi pelu ero sputinik, kodese se. Eyin ole losibi kankan. Bi ile aye wa seri niyen. itumo idimu yi niwipe egbodo duro sibi. Egbodo wa nibi. Talo fe ke losi awon isogbe imi? Lati ni visa ayeraye fun orile-ede yin, mosi se irin ajo to po pelu oko-afefe, eyin si fe losori isogbe osupa? Se kosi visa? Won ma jeke wole bee? Se nkan to rorun bayi loje? Sugbon ronu pel'ogbon ode pe " Emi ni oludari gbogbo nkan timon ri." Otan. Isogbe wa logba, gbogbo awon isogbe wanyi wa labe ti tawa. Wonma fun iye ara wa nitelorun. Iwa didinri leleyi. O daa be. E korin Hare Krsna.