YO/Prabhupada 0576 - The Process should be How To Make Zero all these Propensities



Lecture on BG 2.19 -- London, August 25, 1973

Beena loke vyavāya āmiṣa mada-sevā nityas tu jantuḥ. Iwa okan to wa niyen. Itumo aye yi niwipe gbogbo eda laye yi ni awon iwa okan re. sugbon won gbodo fi ipaari si. Pravṛttiḥ eṣaṁ bhūtānām. Iwa adayeba towa niyen. Sugbon teyin ba le fi opin si, aseyori teni niyen. Nkan tonpe ni tapasya niyen. Itumo Tapasya niwipe moni awon iwa kan, sugbon ko da. Idi tojepe kofi da niwipe taba tesiwaju pelu iru iwa bayi, awa gbodo gba ara eda imi. Awon ofin aye yi niyen. Ese iwe kan wa, pramattah. Kilon pe...? Moti gbagbe nisin. Pe gbogbo awon eyan n'sa tele igbadun iye ara won. Na sādhu manye yata ātmano 'yam asann api kleśada āsa dehaḥ (SB 5.5.4). Taba si ni iwa yi lati gbadun iye ara wa, agbodo gba ara eda imi. Ibimo ati iku niyen> Nitorina ilana to wa niwipe agbodo giyanju lati yi gbogbo awon iwa yi si opin. Pipe aye wa niyen. Ema je ko posi. Nūnaṁ pramattaḥ kurute vikarma yad indriya-prītaya āpṛṇoti (SB 5.5.4). Nūnam, looto, pramattaḥ, awon were wanyi. Were ni won, awon eyan ton sa tele awon iwa bayi, vyavāya āmiṣa mada-sevā, imo ako ati abo ati eran jije. Awon were nigbogbo won. Pramattah. Nūnaṁ pramattaḥ kurute vikarma (SB 5.5.4). Awon ise t'awa o gbodo se nitumo Vikarma. Fun awon nkan meta wanyi, āmiṣa-mada-sevayā, fun imo ako ati abo, fun eran jije, fun oti mimu Awon eyan n'sise. Awon sin sise tio daju. Bawo lonsele gbo'wo, bi won sele ri owo, oja dudu, oja funfun, bayi bayi, fun awon nkan meta wanyi: āmiṣa-mada-sevā. [...]

Nitorina nūnaṁ pramattaḥ kurute vikarma yad indriya-prītaya āpṛṇoti (SB 5.5.4). Itosona ti Ṛṣabhadeva si awon omo re niyen. " Eyin omo mi, ema je kon tanyinje. Awon asiwere wanyi, wanti ya were tele awon nkan wanyi, eran jije, oti mimu ati imo ako ati abo." Na sādhu manye, "Koda rara" Na sādhu manye. " Mio gba, mio sowipe o da. Ko da rara." Na sādhu manye, "kilode ti ko se da? Awan'gbadun aye yi." Beeni, eyin gbadun nisin, sugbon yata ātmano 'yam asann api kleśada āsa dehaḥ (SB 5.5.4). Fun igba teyin ban se awon nkan wanyi egbodo gba ara imi, teyin ba tun gba ara eda imi, egbodo ni ibimo, e gbodo ku, aisan gbodo wa, ojo arugbo na gbodo wa. Eyin ma jiya. E ma jiya. Sugbon ipo yin talakkoko ni na jāyate Koyeke ni ibimo ninu aye yi, sugbon eyin ti fi ara yin sinu idimuibimo aye yi. Looto koye keyin ni ibimo, aye tayeraye. Bi Krsna sewa tayeraye, beena ni gbogbo wa se wa tayeray nitoripe nkankana laje pelu Krsna - amuye kanna.