YO/Prabhupada 0649 - Mind is the Driver. The Body is the Chariot or Car



Lecture on BG 6.2-5 -- Los Angeles, February 14, 1969

Olufokansi: Ese iwe kaarun. " Eyan gbodo gbe ara re soke pel'okan re. Koye ko fi ara re woole. Ore ni okan jesi awon eda aye yi, ati ota re na (BG 6.5)."

Alaye: Oro atma ni ede Sanskrti, emi, ara, okan ati emi nitumo re je, sugbon lorii ipo orisirisi. Ninu ilana yoga, okan ati awon eda lon se pataki ju. Bosejepe okan wa ni ipo to wa laarin ise adase yoga yi, okan w anitumo atma. Lati ni idari lori okan wa nidi fun ilana yoga yi ati lati yoo kuro lori awon oun igbadun iye ara wa. Wanti salaaye nibi pe awa gbodo ko okan wan leeko kobale yowa kuro ninu igbese aye yi."

Prabhupada: ninu ilana astanga-yoga, ilana ipo mejo ti yoga yi, dhyana, dharana - lati fi ni idari lori okan wa lon wa fun. Afi teyin ba ni idari lori okan wa..... Ni beere wan sowipe awon okurin gbodo gbiyanju lati gbe ara won soke lat'ori okan won. Oniwako l'okan wa je. Ara eda ni oko na. Beena teyin ba sofun oniwako yi, " Dakun mumi losi ile-ajosin imoye Krsna." Oniwako na ma muyin wa sib. Teyin ba sofun oniwako na, " dakun mumi losi ile oti." Oniwako na ma muyin losibe. Ise oniwako yi ni lati muyin losibikibi tebafe. Beena bi oniwako yi ni okan yi se ri. Teyin bale ni idari - sugbon oniwako yi le gba iwe-eri, pe ibikibi toun ba fe loma muyin lo. Lehin na oti ton fun yin niyen. Oniwako ti d'ota yin niyen. Sugobn tii oniwajo yin ma sise teba se sofun, lehin na ore loje siyin. Beena lati ni idari lori okan wa nitumo ilana yoga yi pe asi sise bi ore siyin, koni sise bi ota. Looto oro okan mi n'sise, nitoripe ominiran die nimo ni, nitoripe nkankana nimo je pelu Eledumara toni gbogbo ominira, nitorina ominiran die nimoni. Okan wa lon p'ase lori eto ominiran yi. T'okan wa ba sowipe, " O da, eje kin lo si ile-ajosin imoye Krsna<" ti okan wa basi sowipe, "Oh iranu niyen, Krsna, e je ka losi ile ijo." Beena okan wa lon fun wa l'ase. Beena egbe imoye Krsna wa yi wa lati fi okan wa lori eto Krsna, otan. Kosi bosefe se ogbodo huwa bi ore siyin. Se ri bayi? Kole se bose fe. Lesekese ti Krsna ma joko sori okan wa, gege bi lesekese t'orun ban ran orunb wa lori sanmo, kole s'okunkun mo. Kole sele. Kosi b'okunkun sefe wa niwaju orun. Beena bi orun ni Krsna se ri. E fi Krsna sinu okan yin. maya,, okunkun yi o le wa ba yin. ilana yoga to gaju leleyi. Ilana yoga toje pipe. T'okan yin ba lagbara gan tio jeki awon nkan iranu wole sinu re, bawo leyin sefe wolule? Okan yin lagbara, oniwako lagbara. Kosi bosefe mu yin losibhi teyin o ba fe afi teba gba. Beena gbogbo ilana yoga yi wa lati je ki okan wa lagbara. Konsepe ko fi Eledumare sile. Ilana yoga to gaju niyen. Sa vai manaḥ kṛṣṇa-padāravindayoḥ (SB 9.4.18). Eyan gbodo fi okan si, gege bi Ambarisa Maharaja to gbokanle Krsna. osi ja pelu yogi pataki kan, astanga-yogi, Durvasa Muni. Mahaja Ambarisa, oba loje, onile loje, onisowo loje. Itumo onile niwipe oni eto oro aje tonse. Dollar, cents. Oba, oba gidi loje. Beena yogi pataki ni Durvasa Muni je. Osio ni itara si oba na. Pe " Bawo lose je? yogi pataki nimi , mole se irin ajo lori ofurufu, oba lasan l'okurin yi, kole fi nkankan han ninu eto yoga, sugbon awon eyan sin wa terba fun. Kilode? Mofe yanju eto re." Beena osi lo toja oba na, itan to gun gan, Lojoowaju ma salaaye re dada, beena lehin gbogbo e wan ni isegun lori e. Narayana si sofun ko pada lo ba oba Maharaja Ambarisa ko si teriba fun. Awon apeere lati awon iwe mimo leleyi, pe o kon wo Krsna ninu okan re, osi ni'segun lori yogi alagbara yi. Durvasa Muni, yogi oataki loje, tojepe laarin odun kan o se irin ajo lori gbogbo agbaye yi titi de oforufu ninu odo metalokan - o lop ba Olorun fun arfa re ni odo metalokan, Vaikuntha, ori Olorun soju. Beena osi pada wa teriba fun Maharaja Ambarisa. Sugbon Maharaja Ambarisa, oba lasan ko loje, o kon ronu nipa Krsna, otan. Awon nkan wanyi a ma ri won. Nitorina lati ni idari lori okan wa ni yoga to gaju. teyin bale fi ese meji Krsna toda bi ododo ninu okan yi o rorun gan lati ni idari lori okan na, otan. Teyin ba rinu nipa Krsna, eyin ma ni isegun. Eti di ogi to gaju. Nitoripe leyin gbogbo e, yoga indriya saṁyama ni ilana yoga yi je. Lati ni dari lori iye ara nitumo Yoga. Okan wa si gaju iye ara wa. Beena teyin ba ni idari lori okan yin, eyin ti ni idari lori iye ara yin niyen. Ahon yin fe je ijekuje, sugbon t'okan yin ba lagbara, Okan yin masowipe,. Rara. Eyin o le je nkankan tio ban se Krsna-prasada." Leyin na awon na ti ni idari. Beena okan wa lo ni idari lori iye ara. Indriyāṇi parāṇy āhur indriyebhyaḥ paraṁ manaḥ (BG 3.42). Iye ara wa nitumo ara mi, beena, iye ara wa, ise wa nitumo igbadun ara mi, otan. sugbon lori iye ara wa ni okan wa. lori okan wa l'ogbon wa. lori ogbon wa ni emi wa. Teyan ba wa lori ipo mimo yi, lori ipo emi, leyin na ogbon re ma yasi mimo, opkan re ma yasi mimo, iye ara re ma yasi mimo, leyin na oun na ma yasi mimo. Ilana imoye Krsna niyen. Nitoripe, emi wa lon sise, sugbon oti fun okan iranu yi lagbara. On sun. sugbon toba ji soke, t'oga ba ji soke, oniranse o le huwa kuwa. Beena teyin ba jisoke ninu imoye Krsna, ogbon yin, okan yin, tabi oye ara yin o le se isekuse. won gbodo huwa to da. Yiya si mimo niyen. Iwenu niyen je.

Hṛṣīkeṇa hṛṣīkeśa-sevanaṁ bhaktir ucyate (CC Madhya 19.170). Iwa mimi nitumo Bhakti. Bawo lese huwa? Egbodo huwa pelu iye ara yin. Nitorina egbodo ya iye ara yin si mimo. Sasaro, teyin ba fi ipaari si iranu iyen nitumo pe eyin ti fi ipaari si ise, sugbon ise ninu imoye Krsna wa ni pipe. Gege bi eyin gbodo fi ipaario si gbogbo iranu t'okan yin se sugbon ipo pipe koniyen. EYin gbodo huwa dada. Lehin na ipo to gaju niyen. Bibeko teyin o ba ko iye ara yin lati huwa dada, asi pada si awon iranu ton se tele. Beena agbodo fun ni'se fun Krsna. lehin na kole tuin subu. Imoye Krsna niyen.