YO/Prabhupada 0652 - Padma Purana is Meant for the Persons Who Are in the Modes of Goodness



Lecture on BG 6.6-12 -- Los Angeles, February 15, 1969

Olufokansi: Alaaye: " Ofo l'ogbon iwe laini imo nipa Eledumare. Wanti salaye bayi ninu Padma Purana..."

Prabhupada: Beeni, Padma Purana. Purana mejidinlogun lowa. Awon Okurin ti pejo si amuye meta: ipo iwa rere, ipo iwa ife kufe, ati ipo aimokan. Lati yo awon eda wanyi kuro ninu awon ipo orisirisi aye yi, awon ilana wa ninu Purana. Awon Purana mefa wa fun awon eyan ton ni iwa rere. Purana mefa tun wa fun awon eyan pelu iwa ife kufe. ati Purana mefa fun awon eyan pelu iwa aimokan, awon Purana yi wa fun won. Padma Purana yi wa fun awon eyan ton wa ninu ipo rere. Ninu awon ebo Veda, eyin ma ri awon ebo orisirisi. Nitori awon eyan orisirisi lonse wa. gege bi eyin se mope ninu iwe Veda, oni awon ebo ton pa ewúrẹ niwaju orisa Kali. Sugbon ninu Purana yi, Mārkaṇḍeya Purāṇa, wa fun aawon eyan ton wa ninu ipo aimokan.

Gege bi eyan to nife eran. Nisin, teyin ba dede sofun pe eran jije o da... tabi eni to feran oti mimu. Teyin ba dede sofun pe, oti o da, kole gba. Nitorina ninu awon Purana eyin ma ri, " O da teyin bafe jeran, e s'adura si orisa Kali ke pa ewure niwaju orisa na. Lehin na ele je. Eyin o ole jeran ton ta ni ile-iperan. Boseye ke je niyen. " Ihamo towa niyen. Nitoripe teyin bafe s'ebo na niwaju orisa Kali, o l'ojo,ati awon oun elo teyin gbodo lo fun. puja yi, tabi ebo yi l'ojo osupa dudu nikan lema se. Beena leekan soso l'osupa dudu yi ma wa ninu ose kan. mantra tema ko niwipe; eyin ma fun ewure ni awon itosona wanyi " Iwo tin fi aye re sile niwaju orisa Kali. Beena lesekese loye ko gba ara eda eyan." Looto a sele. Nitoripe lati wa sori ipo ara da eyan, awon eda gbodo koja ipo orisirisi to po. Sugbon ti ewure na ba gba tabi ton f'agidi pa niwaju orisa Kali, lesekese loma ni ara eda. mantra na sowipe, "Eyin na le fiku pa okurin ton fi e s'ebo." Māṁsa. Itumo Māṁsa niwipe iwo na le jeran ara re, ni aye to kan. beena bayi, okurin ton s'ebo na, oma gba s'ogbon ori re, " Kilode ti mo sen jeran? Lehin na matun son gbese na pelu eran ara mi. Kilode ti mosen se iru ise bayi?" Seri bayi. Lati daduro ni ilana yi wa fun.

Beena orisirisi Purana lowa, Purana mejidinlogun. Nitoripe awon iwe Veda wa fun gbogbo awon okurin aye yi. Konsepe awon ton jeran tabi awon oloti, ka tiwan segbe. Rara. Wanti gba gbogbo awon eyan - sugbion teyin ba losodo Oniwosan. A fun yin logun fun iru aisan teyin ni. Konsepe a fun yin l'ogun kan soso fun aisan kanna. Rara. Iwosan to daju niyen. Die die, die die. Sugbon ninu sāttvika-purāṇas, won wa fun awon eyan tonfe s'adura s'Eledumare. Kos'ona die die nibe. Sugbon wansi ma salaye fun awon eyan pe kon wa sori ipo yi die die. Beena ikan ninu awon Purana ninu ipo rere ni Padma Purana yi je Kilo so? Tesiwaju.