YO/Prabhupada 0659 - Simply Hear Sincerely and Submissively, Then You Will Understand Krishna



Lecture on BG 6.13-15 -- Los Angeles, February 16, 1969

Prabhupāda: Kilode?

Olufokansi: Prabhupada, e sowipe Krsna o l'apa at'ese, ko l'oju, ko l'ara tio le yewa. Bawo lasele ni oye nipa irisi Krsna towa ninu awon iworan ati awon murti?

Prabhupada: Beeni, moti salaaye. Eyin gbodo sise fun, lehin na o ma farahan siyin. Eyin o le mo nipa Krsna pelu ilana yin. Eyin gbodo sise fun Krsna, Krsna asi farahan siyin. Wanti slaaye ninu Bhagavad-gita, eyin ma ri ninu apa Kewa.

teṣām evānukampārtham
aham ajñāna-jaṁ tamaḥ
nāśayāmy ātma-bhāva-stho
jñāna-dīpena bhāsvatā
(BG 10.11)

"Fun awon ton sise funmi, lati fun won ni ore-pfe die," teṣām evānukampārtham, aham ajñāna-jaṁ tamaḥ nāśayāmi. " Moti fi ipaari si gbogbo okunkun pelu ina imoye." Beena Krsna wa ninu yin. Teyin ban sewaadi nipa Krsna pelu ilana ise ifarasi, gege bi wonse salaaye ninu Bhagavad-gita, eyin ba ri ninu apa okanla, bhaktyā mām abhijānāti (BG 18.55). "Eyan le ni oye nipa Mi lati ilana ise ifarasi Mi." Bhaktya. Kini bhakti? śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ (SB 7.5.23) ni Bhakti. Teyin ba gbo tesi korin nipa Visnu. Ibeere bhakti niyen.

Beena teyin ba gbo dada tesi teriba, lehin na eyin ma ni oye nipa Krsna. Krsna ma farahan siyin. Śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ smaraṇaṁ pāda-sevanam arcanaṁ vandanaṁ dāsyam, awon orisirisi nkan mesan lowa. Beena vandanam, adura,m bhakti no niyen je. Śravaṇam, e gbo nipa re. Gege bi awa sen gbo nipa Krsna lati Bhagavad-gita. E korin nipa ogo re, Hare Krsna. Ibere towa niyen. Śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ (SB 7.5.23). Itumo Visnu niwipe...Gbogbo nkan ni Visnu. Lori Visnu lan sasaro. Visnu ni bhakti na. Laisi Visnu. Krsna ni irisi talakoko ti Visnu. Kṛṣṇas tu bhagavān svayam (SB 1.3.28). Irisi t'alakoko t'Eledumare. Beena teyin ba tele ilana yi, eyin ma leni oye laisi iiyemeji kankan.