YO/Prabhupada 0850 - Ti o ba ti ni Owo diẹ, ki o si tẹ awọn iwe jade



750620d - Lecture Arrival - Los Angeles

A ko ni ohun titun miran. (Ẹrin) A ko fi se lọpọ. Eleyi jẹ ilana wa. A kan tẹle imọran awọn aṣáájú, ko ju yẹn lọ. Ironu wa ko le rara nitori a ko ni lati se nkankan lọpọ. A kan nse atunwi awọn ọrọ ati imọran ti awọn asaaju pasẹ fun ni. Ọlọrun kọ Brahmā, Brahmā kọ Nārada, Nārada kọ Vyāsadeva, Vyāsadeva kọ Madhvācārya, ati ni ọna yi, lẹhinna Mādhavendra Puri, Īśvara Puri, Śrī Caitanya Mahāprabhu, lẹhinna awọn Goswami mẹfa, lẹhinna awọn Srinivasa Acharya, Kavirāja Goswami, Narottama dāsa Ṭhākura, Viśvanātha Cakravartī, Jagannātha dāsa Bābājī, Bhaktivinoda Ṭhākura, Gaurakiśora dāsa Bābājī, Bhaktisiddhānta Sarasvatī, lẹhinna awa na si nse ohun kanna. Ko si iyatọ nibẹ. Iyẹn jẹ ilana kan pato ti ẹgbẹ isọkan Ọlọrun. Ẹ nkọrin lojoojumọ, guru-mukha-padma-vākya, cittete koriyā aikya, ār nā koriho mane āśā. O jẹ ohun ti o rọrun gan. A ti ngbà imọ imọlẹ nipa asa atọwọdọwọ-guru sọkalẹ wa. Nitorina a kan ni lati gba ẹkọ lọdọ guru, ati ti ẹ ba si fi ṣiṣẹ tọkàntọkàn, iyẹn jẹ aseyori. Ti o ni wulo. Emi ko ni agbeyô ara ẹni kankan, sugbọn mo kan gbiyanju lati se itẹlọrun guru mi, ko ju yẹn lọ Guru Maharaja mi wi fun mi pe "Ti o ba ni owo diẹ , ki o si tẹ sita awọn iwe jade." Bẹ ni ipade ikọkọ kan se wa nibẹ, ti wọn sọrọ, diẹ ninu awọn arakunrin ninu ẹmi ti wọn jẹ pataki naa wa nibẹ. Ni Rādhā-kuṇḍa ni o ti sẹlẹ. Bẹẹ naa ni Guru Maharaja se mba mi sọrọ pe "Lati igba ti a ti ni Bagbazar tẹmpili didan yi, ọpọlọpọ awọn ede aiyede niwọn ti wa nibẹ olukaluku ti wa nlero tani o ma gba yara yi tabi yara ọhun, yara. Nitorina mo fẹ, ta tẹmpili yi ati awọn marbili didan rẹ ki nsi tẹ awọn iwe diẹ jade. " Bẹẹni. Mo si gba eyi lati ẹnu rẹ, wipe o nifẹ awọn iwe gidigidi. O si sọ fun mi tikalararẹ pe "Ti o ba ni owo diẹ, tẹ awọn iwe jade." Nitorina ni mo nse fenumọ sori ọrọ yi: "Nibo ni iwe wa? Nibo ni iwe wa? Nibo ni iwe wa?" Nitorinaa ẹ jọwọ ẹ ran mi lọwọ. Eyi ni mo beere fun. Ẹ tẹ sita iye bi ye awọn iwe ni ọpọlọpọ awọn ede ki ẹ si pin wọn jakejado gbogbo agbaye. Nigbana ni ẹgbẹ isọkan Olọrun yio funrarẹ ni lọsiwaju. Bayi awọn alakọwe, ẹlẹkọ ọjọgbọn, nwọn ti wa mọrírì ronu wa, nipa kika awọn iwe, nipa gbigba esi iwulo. Dr. Stillson Juda, ti kọ ìwé kan, boya ẹ mọ, Krishna... Hare Krishna ati asa-we-asa, iwe to dara gan nipa ronu wa, o si nfun niyi. O si ti gba wipe "Swamiji, o ti ṣe ohun iyanu nitori pe o ti tan awọn oògùn-mowonlara hippies si awon olufokansi ti Ọlọrun, ti wọn si wa mura silẹ fun iṣẹ araiye."