YO/Prabhupada 1066 - Awon eyan tio logbon won rowipe Otito to Gaju yi pe ko kin seyan



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Awọn eniyan alaimoye gbero pe Otitọ-to gaju lọ jẹ ohun ti ko lara Ọlọrun Ọba ni ẹni aringbungbun ti ẹda, aringbungbun ti ẹda ati ti igbadun, ni Ọlọrun Ọba, awọn ẹda alãye si jẹ alajumọse. Nipa ifọwọsowọpọ ni awọn na gbadun. Ibasepọ wọn tun dabi ti oluwa ati iranṣẹ rẹ. Ti oluwa na ba ni itẹlọrun daradara, nigbana awọn ọmọ-ọdọ na yio ni itẹlọrun. Ofin to wa niyen. Bakanna, o yẹ ki Ọlọrun Ọba ni itẹlọrun, biotilẹjẹpe ifarahan lati di ẹlẹda ati itẹsi lati gbadun awọn ohun elo ti aye... Awọn na wa ninu ẹda alãye nitori itẹsi wọnyi wa ninu Ọlọrun Ọba. O ti da, O ti da awọn agbaaye.

Nitorina, awa o ri, ninu Bhagavad-gītā yi pe odindi pipe jẹ agbajọ ti Ọlọrun Ọba, awọn ẹda alãye ti wọn ndari, awọn ifihan agbaye, akoko ainipẹkun ati akitiyan, gbogbo awọn wọnyi ni wọn ti ni alaye ninu ọrọ yi. Gbogbo awọn wọnyi lapapọ ni a npe ni Ọlọrun Olotitọ to ga julọ. Odindi Pipe tabi Otitọ Atobiju ti o pe ni wọn jẹ pipe ti Ẹni Isaju Eledumare Sri Krishna. Bi mose salaaye tele pe, gbogbo awọn ifihan ni wọn wa nitori orisirisi okunagbara rẹ. Oun si ni odindi to pe.

Iwe mimọ Bhagavad-gītā se alaye pe Brahman ti ko lara na je ọmọ ẹhin Ẹnì ti O tobijulọ ni asepe . Brahmaṇo 'haṁ pratiṣṭhā (BG 14.27). Brahman ti ko lara... Alaye Brahman ninu Brahma-sutra wa ni kedere pupọ gẹgẹ bi itansan. Gẹgẹ bi itansan imọlẹ ti oorun riran., aye oorun, bakanna, Brahman aimọlara ni didan itansan imọlẹ ti Brahman to gaju tabi Ẹnì Isaju Eledumare. Nitorina imọ alabọ ti odindi patapata ni Brahman Aimọlara jẹ, beẹ na ni ero nipa ti Paramātmā. Awọn nkan wọnyi ti ni alaaye. Puruṣottama-yoga. Nigbati a ba ma ka ori iwe ti o sọrọ nipa Purusottama-yoga , a le ri wipe Eledumare, Purusottama, gaju Brahman ti ko lara, ati àbọ iriri ti Paramatma. Ẹnì Isaju Eledumare ni a npe ni

sac-cid-ānanda-vigraha. (BS 5.1) Brahma-samhita bẹrẹ ni ọna yi: īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ sac-cid-ānanda-vigrahaḥ/ anādir ādir govindaḥ sarva-kāraṇa-kāraṇam (BS 5.1)." Govinda, Kṛṣṇa, ni orisun gbogbo nkan. Oun l'Olorun gbogbo wa." "Govinda, Ọlọrun, ni idi gbogbo awọn okunfa. Oun ni ifa akọkọ, Be ni Ẹni Isaju Eledumare ni sac-cid-ānanda-vigrahaḥ. "Iriri Brahman Aimọlara ni riri ti sat (ayeraye) ẹya-ara rẹ Iriri Paramātmā ni riri sat-cit, ayeraye ati imọ. Ṣugbọn iriri ti Ẹni Isaju Eledumare, Krishna, ni riri ti gbogbo awọn ẹya ara imọlẹ bi sat, cit ati ananda, ninu vigraha to pe ju. Irisi nitumo Vigraha. Irisi nitumo Vigraha Avyaktaṁ vyaktim āpannaṁ manyante mām abuddhayaḥ (BG 7.24). Awọn eniyan alaimoye gbero pe Otitọ-to gaju lọ jẹ ohun ti ko lara, Sugbọn Oun jẹ eniyan imọlẹ, eyi si ti ni ifọwọlelori ninu gbogbo awọn iwe Vediki. Nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām (Kaṭha Upaniṣad 2.2.13). Bi gbogbo wa ti jẹ ẹda alãye kọọkan ti a si ni iwa olukuluku wa, bakanna, Otitọ ti nse Atobijulọ na, ni igbẹhin ọrọ, jẹ eniyan, Sugbon iriri Ẹni Ọlọrun Eledumare jẹ riri ti gbogbo awọn ẹya ara imọlẹ gan ni irisi Rẹ pipe. bi sat, cit ati ananda, to wa ni pipe ninu vigraha. Irisi ni itumo Vigraha. Nitorina Odindi pipe ki ise alailara. Ti O ba si jẹ alailara, tabi ti O ba rẹhin ju ohunkohun miiran, nigbana ko le jẹ pipe lodindi. Ohun ti o pe lodindi gbọdọ ni ohun gbogbo ninu iriri wa ati re kọja iriri wa, Bibẹkọ ko le jẹ pipe. Odindi pipe, Ẹni Ọlọrun Eledumare, ni okunagbara pupọ Parāsya śaktir vividhaiva śrūyate (CC Madhya 13.65, isotunmo). Bi Ọlọrun ti se nlo awọn orisirisi agbara Rẹ tun ni alaye ninu Bhagavad-gita Ile-aye iyalẹnu yi, tabi inu aye asan ti a ba ra wa na jẹ pipe funara rẹ nitori pūrṇam idam (Śrī Īśopaniṣad, Ayajọ). Awọn eroja mẹrin-le-logun ti agbaye, ni ibamu si imoye Sāṅkhya, awọn eroja mẹrin-le-logun ti agbaye yi jẹ ifihan fun igba diẹ, o si wa ni ti-to lẹsẹsẹ patapata lati se awọn iranlọwọ pipe ti wọn ni pataki fun itọju ati ilọ-deede ti agbaye yi. Ko si ohun ti o wa ni afikun, tabi ohunkohun ti o nilo fun ilọ-deede agbaye. Akoko ifarahan aye yi ti wa ni ikọsile nipa agbara ti Odindi Atobiju, ati nigbati akoko naa ba pari, awọn ifihan aye yio wa si opin nipasẹ akanṣe pipe ti àsepe.