YO/Prabhupada 1072 - Ka fi ile aye yi sile ka pada s'aye tio le paari ninu ijoba towa tayeraye



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Ka fi ile aye yi sile ka pada s'aye ainipẹkun ni ijọba ọrun. Oluwa si fi ara Rẹ han nipa ore-ọfẹ Rẹ, bi o ti wa, gẹgẹ bi Śyāmasundara-rūpa. Osenilaànu, pe awọn alaimoye se ni yẹpẹrẹ Avajānanti māṁ mūḍhā (BG 9.11). Nitori ti o ti wa ninu awọ ara eniyan ti o si nsere pẹlu wa bi ọkan ninu wa, Ṣugbọn a ko le titori eyi daro Oluwa bi ọkan ninu wa. O jẹ nipa agbara Rẹ ti o fi ara rẹ gidi han niwaju wa ati ti o si fi idaraya rẹ han, eyi ti wọn jọra mọ awọn idaraya ninu ibugbe Rẹ.. Awọn aye ainiye ni wọn leefo ninu itansan imọlẹ, eyini brahma-jyotir. gege b'ase ni aimoye awon isogbe ti wọn leefo ninu itansan imọlẹ oorun, bee na, ninu brahma-jyotir, ti o jade lati inu ibugbe to ga julọ, Kṛṣṇaloka, Goloka, ānanda-cinmaya-rasa-pratibhāvitābhis (BS 5.37), mimọ ni gbogbo awọn isọgbe wọnyi. ānanda-maya, awọn aye cin-maya, ti wọn kii se ti aye ilẹ Bee na Oluwa sọ wipe, na tad

na tad bhāsayate sūryo
na śaśāṅko na pāvakaḥ
yad gatvā na nivartante
tad dhāma paramaṁ mama
(BG 15.6)

Ẹni ti o ba le sunmọ ọrun ẹmí yi ko ni lati sọkale mọ si ode aye. Ninu ode aye, ki a ma wa sọ nipa ti oṣupa... Isogbe osupa, lo summo wa ju, sugbon taba tie de isogbe to gaju yi, ani ti a ba tilẹ sunmọ aye to ga julọ (Brahmaloka), a ma ri awọn inira inu aye kanna, eyun inira ibimọ, iku, aisan ati arugbo. Ko si aye kan ni gbogbo agbaye ti o ni iyọkuro ninu awọn ipinlẹ mẹrin ti igbesi aye wọnyi. Nitorina Oluwa si sọ ninu Bhagavad-gita wipe, ābrahma-bhuvanāl lokāḥ punar āvartino 'rjuna (BG 8.16). Awọn ẹda alààyè ti nrin irin ajo lati aye kan si miran, sugbọn ki se pe a le lọ si aye eyikeyi ti a fẹ nipa eto ohun elo. Ti a ba fẹ lati lọ si aye ọrun miiran, ilana wa bi a se nlọ sibẹ. Yānti deva-vratā devān pitṟn yānti pitṛ-vratāḥ (BG 9.25). Ti a ba fẹ lati lọ si aye ọrun miiran, ka so wipe, oṣupa, , awa o gbodo gbiyanju lati lọ nipa eto ohun elo. Bhagavad-gita ti salaaye wipe, yānti deva-vratā devān. Oṣupa, oorun ati awọn aye ọrun ti wọn ga ni a npe ni Svargaloka. Svargaloka. Bhūloka, Bhuvarloka, Svargaloka. Awon orisi ipo aye ti o yatọ ni wọn wa nbe. Beena Devaloka, bonse mo won niyen. Bhagavad Gita kọ wa bi a se le se irin ajo lọ si awọn ọna aye ti o ga (Devaloka) pẹlu afise ti o rọrun pupọ. Yānti deva-vratā devān. Yānti deva-vratā devān. Deva-vratā, Ẹ kan lati sin awọn orisa akunlẹbọ pataki ti aye na, lehin na a le losi isogbe tafe. A le lọ si ori oṣupa, oorun tabi eyikeyi ninu awọn ọna aye ti o ga. Sibẹsibẹ Bhagavad Gita ko da ni nimọran lati lọ si eyikeyi ninu awọn isalu aye yi, nitori ani ti a ba lọ si Brahmaloka, aye ti o ga julọ, ti awon onisayensi ti siro pe lati de bee nipasẹ awọn ohun elo ẹrọ kan nipa boya ririn fun ọkẹ ọdun tani o si le gbe le aye fun iye igba na lati lo si aye ọrun ti o ga julọ? Sugbon ti eyan ba fi aye rẹ sin orisa-akunlẹbọ ti aye ọrun kan pato, o le lọ si bẹ, Bhagavad-gītā se ni imọran: yānti deva-vratā devān pitṟn yānti pitṛ-vratāḥ (BG 9.25). Bakanna, Pitrloka na wa. Ṣugbọn ẹni ti o ba fẹ lati sunmọ aye ọrun ti o ga julọ, Aye ọrun ti o ga julọ ni Kṛṣṇaloka. Ninu isalu ọrun yi, aimoye ọrun alakeji ni wọn wa nibe, awọn ọrun sanatana, awọn ọrun ayeraye, ti wọn ko ni iparun. Sugbon ninu gbogbo awọn aye ti ẹmí ọrun wọnyi ẹyọkan wa aye atetekọse ti a npe ni Goloka Vrndavana. Gbogbo awọn ẹkọ yi ni Bhagavad Gita ti fun ni, a si tun gba nipasẹ awọn imọran rẹ ẹkọ bi a se le fi ile aye silẹ lati bẹrẹ aye alayọ gidi gan ninu ijọba ọrun.