YO/Prabhupada 1076 - lasiko iku ale wa nibi, tabi ka pada si odo metalokan



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Lasiko iku a le duro nibi, tabi ka pada si ijọba Ọlọrun. bhava orisirisi lo wa. Nisin, iseda aye yi na je ọkan ninu awọn bhavas ni, bi ati salaaye tele, wipe isẹda aye jẹ asehan ọkan ninu awọn okunagbara ti Ọlọrun Ọba. Ninu Viṣṇu Purāṇa apapọ okunagbara Ọlọrun Ọba ti wa ni ijuwe:

viṣṇu-śaktiḥ parā proktā
kṣetra-jñākhyā tathā par
avidyā-karma-saṁjñānyā
tṛtīyā śaktir iṣyate
(CC Madhya 6.154)

Gbogbo awon agbara, Parāsya śaktir vividhaiva śrūyate (CC Madhya 13.65, purport). Ọlọrun Ọba ni oniruuru ati ainiye okunagbara eyi ti o kọja ero wa. sibẹsibẹ, awọn ọjọgbọn akẹkọ nla tabi awọn ẹmi ti wọn ti ni igbala ninu ẹsẹ ti se iwadi si ti se akopọ gbogbo awọn okunagbara wọnyi si ọna mẹta, Ikini ni pe... gbogbo awọn okunagbara na ni wọn jẹ Viṣṇu-śakti. gbogbo awọn okunagbara, wọn jẹ awọn orisi agbara ti Oluwa Viṣṇu. Nisin, para ni agbara yi, to gaju. Ati kṣetra-jñākhyā tathā parā, ati awon eda, kṣetra-jña, awọn ẹda alaaye na tun jẹ agbara to ga wanti jeerisi ninu Bhagavad-gita na. A ti salaaye tẹlẹ. Awon agabra iyoku, agbara ile aye yi, ṛtīyā karma-saṁjñānyā (CC Madhya 6.154). Awọn okunagbara miiran, wọn jẹ ti ipo aimọkan. Bẹ eyinni jẹ okunagbara aye. Bẹ okunagbara aye na - ( ko daju). Ni akoko ti iku ba de a le duro boya ninu agbara ti o rẹlẹ ti aye yi, tabi ile aye yi, tabi ki a ni igbe lọ sinu agbara ti awọn aye ọrun. Eyinni jẹ bosewa. Bẹ ni Bhagavad Gita sọ pé: yaṁ yaṁ vāpi smaran bhāvaṁ tyajaty ante kalevaram taṁ tam evaiti kaunteya sadā tad-bhāva-bhāvitaḥ

yaṁ yaṁ vāpi smaran bhāvaṁ
tyajaty ante kalevaram
taṁ tam evaiti kaunteya
sadā tad-bhāva-bhāvitaḥ
(BG 8.6) .

Bayi a nsaba lero si, boya agbara aye tabi agbara ẹmi. Bayi, bawo ni a se le dari ero na? Ironu ile aye bawo ni a se le gbe ero wa lati inu agbara aye si agbara ẹmí? Bẹ na fun eronu nipa agbara mimo awọn iwe ilana Vediki wa nibẹ. Gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn iwe ni wọn wa fun ero ti agbara aye iwe iroyin, akọọlẹ, iwe, bẹ bẹ lọ. O kun fun iwe. Bẹ ni wọn fi ọkan wa kun fun ero ninu awọn iwe wọnyi. Bakanna, ti a ba fẹ gbe ero wa sinu agbara ẹmí, nigbana a gbọdọ rọpo wọn pẹlu awọn iwe Vediki. Nitorina, awọn ọjọgbọn nla ti kọ ọpọlọpọ awọn iwe ilana Vediki, Awọn Purāṇas ko wa lati inu igbiro; wọn jẹ awọn itan igbasilẹ. Ninu Caitanya-caritamrta ese iwe kan salaaye bayi. Anādi-bahirmukha jīva kṛṣṇa bhuli' gela ataeva kṛṣṇa veda-purāṇa kailā (CC Madhya 20.117). Awọn eda alãye ti wọn ni igbagbe tabi ti wọn wa ninu idé yi, wọn ti gbagbe ibasepọ wọn pẹlu Ọlọrun Ọba, ti ero awọn akitiyan aye si ti gba wọn l’ọkan. Ani ki wọn kan fi le gbe agbara iro wọn si sàkaani ọrun, Krsna-dvaipāyana Vyāsa ti fi iye ojulowo iwe ilana Vediki silẹ. Ni akọkọ o pín awọn Vedas si mẹrin. Lẹhinna o si salaye wọn ninu awọn Purāṇas. Ati fun awọn eniyan ti wọn ko l’oye pupọ bi awọn strī, śūdra, vaiśya o ti kọ Mahābhārata, O si funni ni Bhagavad Gita ninu Mahābhārata. Lẹhin na o tun fun wa ni akopọ gbogbo ilana Vediki ni soki ninu Vedanta sutra. ati fun itọnisọna l’ọjọ iwaju lori Vedanta sutra, o se àsọyé tinu-tinu ti a npe ni Śrīmad-Bhāgavatam funrarẹ.