YO/Prabhupada 1078 - Ton ronu t'okan t'ara wakati merin le-logun nipa Oluwa



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Oye ati ọkan ba nfi gbogbogba npero ti Ọlọrun Ọba wakati merin le-logun Ti ẹ ba ni ori ifẹ to lagbara fun Oluwa Ọlọrun, nigbana ni a si le ṣe iṣẹ ojuse wa ati tun se ranti Oluwa nigba kanna. Ṣugbọn a ni lati mu ori ifẹ na dagba. Arjuna, fun apẹẹrẹ, ti nlero Ọlọrun l’ọkan nigbagbogbo. Ninu wakati mẹrin-le l’ogun, ko fi iseju kan gbagbe Ọlọrun. O si jẹ ibakan ojugba Ọlọrun, bi o tun se jẹ jagunjagun lọwọ kanna. Ọlọrun kò fun ni imọran ki o fi jijagun silẹ ki o si lọ farati sinu igbo lati ṣe àṣaro lori Himalaya. Nigba ti Oluwa Ọlọrun salaaye awọn ọna sîsê yoga fun Arjuna, Arjuna sọ pé asa ọna sîsê yi ko ṣee ṣe fun oun, Arjuna sọ pé asa ọna sîsê yi ko ṣee ṣe fun mi.." Lehin na Oluwa sọ wipe, yoginām api sarveṣāṁ mad-gatenāntarātmanā (BG 6.47). Mad-gatenāntarātmanā śraddhāvān bhajate yo māṁ sa me yuktatamo mataḥ. Nítorí náà, ẹni ti o ba nse ero ti Ọlọrun Ọba nigbagbogbo oun ni Yogi to ga julọ, jñānī to lokiki julọ, ati olufọkansin ti o ga julọ ni igba kanna. Ọlọrun ti se eyi nimọran tasmāt sarveṣu kāleṣu mām anusmara yudhya ca (BG 8.7). "Gẹgẹ bi kṣatriya, ajagun, ko le fi jijagun rẹ silẹ, ṣugbọn ti Arjuna ba nse iranti Ọlọrun ninu ija, nigbana yio see se," anta-kāle ca mām eva smaran (BG 8.5), "nigbana yio see se lati ranti Ọlọrun ni akoko ikú" Mayy arpita-mano-buddhir mām evaiṣyasy asaṁśayaḥ. Lẹẹkan si O tun sọ wipe ko si isiyemeji kankan. Ti eniyan ba jọwọ ara rẹ patapata ninu iṣẹ Oluwa. ninu iṣẹ ìfẹ imọlẹ ti Oluwa, mayy arpita-mano-buddhir (BG 8.7). Ki ise ara wa ni a fi nṣiṣẹ, lododo. ṣugbọn pẹlu ọkan ati ọgbọn wa. Bẹ ti oye ati ọkan ba nfi gbogboigba npero ti Ọlọrun Ọba, laifagbarase ni awọn iye-ara na ma kopa ninu iṣẹ Rẹ. Eyini si jẹ asiri ti Bhagavad-gita. Eniyan gbọdọ kọ ise ọna yi, bi a se nfi, ọkan ati oye sinu ero ti Oluwa, wakati mẹrin-le-logun. Iru ifọkansi na yoo jẹki eniyan le gbe ara rẹ si ijọba Ọlọrun tabi si sakaani ọrun lẹyin igba ti o ba ti fi awọ ara yi silẹ. Awọn eniyan iwoyi ti ngbiyanju fun ọdun si ọdun jọ gidigidi gan, lati de ori oṣupa, sugbọn sibẹ wọn ko ti sunmọ. Sugbon ninu Bhagavad-gita, won ti daba fun wa. Ti eniyan ba nireti a ti tunbọ se adọta ọdun si laye... o yẹ ki o fi akoko finifini yi se riro asa irántí Ẹni Isaju Eledumare. Eyini jẹ ero ti o dara gan. sugbọn ti eyan ba gbiyanju sise yi fun ọdun mẹwa tabi marun, mayy arpita-mano-buddhir (BG 8.7)... O jẹ ọrọ ise ti iwa nìkan. Ati pe asa na le jẹ ṣiṣe ni rọọrun gidigidi nipa ilana isẹ Oluwa, śravaṇaṁ. Śravaṇaṁ. Ilana to rọrun julọ ni lati gbọran.

śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ
smaraṇaṁ pāda-sevanam
arcanaṁ vandanaṁ dāsyaṁ
sakhyam ātma-nivedanam
(SB 7.5.23)

Awọn ilana mẹsan wọnyi, eyi ti o rọrun julọ ninu wọn jẹ śravaṇam.