YO/Prabhupada 1079 - Iwe mimo ti gbogbo awon eyan gbodo ka dada ni Bhagavdad-gita je



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Bhagavad Gita jẹ iwe mimọ eyi ti o yẹ ki a fi pẹlẹpẹlẹ ka gan Gbigbọ ọrọ Bhagavad Gita lati ọdọ onimọran eniyan, yoo dari oluwarẹ sinu ero ti Atobijulọ fun wakati mẹrin le logun, yoo ja si ìrántí Ọlọrun Ọba, anta-kale, yoo si jẹki oluwarẹ, lẹyin ti o ba ti fi ara yi silẹ ni anfaani ati gba, ara ẹmí, eyi ti o wulo lati ni irẹpọ pẹlu Ọlọrun Ọba. Nitorina Oluwa sọ wipe,

abhyāsa-yoga-yuktena
cetasā nānya-gāminā
paramaṁ puruṣaṁ divyaṁ
yāti pārthānucintayan
(BG 8.8)

Anucintayan, ti o nse iranti Rẹ ninu ọkàn nigbagbogbo. Eleyi ki ise ilana ti o soro gan. Sugbọn, eniyan gbọdọ kọ ilana na lọdọ ẹni ti o ti ni irirÍ aye ninu ọna yi. Tad vijñānārthaṁ sa gurum evābhigacchet (MU 1.2.12). Oluwarẹ gbọdọ sunmọ ẹni ti o wa ninu asa na tẹlẹ. Bẹ na abhyāsa-yoga-yuktena. Eyi ni a npe ni abhyāsa-yoga, lilo niwa. Abhyāsa..... bi a se le ranti Oluwa nigbogbo'gba. Cetasā nānya-gāminā. Ọkan, Ọkan ẹni ki duro jẹ. ṣugbọn a gbọdọ se niwa lati maa fọkansi irisi Ọlọrun Ọba nigbogbogba, ninu ohùn kike pe orukọ Ọlọrun ti o ti wa ni rọrun. Dipo ti mo ma fi fọkansi -- inu riro ko njẹki ọkan eniyan le sinmi, ko le duro jẹ, ṣugbọn mo le fọkansi ifeti si ohùn kike pe Ọlọrun, eyini na ma ranmilọwọ. Eyini na ni abhyasa-yoga. Cetasā nānya-gāminā paramaṁ puruṣaṁ divyaṁ. Paramaṁ puruṣa, Ẹni Isaju Eledumare ninu ijọba ẹmí, eniyan le sumọn, sakaani ọrun, anucintayan, ni sise bayi ni nigbogbo'gba. Be na awon ilana wanyi, awọn ọna ati iwa ti a le gba, wọn ti ni mẹnuba ninu Bhagavad Gita, Kosi idina fun ẹni kankan. Ki ise wipe awọn eniyan iru ipo kan pato ni o le sunmọ. nitori gbigbero Oluwa Ọlọrun, ati gbígbọ nipa Rẹ ṣee ṣe fun gbogbo eniyan. Oluwa si sọ ninu Bhagavad-gita,

māṁ hi pārtha vyapāśritya
ye 'pi syuḥ pāpa-yonayaḥ
striyo vaiśyās tathā śūdrās
te 'pi yānti parāṁ gatim
(BG 9.32)
kiṁ punar brāhmaṇāḥ puṇyā
bhaktā rājarṣayas tathā
anityam asukhaṁ lokam
imaṁ prāpya bhajasva mām
(BG 9.33)

Bayi ni Oluwa wi pe ani awọn eniyan ti wọn jẹ ero-ẹhin, tabi paapa obinrin to wọpọ, eniyan oniṣowo, tabi alagbaṣe... Awọn onisowo, awọn alagbase, ati awọn obirin, nwọn ti kà wọn bi ẹka kanna nitori ọgbọn wọn ko se bẹ ni idagbasoke. Sugbon Oluwa sọ wipe, ani awọn eniyan ti wọn lọ sẹhin ju wọn lọ, māṁ hi pārtha vyapāśritya ye 'pi syuḥ (BG 9.32), awon nikan kọ tabi awọn eniyan ti wọn kere ju wọn lọ, tabi ẹnikẹni. Ko ṣe pataki ẹni ti o jẹ, botiwu ki o ri, ẹnikẹni ti o ba gbà ilana ti bhakti-yoga yi ti o si gbà Ọlọrun Ọba bi ipilẹsẹ aye, ifọkansi to ga julọ, ìlépa igbẹhin... Māṁ hi pārtha vyapāśritya ye 'pi syuḥ, te 'pi yānti parāṁ gatim. param gatim ti ijoba ọrun ati ti ọrun ẹmí ti gbogbo eniyan le sunmọ. A kan ni lati kọ ọna sise niwa. Ọna sise na ti wa ni alaaye dàdà ninu Bhagavad-gita. ti eniyan ba gba awọn ilana ti wọn fi lelẹ ninu Bhagavad Gita, o le ṣe ojutu to yẹ si gbogbo awọn isoro aye. Eleyi jẹ aropọ gbogbo nkan ti Bhagavad Gita jẹ. Nitorina, ipari ọrọ ni wipe, Bhagavad-gita jẹ iwe imọlẹ eyi ti o yẹ ki a fi tọkantọkan ka gan. Gītā-śāstram idaṁ puṇyaṁ yaḥ paṭhet prayataḥ pumān. bi o ba tẹle awọn ilana Gita daradara, iyọrisi rẹ yio si jẹ, nigbana o see se ki o le ni ominira ninu gbogbo awọn inira ati àníyàn aye. Bhaya-śokādi-varjitaḥ. Oluwarẹ a bọ ninu ibẹrubojo ti aye yi, aye atunwa rẹ yio si jẹ ti ẹlẹmí.

gītādhyāyana-śīlasya
prāṇāyama-parasya ca
naiva santi hi pāpāni
pūrva-janma-kṛtāni ca
(Gītā-māhātmya 2)

Anfani miran ti o tun wa niwipe, ti eniyan ba ka Bhagavad Gita, tọkàntọkàn gan ti o si mu ni pataki, nigbana nipa ore-ọfẹ Oluwa, ere awọn aisedeede rẹ ti o ti kọja ko ni f’abọ si lori.