YO/Prabhupada 0050 - Won o mo nkan ti o nje ile aye miran



Lecture on BG 16.5 -- Calcutta, February 23, 1972

Eda ohun kohun, nfun wa ni aayee pupo l'abe ase Olorun, nfun wa ni aayee lati kuro ninu idande ibi ati iku: janma-mṛtyu-jarā-vyādhi duḥkha-doṣānudarśanam (BG 13.9). A gbodo ni ogbon lati ri awon iyonu isele merin ile aye: janma-mṛtyu-jarā-vyādhi. Iyen ni gbogbo eto Vediki - bawo ni a se le ni ominira ninu idande won yi. Sugbon won fun won l'aayee wipe " Iwo se eleyi, iwo se to'hun", aye idani lofin. ki ofi le jade ni igbehin.

Nitorina Oluwa so wipe, daivī sampad vimokṣāya (BG 16.5). Ti e ba se idagba daivi sampat, iwa wonyi, bi won se sapejuwe - ahiṁsā, sattva-saṁśuddhiḥ, ahiṁsā, nkan orisirisi - nigba na ni iwo o si jade, vimpksaya. O se ni laanu, pe ilaaju ode oni, won ko mo nkan ti onje vimoksaya. Won s'afoju gidi gan. Won o mo pe ipo kan wa ti won npe ni vimoksaya. Won o mo. Won o mo nkan ti o nje ile aye miran. Ko si eto eko fun eleyi. Mo nse irin ajo kaakiri orile aye. Ko si ile eko kan ti won se fun ati ma da imoran nipa irin ajo emi lati ara kan si imiran, bi a ti le ri igbesi aye to dara. Sugbon won o gbagbo. Won o ni oye. Iyen ni āsurī sampat. Alaaye re ni won se sibi: pravṛttiṁ ca nivṛttiṁ ca janā na vidur āsurāḥ. Pravṛttim. Itumo Pravṛttim ni ifanimora, tabi isomora. Awon iru ise wo ni a ni lati faramo, ati ninu awon wo ni a le ti ya soto. nipa iyen, awon asuras, won o ni iye. Pravṛttiṁ ca nivṛttiṁ ca.

pravṛttiṁ ca nivṛttiṁ ca
janā na vidur āsuraḥ
na śaucaṁ nāpi cācāro
na satyaṁ teṣu vidyate
(BG 16.7)

Awon asura ni yi. Won o mo bi won se ma dari ile aye won, ni ona wo ni won ma gba. Iyen ni won npe ni pravrtti. Ati iru igbesi aye wo ni won gbodo ya soto. Pravṛttis tu jīvātmana. Imiran ni yen. Bhunam. Nivṛttis tu mahāphalām. Gbogbo awon iwe mimo, gbogbo ilana Vediki wa fun pravṛtti-nirvṛtti. Won nse leko diedie. Gege bi Loke vyavāyāmiṣa-madya-sevā nityā sujantoḥ. Nkan elemi ni iwa idanida fun vyavaaya, idapo; ati madya sevāḥ, ipaloti; āmiṣa sevāḥ, ati eran jije. Iwa idanida wa nbe. Sugbon awon asura won ko gbinyanju lati mu duro. Won fe fi po si. Iyen ni ile aye asura. Mo ni arun kan. Ti mo ba fe wo san, oniwosan dokita ma ko ogun fun mi wipe "Ma se bayi" Gege bi eni ti o ni arun ti o nmu ni to nigba gbogbo. Won da-lekun wipe " Ma je nkan ti o wa ni didun, ma je nkan ti o ni stachi" Nivṛtti.. Ni bakanna, iwe mimo fun wa ni ilana wipe ki e gba awon nkan won yi ati awon nkan ti e gbodo lodi si, sastra Gege bi ninu egbe wa, a ti mu awon nivrtti ati pravrtti ti o wa ni pataki. Pravrtti na... A nse lofin fun awon omo eleyin wa, "E lodi si iparapo sina, e lodi si eran jije, e lodi si āmiṣa-sevā" Āmiṣa-sevā nityā sujantoḥ. Sugbon iwe mimo so wipe ti o ba le lodi si, nivṛttis tu mahāphalām, aye re yi o si je aseyori. Sugbon awa ko ti se tan lati se nkan wonyi. Ti e ko ba se tan lati gba awon pravrtti ati lati lodi si awon nivrttis, e gbodo mo wipe asura ni yin nigbana. Olorun so nibi, pravṛttiṁ ca nivṛttiṁ ca janā na vidur āsurāḥ (BG 16.7). Won o se... "Ah, Kini yen?" Won so wipe, awon swami(ojise), nla nla, won a so wi pe, "Kini o buru mbe? O le je ohun kohun. Ko ja mo nkan kan. O le se nkan to ba wu e. Sa fun mi ni owo, emi yio si fun e ni adura, mantra pataki." Eleyi nsele.