YO/Prabhupada 0080 - Olorun na ni ife pupo lati ma sere pelu awon ore odomo kunrin Re



Lecture on CC Madhya-lila 21.13-49 -- New York, January 4, 1967

e-mata anyatra nāhi śuniye adbhuta
yāhāra śravaṇe citta haya avadhūta
'kṛṣṇa-vatsair asaṅkhyātaiḥ'-śukadeva-vāṇī
kṛṣṇa-saṅge kata gopa-saṅkhyā nāhi jāni
(CC Madhya 21.18-19)

Gopa. Se mo, Olorun, ni ibugbe Re, Ko ju bi odo omo odun merindinlogun, nkan ti O si fi nlode ni lati ko awon malu lati lo je'dan pelu awon ore re. ati lati ma ba won sere. Eyi ni ise ojo fun Krishna. Bee ni Sukadeva Goswami ti ko ese to dara, wipe awon odomo kunrin ti won ba Krishna sere yi, ni ile aye won akowa, won ti se ikojo awon ere ise rere pupo jo. Kṛta-puṇya-puñjāḥ (SB 10.12.11). Sākaṁ vijahruḥ. Itthaṁ satāṁ brahma-sukhānubhūtyā. Ni bayi, Sukadeva Goswami nfi se ni ki ko. Awon omo kunrin ti won ba Krishna sere yi, tani won nba sere? Won nba Otito Atobiju Lo sere, eniti awon ologbon giga ro wipe o je alailara. Itthaṁ satāṁ brahma... Brahma-sukha. Brahma, ifise mimo nkan emi, Brahman, ti o ju iriri ti aye yi. Orisun ifise mimo emi wa ni bi, Olorun Bee na awon omo kunrin ti won ba Olorun sere yi, Oun ni orisun ti ifise mimo ti emi, Brahman, Itthaṁ satāṁ brahma-sukhānubhūtyā dāsyaṁ gatānāṁ para-daivatena. Ati dāsyaṁ gatānām, awon ti won ti gba Olorun Oba bi alakoso won, iyen je awon olufokansin. fu won Krishna ti e nri yi ni Olorun Oba. Fun awon ologbon to keyin si eda Olorun Oun ni Emi To Ga Ju Lo, ati fun awon ti o nigbagbo si eda Olorun, Oun ni Olorun Oba. Ati māyāśritānāṁ nara-dārakeṇa. Ati fun awon ti won wa ninu ide ile aye asan, fu won Ko Ju omo kunrin bi awon yoku. Māyāśritānāṁ nara-dārakeṇa sākaṁ vijahruḥ kṛta-puṇya-puñjāḥ (SB 10.12.11. Pelu Re awon omo kunrin won yi ti won ti ni ikojo ere ti ise rere ni aimoye igba ni ile aye akowa won, nisinyi won ti ni ore ofe lati sere pelu Olorun loju koro ju gege bi awon omode lasan. Bakanna, Olorun na ni ife pupo lati ma sere pelu awon ore odomo kunrin Re. Won fi ey i se ni mimo ninu Brahma-samhitaa. Surabhīr abhipālayantam, lakṣmī-sahasra-śata-sambhrama-sevyamānam (Bs. 5.29). Bee na ni won se s'alaye awon nkan wonyi ni bi na.

eka eka gopa kare ye vatsa cāraṇa
koṭi, arbuda, śaṇkha, padma, tāhāra gaṇana
(CC Madhya 21.20)

Nisinyi awon ore po rere, awon oluso-agutan, a o le ka won tan. Ko s'eni na... Alailopin, gbogbo nkan alailopin. Won ni awon malu ni aimoye, awon aimoye ore odomo-kunrin, gbogbo ohun ni aimoye.

vetra, veṇu dala, śṛṅga, vastra, alaṅkāra,
gopa-gaṇera yata, tāra nāhi lekhā-pāra
(CC Madhya 21.21)

Nisinyi awon omo oluso-agutan won yi, won ni opa lowo, vetra. Olukaluku won si ni fere pelu. Vetra veṇu dala. Pelu ododo oju omi, ati srngara, iwo. Śṛṅgara vastra, won a si wewu to dara. Pelu awon ileke to kun. Gege bi Krishna se wewu, bakanna, awon ore Re, awon aluso-agutan, awon na si wewu. Ni abugbe orun, nigba te ba de be, e ko ni le se iyato laarin eniti o je Olorun ati eniti ki se Olorun. Gbogbo won ni won dabi Olorun. Bakanna, ni awon orun Vaikuntha gbogbo won ni won dabi Vishnu. Iyen ni won pe ni sarupya-mukti. Awon eda araye, nigba ti won ba wo nu awon ibugbe orun, won a si di didara bi Krishna ati Vishnu - ko si iyato - nitori pe o je aye pipe. Eyi ni iyato to wa nbe. Awon ojogbon ti won lodi si eda, ko le ye won wipe paapa ninu idaduro enikokan wa, ko si iyato. Kete bi won ba ronu si idaduro olukaluku, oh, won a ro wipe iyato wa. Kini igbala nigba na? Bee ni. Ati pe ni totô ko si iyato. Iyato kan to wa ni wipe iseda ti Olorun ati iseda ti awon miran, o da won loju wipe "Olorun ni ohun ti a gbodo ni ife." Ko ju yen lo. Olorun ni agbedemeji. Ni ona yi awon olukaluku odomo kunrin ati obirin ati Krishna, gbogbo won ni won ngbadun ayo ti ko lopin.