YO/Prabhupada 0088 - Awon akeko ti won darapo mo wa, won ti fi fun gbigba oro nipa ifetisile



Lecture on BG 7.1 -- San Diego, July 1, 1972

Brahma so wipe. Iriri Brahma... Oun ni eda alaaye to ga ju lo ninu ayegbogbo. O so wipe "Nigba ti eeyan ba ma fi iwa isokuso gbiroigbimo sile..." Jnane prayasam udapasya. O gbodo ni teriba. Eeyan o gbodo gbera re ga pe oun mo nkan, o le gbiroigbimokan, o le da nkan tuntun sile. Gege bi awon karohun-wi onimo ijinle, won kan nse igbiroigbimo sa won si nse ise asedanu. Ko si nkan ti e le se. Gbogbo nkan ti wa ni ito-sile. E ko le yi pada. E kan le ri bi ofin se nsese , iba ti e le se ni yen. Sugbon beni e ko le yi ofin na pada, e le se eto to dara fun ofin na. Rara. E o le se yen. Daivi hy esa gunamayi mama maya duratyaya (BG 7.14). Duratyaya tumo si nkan ti o nira gan. Bee na ni Chaitanya Mahaprabhu, nigbati O gbo oro ti Brahma so sile, pe a gbodo fi ona ti igbiroigbimo si le, pe o le da nkan sile... Awon iwa ainilari yi je dandan lati fi sile. O gbodo di onirele pupo. Irele to ju ti koriko. Gege bi a se ma nte koriko lori mole; ti ko si ns'aroye. "O dara, oga, e ma lo." Iru irele ba yen. Trnad api sunicena taror api sahisnuna. Taru tumo si igi. Igi ni ifarada pupo.

Bee na ni Chaitanya Mahaprabhu so wipe, jnane prayasam udapasya namanta eva... O dara nigbana, ma fi ona igbinaigbiro na sile ma si di onirele, gege bi e se damoran. Nigba na kini ojuse mi to ku? Ojuse tokan ni: namanta eva, je onirele, san-mukharitam bhavadiya-vartam, o ye ki e sunmo eniti o je olufokansin. e si ye ki e feti si oro re. Sthane sthitah. E duro si ipo ti e ba wa. E duro bi omo ile Amerika. E duro bi omo ile India. E duro gege bi omoleyin Kristi. E duro bi onise esin Hindu. E duro bi eniyan dudu. E duro bi eniyan funfun. E duro bi obinrin, okunrin tabi nkan ki nkan ti e le je. E kan fi eti yin sile si oro ijinle la t'odo awon ti won ti di atunbi ninu emi. Eleyi je iseduro. Ti e ba si gbo, e si fi se asaro-inuwo. Gege bi e se ngbo mi. Ti e ba fi se asaro-inuwo wipe "Nkan ti Swamiji so...?" Sthane sthitah sruti-gatam tanu-van-manobhih. Sruti-gatam. Sruti tumo si ki a kan ma gboro lati eti. Ti e ba se isaro-inuwo, ti e si gbiyanju lati ni loye pelu ara, ati okan yin, die-die nigbana ni ema... Nitoripe ifojusi yin ni imo oran nipa ti ara eni. Bee na ni ara eni tumo si Emi mimo. Olorun Oba, Oun ni Emi mimo. Awa je apa ati ese. Bee na ni pa ilana yi, Chaitanya Mahaprabhu so wipe, Olorun, Ajita, eni ti a ko le segun... Ti e ba... Ti e ba fe mo Olorun, ni pa ileri e ko ni le mon lai lai. Olorun ko ngba ileri. Nitoripe Olorun to bi, fun kini O se ma gba ileri yin. Ti e ba so wipe, "Ah Olorun mi owon, jowo wa sibi. Mo fe ri E," bee na Olorun ko ri ba yen, ti O fi ma je olu ranse yin. E yin gbodo je olu ranse Re. Nigba na ni a le ni imo to daju ni pa ti Olorun. Olorun so wipe: "Jowo ara re," sarva-dharman parityajya mam ekam saranam vraja (BG 18.66). Nipa ona yi e o ni eko ni pa Olorun. Ki se pe "Ah, emi o mo Olorun. Mo ni oye ti o dara, igbimoigbiro." Rara o.

Bee ni ifetisileyi... A nsoro nipa ifetisile. Ifetisile je nkan ti o se pataki. Gbogbo nkan wa, idasile yi, egbe isokan Olorun, ti tan ka nitori awon akeko ti won darapo mo wa, won ti fi fun gbigba oro, nipa ifetisile. Ifetisile na, gbogbo nkan ti yi pada ninu aye won won si ti parapo mo wa tokan- tokan, ati ... O nlo loju dede. Nitorina ifetisile se pataki gan ni. A nsi opolopo ile ipade lati fun awon eniyan l'anfani lati gbo ihinrere ti imo ijinle na. Ki e gba anfaani, o ya, mo fe so pe, awon anfani ti gbigboran lowo eniyan yi.