YO/Prabhupada 0094 - Ise wa ni lati se atunwi oro Olorun



Lecture on BG 1.20 -- London, July 17, 1973

Igbesi aye elese ko le se iwadi nipa Olorun tabi le ni oye nipa Olorun. A ti tenumo ese na ni igba pupo,

yeṣāṁ tv anta-gataṁ pāpaṁ
janānāṁ puṇya-karmaṇām
te dvandva-moha-nirmuktā
bhajante māṁ dṛḍha-vratāḥ
(BG 7.28)

Paapis, awon eniyan elese, ko le ye won. Eyi to ye won, ko ju ki won lero wipe "Olorun ni Bhagavan; bee ni emi na Bhagavan. O je arinrin eniyan, boya o lagbara kekere, o si je eni-itan olokiki eniyan. Bee na, bi o ti wu kawi, eniyan ni. Bee na ni emi je eniyan. Kilode ti emi na o le je Olorun?" Eyi ni ipinnu oro ti awon abhaktas, awon alaini-igbagbo ati awon eniyan elese.

Nitorina enikeni ti o ba nfiwon ara re bi Olorun, o ye ki e mo lesekese pe olori eniyan buburu ni. Ti e ba si se àsàro ikoko igbesi aye re, e ma ri wipe oun ni akoko ninu awon eniyan buburu. Eyi ni igbeyewo. Tabi ki enikeni yi o so wipe oun ni Olorun, oniduro eke. Ko si eni na. Ko si eni ti o nse rere to ma se be. O ye. "Kini mo je? Emi arinrin eniyan. Bawo ni mo se le beere lati gba ipo ti Olorun?" Bee ni won se ndi olokiki laarin awon alainilari.

Bi o ti wa ni so ninu Srimad Bhagavatam, śva-viḍ-varāhoṣṭra kharaiḥ (SB 2.3.19). Kini ese yen ti wi? Uṣṭra-kharaiḥ, saṁstutaḥ puruṣaḥ paśuḥ. Awon... Ninu aye yi a ri wipe opolopo awon eniyan nla lo wa, awon karohun-wi eniyan nla, ti awọn eniyan gbogboogbo nyìn gidigidi. Bee ni Bhagavata so wipe, enikeni ti ki se olufokansin, ti ko fi gba kan pe mantra Hare Krishna, o le je eni nla gidi gan loju awon alainilari eniyan, sugbon ko je nkankan ju eranko lo. Eranko. Bee ni, śva-viḍ-varāha-uṣṭra-kharaiḥ. "Ni bawo le se le so wipe iru eni nla. E nso wipe eranko" Ise wa je eyi ti ko l'ope. A so wipe eni keni ti ko nse olufokanin, o je alaibikita. A nso nigbogbo igba. Gbolohun oro to le gan ni; sugbon a ni lati lo o. Bi ni kete ti a ba ri wipe ki se olufokansin Olorun, o si je alaibikita ni yen. Bawo la se le so be? Kii se ota mi, sugbon a ni lati so nitoripe be ni Krishna wi.

Ti a ba je onisokan Olorun gidi, ise wa ni lati se atunwi oro Olorun. Ko ju be lo. Kini iyato laarin eniti nse asoju Olorun ati eniti kii se asoju? Asoju Olorun ma kan se atunwi ohun ti Olorun wi. Ko ju be lo. O di asoju. Ko ni iwulo ijeri pupo. E kan s'atunwi pelu igbagbo to duro sinsin. Gege bi Olorun se wi, sarva-dharmān parityajya mām ekaṁ śaraṇaṁ vraja (BG 18.66). Bee ni eniti o ba ti gba eyi daju wipe "Ti mo ba fi aye mi fun Olorun, gbogbo owo mi ni o je aseyori." oun ni asoju Olorun. Ko ju be lo.

E ko n'ilo lati je omowe giga tabi je eniti o ni ilosiwaju. Ti e ba ti le gba ohun ti Olorun wi nikan... Gege bi Arjuna se wi, sarvam etaṁ ṛtam manye yad vadasi keśava: (BG 10.14) "Oluwa mi owon, Kesava, ohunkohun ti O ba nwi, ni mo gba, laisi iyipada eyikeyi." Bhakta ni yen. Nitori idi eyi ni won se pa Arjuna ni, bhakto 'si. Eyi ni owo awon bhaktas. Kilode ti mo se ma fi ara mi we Olorun, emi arinrin eniyan? Eyi ni iyato laarin bhakta ati eniti ko nse bhakta. Bhakta mo wi pe " Emi alaito, ina-tan Olorun. Olorun je oluku eniyan. Oluku eniyan ni emi na. Sugbon nigbati a ba ro agbara Re ati agbara temi, emi je alaito julo." Eleyi ni oye ti Olorun.

Ko si isoro nibe. A kan gbodo je olododo, ki se elese. Sugbon eniyan elese ko le ni oye Re. Eniyan buburu, ma so wipe, "Eniyan na ni Krishna, eniyan ni emi na. Kilode t'emi o le je Olorun? O kan je Olorun? Rara, emi na. Olorun ni mi. Olorun ni wo na, Olorun ni wo na, olukaluku je Olorun." Gege bi Vivekananda ti so, "Kilode ti e nwa Olorun? Se e ko leri pe opolopo awon orisa nrin kaa kiri loju titi? Se e ri. Eleyi ni riri gan Olorun re. Eleyi ni riri gan Olorun re. O si di eniyan pataki: "Ah, o nri gbogbo eniyan bi Olorun."

Ero omugo yi, ise alaibikita yi, ti ngba iyi lori gbogbo aye. Eyan o mo ohun ti Olorun je, ohun ti nse agbara Olorun, ohun ti Olorun tumo si. Won ngba enikeni ti onilari bi Olorun. Lasiko yi o ngba yi si. Alaini lari miran tun wa. Oun na npe ara re ni Olorun. Bee na lo se di nkan opo. Sugbon won o ni opolo lori lati lero wipe "Mo nso wipe Olorun ni mi; agbara wo ni mo ni?"

Bee ni ohun ijinle na ni yi. Eleyi ni adiitu. Lai di olufokansin, awon ijinle oye ti Olorun ko le see se. Ati wipe Olorun ti so ninu Bhagavad Gita bi a se le mo. Bhaktyā mām abhijānāti yāvān yaś cāsmi tattvataḥ (BG 18.55) Nipa ifokansin nikan, ni won be. O le ti wipe, "Nipa imo to ga " tabi "Nipa ilana yoga" tabi "Nipa ifisewa hu, nipa di di osise nla, karmi, bayi ni e se le mo mi." Rara, ko fi gba kan so be lailai. Bee na awon karmis, jnanis, yogis, gbogbo won ni won je alaini lari. Won o le loye Olorun. Awon alainilari. Awon karmis je ipo-keta awon alainilari, awon jnanis ni ipo -keji awon alainilari, ati awon yogis ni won se akoko ninu awon alainilari. Bo se ri ni yen.