YO/Prabhupada 0105 - Imo yi ti wa ni igboye nipase ijogun awon omo eleyin



Lecture on BG 18.67 -- Ahmedabad, December 10, 1972

Olufokansin: Śrīla Prabhupāda, enikan beere wipe, "Tani o ma s'akoso egbe yi lehin yin?

Prabhupāda: Tani eni ti o nbere, oun lo ma se. (Erin)

Arakunrin India: Se mo le beere lowo awon olujosin mi owon kini eto yin lati gbe siwajusi, lati mu egbe yin lo siwaju lehin yin, pe kini o ma s'eyin Śrī Bhaktivedanta Prabhu, lati jeki akaba yi duro: hare Krsna, Hare Krsna.

Prabhupāda: O ti wa ni imenuba ninu Bhagavad-gītā:

imaṁ vivasvate yogaṁ
proktavān aham avyayam
vivasvān manave prāha
manur ikṣvākave 'bravīt
(BG 4.1)

Ni akoko, Olorun soro imo ijinle isokan Olorun yi salaaye imoye yi si alakoso-orun, alakoso-orun Vivasvan na s'alaaye re fun omo re Manu. Bee ni Manu na si salaaye fun omo-okurin re Iksvaku. Evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rājarṣayo viduḥ (BG 4.2). Bee ni imo yi ti wa ni igboye nipase ijogun awon omo eleyin Nítorí náà bi a ti gbọye nipasẹ eto paramparā lati odo Oluko igbala mi Guru Maharaja,, be na eyikeyi ninu awon akeko mi ti o ba ni oye yi, yi o si ma se ni ilosiwaju. Eleyi ni ilana na.. Kii se ohun titun. O ti wa ni ohun atijọ. A kan ni lati pin kaakiri ni ona ti o dara, gege bi a ti gbo lodo awon asaaju ācārya wa. nitorina won fi eyi se akiyesi ninu iwe Bhagavad-gita : ācārya upāsanam: "E gbodo sunmo ācārya." Ācāryavān puruṣo veda. Kii se nipa gbigbiro, nipa ki-na ti-npe sikolasipu, ko le see se bayi. Ko le ṣee ṣe. E kan gbọdọ sunmọ awọn ācārya. Bee ni acarya nbo lati eto parampara, ni itele tele awon omo eleyin. Nitorina Krsna so wipe, tad viddhi praṇipātena paripraśnena sevayā: (BG 4.34) "Ọ kan yẹ ki o sunmọ awọn ācārya ati ki o gbiyanju lati ni oye nipa praṇipāta, tẹriba." Gbogbo ohun da lori iteriba. Ye yathā māṁ prapadyante. Awọn ilana itẹriba, ni ìwọn itẹriba, ni awọn ọna lati ni oye Olorun. Ti a ba fi jowo ara wa pata fun Olorun, nigba na ni awa le ni oye re ni kikun. Ti a ba si jowo ara wa fun ni iwonba die, bee na ni a ma se ni oye re. Bee ni ye yathā māṁ prapadyante. O je iwon ti iteriba. Eni ti o ba ti jowo ara re patapata, yan to teriba tan, o le ni oye ogbon yi. o si tun le se iwaasu , nipa ore-ọfẹ ti Olorun.