YO/Prabhupada 0122 - Awọn alaibikita wọnyi , nwọn ro pe, Èmi ni ara yi



Morning Walk At Cheviot Hills Golf Course -- May 17, 1973, Los Angeles

Prabhupāda: Olorun so wipe, "Ti o ba teriba ni kikun. Emi o fun ọ ni idabobo." Ahaṁ tvāṁ sarva-pāpebhyo mokṣayiṣyāmi (BG 18.66). Oun yoo fun ọ ni oye ati ogbon ni kikun. (Isimi) Eyí yóò jẹ aseyori nla wa nigbati awọn ijinle sayensi aye yio gba. Jẹ ki wọn gba nìkan. Nigbana ni egbe ifokansin Olorun wa yio (jẹ) aseyori nla. E kan gba, "Bẹẹ ni, Ọlọrun wa nbẹ pelu agbara idan." Nigbana ni egbe wa jẹ aseyori gidigidi . Iyen si jẹ nkan ti o daju. Kà kan maa so isọkusọ laarin awon ti o ni laari, iyen kii se nkan pataki. Andhā yathāndhair upanīyamānāḥ (SB 7.5.31). Afọju kan n dari afọju miiran . kini iwulo iru nkan bayi. Afoju ni gbogbo wan. Ati fun igbati eniyan ba wa ni afọju ati ki o si je alaibikita, ko ni gba Ọlọrun. Èyí ni ìdánwò náà. Ni kete ti a ba ri wipe ko ni gbagbo ninu Ọlọrun, o jẹ afọju, alaibikita, aṣiwere, ohunkohun ti o le pe. Gba fun eri, sibẹsibẹ, ohunkohun ti o le jẹ. Oun jẹ alaibikita. Lori ipo yi a le doju ko ọpọlọpọ awọn onisegun, ojogbon ńlá, ńlá, ẹnikẹni ti o ba si wa si odo wa. Awa wipe, "Elẹmí èṣù ni yin." Onisegun miiran to wa, iwo lo muu wà, arakunrin Indian?

Svarūpa Dāmodara: Hm. Chouri.(?)

Prabhupāda: Bee ni, mo sọ fún un pé "O je elẹmí èṣù." Sugbon kò si binu. O si gba eleyi. Ati gbogbo awọn ariyanjiyan rẹ si ni esi to daju Boya o ranti.

Svarūpa Dāmodara: Bẹẹni, ni otitọ, ó ń sọ pé "Krishna kò fun mi ni gbogbo awọn ilana, igbesẹ, bi o ṣe le se awọn ṣàdánwò." Bi o ti je ... O si n so ba yen.

Prabhupāda: Beeni. Kílode ti emi o fi fun ọ? O je alaibikita, o lodi si Olorun, kini idi re ti Olorun yóò fún ọ ni ohun elo? Ti o ba lodi si Olorun ti o si fẹ awọn íyìn lai fi Olorun se, iyẹn ko ṣee ṣe. O gbọdọ ni itẹriba ni akọkọ. Nigbana ni Olorun yio si fun ọ ni gbogbo ohun elo. Gege bi a se gboiya lati dojuko eyikeyi onisegun, eyikeyi ọmowé, eyikeyi oludero. Kílode? Lori agbara ti Olorun ni, awa gbagbọ pe " Olorun wà. Nigbati mo ba ma ba sọrọ, Olorun yóò fún mi ni imo ati oye. " Èyí ni awọn Ipilẹ. Bibẹkọ, nipa jijùlọ, bošewa, won wa gidigidi. A je awon alagbase to wọpọ niwaju wọn. Sugbon bawo ni a se dojuko wọn? Nítorí pé a mọ. Gege bi ọmọ kekere O le dojuko eni ńlá kan nitori o mọpé, "Baba mi wa nbẹ." O si ndii baba rẹ lọwọ mu, o si ni daju wipe "Ko si eni ti o le ṣe mi ni ohunkohun ."

Svarūpa Dāmodara: Śrīla Prabhupāda, Mo fẹ lati rii daju itumo Tad apy aphalatāṁ jātaṁ.

Prabhupāda: Tad apy aphalatāṁ jātaṁ.

Svarūpa Dāmodara: Teṣām ātmābhimāninām, bālakānām anāśritya Teṣām ātmābhimān..., bālakānām anāśritya govinda-caraṇa-dvayam.

Svarūpa Dāmodara: Igbesi aye eda eniyan di ibajẹ fun awon ... "

Prabhupāda: Bẹẹni. "Eni ti ko ba gbiyanju lati ni oye ifokansin Olorun ." O kan ma ku bi eranko. O pari. Gege bi awọn ologbo ati awọn aja, awọn na tun ni ibimo, awọn na njẹun, nsùn, won si mbi awọn ọmọ, won o si kú. Igbesi aye eda eniyan jẹ bakanna.

Svarūpa Dāmodara: Se Jāta tumo si awon eya eda? Jāta?

Prabhupāda: Jāta. Jāta tumo si ibimo. Aphalatāṁ jātam. Jāta tumo si o di asan.. Asan. Igbesi aye eda eniyan di asan ti ko ba gba govinda-caraṇa. Govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi. Ti ko ba ni gbagbọ pe "Emi sin adayeba Eniyan Metalokan Govinda," Oti baje niyen. O pari. Aye re jẹ ibajẹ . Svarūpa Dāmodara: Ātmābhimāninām tumo si...

Prabhupāda: Ātmā, dehātmā-māninām.

Svarūpa Dāmodara: Nítorí náà awon ti won mo ti-ara-won nikan ....

Prabhupāda: " Èmi ni ara yi." Ara-èni? Won ko ni alaye lori ara-eni. Awọn alaibikita wọnyi , nwọn ro pe, "Èmi ni ara yi. Ātmā tumo si ara, ātmā tumo si ara-èni, ātmā tumo si ọkàn. Nítorí náà, ātmābhimānī tumo si ero aye nipa ti ara . Bālaka. Balaka tumo si òmùgọ, ọmọde, bālaka. Ātmābhimānināṁ bālakānām. Awon ti won wa ninu ero aye nipa ti ara , won dabi awọn ọmọde, awọn aṣiwere, tabi awon eranko.

Svarūpa Dāmodara: Nítorí mo gbero lati sọ asọye ofin aye-atunwa, nipasẹ ẹsẹ yìí..

Prabhupāda: Beeni. Aye atunwa. Bhramadbhiḥ. Aye atunwa ni itumo Bhramadbhiḥ, iyipo lati ara kan si ikeji. Gege bi mose wayi, mo laso ton bomi l'ara Sugbon ti mo ba lo si Orile-ede India, koni wulo mo. Nitorina won gba wipe bayi ni ara se dagbasoke. Beko. Nitori nibi se nipa ipo asiko, ni mo se imura bayi. Ni ibòmíràn, labẹ asiko to yato, ma gba imura miran. Nitorina emi ni o se pataki, ki se aso. Sugbon awon alaibikita wonyi nkẹkọọ nipa aso nikan. Iyen ni a npe ni ātmābhimānām, ronù nipa aso, ara. Bālakānām.