YO/Prabhupada 0161 - Egbudo di Vaisnava pelu aanu fun awon eyan ton jiya ninu agbaye



His Divine Grace Srila Bhaktisiddhanta Sarasvati Gosvami Prabhupada's Disappearance Day, Lecture -- Los Angeles, December 9, 1968

Tawa ba gbiyanju lati sise fun oluko wa, Krsna na ma fun wa nigbogbo ohun elo tafe. Asiri towa niyen. Mosi rowipe kosi bimo sele ni aseyori, sugbon die die, awon nkan bere sini tesiwaju, teba ka asọye ti Viśvanātha Cakravartī Ṭhākura lori Bhagavad-gītā. Ninu Bhagavad-gītā ẹsẹ-iwe vyavasāyātmikā-buddhir ekeha kuru-nandana (BG 2.41), pelu ese-iwe yi, Viśvanātha Cakravartī Ṭhākura si funwa ni asoye lori oro na pe agbudo gba oro oluko wa gege bi aye at'emi wa. Agbudo gbiyanju lati se gbogbo nkan ti Oluko basowipe ka se lai ronu nkan toma sele si.

Mosi gbiyanju die pelu iwa yi. Odeti funmi ni gbogbo nkan timo fe larti sise fun. modeti wa si Orile-ede yin ninu ojo arugbo mi, eyin sin gbiyanju lati gba egbe yi nipataki, e gbiyanju lati ni oye nipa re. Ati ni awon iwe die nisin. gege na atini ibere die ninu egbe wa yi. Ni ojo ayeye to siwaju ojo ti Oluko mi fi aye yi sile, mosi gbiyanju lati sise fun, gege na mon bere lowo yin pe ke gbiyanju lati sise yi bimo sefe si. Arugbo nimi, mole fi aye yi sile laipe. Ofin iseda yi niyen. koseni tole da duro. Konse nkan toje iyanu, sugbon lori ojo yi ti Guru Mahārāja mi fi aye yi sile, ibeere kan timoni niwipe, mode mowipe eti ni oye die nipa kókó egbe imoye Krsna yi. Egbudo gbiyanju lati tesiwaju. Awon eyan ton jiya nitoripe wan fe gba imoye yi s'okan. Bawa sen gbadura si awon elesin lojojumo,

vāñchā-kalpatarubhyaś ca
kṛpā-sindhubhya eva ca
patitānāṁ pāvanebhyo
vaiṣṇavebhyo namo namaḥ

Awon elesin Oluwa tabi Vaisnava, wanti fi aye wan fun ise agbaye. Se mo- opolopo ninu yin lati awujo awon Kristiani leti wa - bi Oluwa Jesu Kristi, bose sowipe oun ti fi ara re s'ẹbọ fun gbogbo ese yin. Ipinnu awon elesin Olorun niyen. Awon eyan yi o ni ironu kankan fun igbadun ara wan. Nitoripe wan nife Krsna tabi Olorun, nitorina wan nife gbogbo awon eda tonni asepo pelu Krsna. Gege na egbudo keko. Itumo egbe imoye Krsna yi niwipe egbudo di Vaisnava ke l'aanu fun awon eyan ton jiya ninu agbaye. Oni orisiri oju ta le fi wo iya ton je agbaye yi, Awon eyan mi lee wo lati oju ara eda Eyan na le fe si awon ile-awosan lati fun awon eyan ni iranlowo. Awon eyan mi lefe fun awon eyan l'ounje ni awon ilu ti o lowo. Gbogbo awon nkan yi lo daa gan sugbon awujo awon eyan jiya nitoripe wanti kosi imoye Krsna laarin wan. Gbogbo ijya yi, gun igba die lowa fun, kodesi besele fi ipari si wan pelu awon ofin iseda. Fun apeere teba lo pin ounje ni awon ilu tio lowo se iyen wipe ona abayo fun gbogbo isoro to wa niyen. Ise to pese fun gbogo=bo eyan ni lati pewan si imoye Krsna